Eks 3:1-20

Eks 3:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

MOSE si nṣọ́ agbo-ẹran Jetro baba aya rẹ̀, alufa Midiani: o si dà agbo-ẹran na lọ si apa ẹhin ijù, o si dé Horebu, oke Ọlọrun. Angeli OLUWA si farahàn a ninu ọwọ́ iná lati inu ãrin igbẹ̀: on si wò, si kiyesi i, iná njó igbẹ́, igbẹ́ na kò si run. Mose si wipe, Njẹ emi o yipada si apakan, emi o si wò iran nla yi, ẽṣe ti igbẹ́ yi kò run. Nigbati OLUWA ri pe, o yipada si apakan lati wò o, Ọlọrun kọ si i lati inu ãrin igbẹ́ na wá, o si wipe, Mose, Mose. On si dahun pe, Emi niyi. O si wipe, Máṣe sunmọ ihin: bọ́ salubata rẹ kuro li ẹsẹ̀ rẹ, nitori ibiti iwọ gbé duro si nì, ilẹ mimọ́ ni. O si wipe, Emi li Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu. Mose si pa oju rẹ̀ mọ́; nitoriti o bẹ̀ru lati bojuwò Ọlọrun. OLUWA si wipe, Nitõtọ emi ti ri ipọnju awọn enia mi ti o wà ni Egipti, mo si gbọ́ igbe wọn nitori awọn akoniṣiṣẹ wọn; nitoriti mo mọ̀ ibanujẹ wọn; Emi si sọkalẹ wa lati gbà wọn lọwọ awọn ara Egipti, ati lati mú wọn goke ti ilẹ na wá si ilẹ rere ati nla, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin; si ibi ti awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, igbe awọn ọmọ Israeli dé ọdọ mi; emi si ti ri pẹlu, wahala ti awọn ọba Egipti nwahala wọn. Nitorina wá nisisiyi, emi o si rán ọ si Farao, ki iwọ ki o le mú awọn enia mi, awọn ọmọ Israeli, lati Egipti jade wá. Mose si wi fun Ọlọrun pe, Tali emi, ti emi o fi tọ̀ Farao lọ, ati ti emi o fi le mú awọn ọmọ Israeli jade lati Egipti wá? O si wipe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ; eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ pe, emi li o rán ọ: nigbati iwọ ba mú awọn enia na lati Egipti jade wá, ẹnyin o sìn Ọlọrun lori oke yi. Mose si wi fun Ọlọrun pe, Kiyesi i, nigbati mo ba dé ọdọ awọn ọmọ Israeli, ti emi o si wi fun wọn pe, Ọlọrun awọn baba nyin li o rán mi si nyin; ti nwọn o si bi mi pe, Orukọ rẹ̀? kili emi o wi fun wọn? Ọlọrun si wi fun Mose pe, EMI NI ẸNITI O WA: o si wipe, Bayi ni ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, EMI NI li o rán mi si nyin. Ọlọrun si wi fun Mose pẹlu pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli; OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o rán mi si nyin: eyi li orukọ mi titilai, eyi si ni iranti mi lati irandiran. Lọ, ki o si kó awọn àgba Israeli jọ, ki o si wi fun wọn pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, ti Isaaki, ati ti Jakobu, li o farahàn mi wipe, Lõtọ ni mo ti bẹ̀ nyin wò, mo si ti ri ohun ti a nṣe si nyin ni Egipti: Emi si ti wipe, Emi o mú nyin goke jade ninu ipọnju Egipti si ilẹ awọn ara Kenaani, ati ti awọn Hitti, ati ti awọn Amori, ati ti awọn Perissi, ati ti awọn Hifi, ati ti awọn Jebusi, si ilẹ ti nṣàn fun wàra ati fun oyin. Nwọn o si fetisi ohùn rẹ: iwọ o si wá, iwọ ati awọn àgba Israeli, sọdọ ọba Egipti, ẹnyin o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu pade wa: jẹ ki a lọ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, ni ìrin ijọ́ mẹta si ijù, ki awa ki o le rubọ si OLUWA Ọlọrun wa. Emi si mọ̀ pe ọba Egipti ki yio jẹ ki ẹnyin ki o lọ, ki tilẹ iṣe nipa ọwọ́ agbara. Emi o si nà ọwọ́ mi, emi o si fi iṣẹ-iyanu mi gbogbo kọlù Egipti ti emi o ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin eyinì li on o to jọwọ nyin lọwọ lọ.

