Eks 3:16-17
Eks 3:16-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lọ, ki o si kó awọn àgba Israeli jọ, ki o si wi fun wọn pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, ti Isaaki, ati ti Jakobu, li o farahàn mi wipe, Lõtọ ni mo ti bẹ̀ nyin wò, mo si ti ri ohun ti a nṣe si nyin ni Egipti: Emi si ti wipe, Emi o mú nyin goke jade ninu ipọnju Egipti si ilẹ awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin.
Eks 3:16-17 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní, “Lọ kó gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, kí o sì sọ fún wọn pé, èmi OLUWA, Ọlọrun àwọn baba yín, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu, ni ó farahàn ọ́, ati pé, mo ti ń ṣàkíyèsí wọn, mo ti rí ohun tí àwọn ará Ijipti ti ṣe sí wọn. Mo ṣèlérí pé n óo yọ wọ́n kúrò ninu ìpọ́njú Ijipti. N óo kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Perisi ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.
Eks 3:16-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Lọ, kó àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, kí o sì wí fún wọn pé, ‘OLúWA Ọlọ́run àwọn baba yín, Ọlọ́run Abrahamu, ti Isaaki, àti ti Jakọbu; ni ó farahàn mi, ó sì wí pé: Lóòótọ́ èmi ti ń bojú wò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Ejibiti. Èmi sì ti ṣe ìlérí láti mú un yín jáde kúrò nínú ìpọ́njú yín ni ilẹ̀ Ejibiti wá sí ilẹ̀ Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.’