Eks 3:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kan, Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, tíí ṣe alufaa ìlú Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn aṣálẹ̀, títí tí ó fi dé òkè Horebu ní Sinai, tíí ṣe òkè Ọlọrun. Angẹli OLUWA farahàn án ninu ahọ́n iná láàrin ìgbẹ́; bí ó ti wò ó, ó rí i pé iná ń jó nítòótọ́, ṣugbọn igbó náà kò jóná. Mose bá wí ninu ara rẹ̀ pé, “N óo súnmọ́ kinní yìí, mo fẹ́ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná fi ń jó tí igbó kò sì fi jóná.” Nígbà tí Ọlọrun rí i pé ó súnmọ́ ọn láti wo ohun ìyanu náà, Ọlọrun pè é láti inú igbó náà, ó ní, “Mose! Mose!” Mose dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọrun ní, “Má ṣe súnmọ́ tòsí ibí, bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé, ilẹ̀ tí o dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Ọlọrun tún fi kún un pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu.” Mose bá bo ojú rẹ̀ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á láti wo Ọlọrun. Lẹ́yìn náà OLUWA dáhùn pé, “Mo ti rí ìpọ́njú àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní Ijipti, mo sì ti gbọ́ igbe wọn, nítorí ìnilára àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́, mo mọ irú ìyà tí wọn ń jẹ, mo sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti wá gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati láti kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dára, tí ó sì tẹ́jú, ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú tí ó kún fún wàrà ati oyin, àní, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Perisi, ati ti àwọn ará Hifi ati ti àwọn ará Jebusi. Igbe àwọn eniyan Israẹli ti gòkè tọ̀ mí wá, mo sì ti rí bí àwọn ará Ijipti ṣe ń ni wọ́n lára. Wá, n óo rán ọ sí Farao, kí o lè lọ kó àwọn eniyan mi, àwọn ọmọ Israẹli, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.” Ṣugbọn Mose dá Ọlọrun lóhùn pé, “Ta ni mo jẹ́, tí n óo fi wá tọ Farao lọ pé mo fẹ́ kó àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti?” Ọlọrun bá dá a lóhùn pé, “N óo wà pẹlu rẹ, ohun tí yóo sì jẹ́ àmì fún ọ, pé èmi ni mo rán ọ ni pé, nígbà tí o bá ti kó àwọn eniyan náà kúrò ní Ijipti, ẹ óo sin Ọlọrun ní orí òkè yìí.” Mose tún bi Ọlọrun pé, “Bí mo bá dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Israẹli, tí mo sì wí fún wọn pé, ‘Ọlọrun àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ bí wọ́n bá wá bi mí pé ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni kí n wí fún wọn?” Ọlọrun dá Mose lóhùn pé, “ÈMI NI ẸNI TÍ MO JẸ́. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘ÈMI NI ni ó rán mi sí yín.’ ” Ọlọrun tún fi kún un fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu, ni ó rán òun sí wọn. Ó ní orúkọ òun nìyí títí ayérayé, orúkọ yìí ni wọn óo sì máa fi ranti òun láti ìrandíran. Ó ní, “Lọ kó gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, kí o sì sọ fún wọn pé, èmi OLUWA, Ọlọrun àwọn baba yín, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu, ni ó farahàn ọ́, ati pé, mo ti ń ṣàkíyèsí wọn, mo ti rí ohun tí àwọn ará Ijipti ti ṣe sí wọn. Mo ṣèlérí pé n óo yọ wọ́n kúrò ninu ìpọ́njú Ijipti. N óo kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Perisi ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin. “Wọn yóo gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, ìwọ ati àwọn àgbààgbà Israẹli yóo tọ ọba Ijipti lọ, ẹ óo sì wí fún un pé, ‘OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu ti wá bá wa, jọ̀wọ́, jẹ́ kí á lọ sinu aṣálẹ̀, ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta, kí á lè rúbọ sí OLUWA, Ọlọrun wa.’ Mo mọ̀ pé ọba Ijipti kò ní jẹ́ kí ẹ lọ rárá, àfi bí mo bá fi ọwọ́ líle mú un. Nítorí náà n óo lo agbára mi láti fi jẹ Ijipti níyà, ń óo sì ṣe iṣẹ́ ìyanu níbẹ̀, nígbà náà ni yóo tó gbà pé kí ẹ máa lọ.

Eks 3:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jetro baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jíjìn nínú aginjù. Ó dé Horebu, òkè Ọlọ́run. Níbẹ̀ ni angẹli OLúWA ti yọ sí i nínú ọ̀wọ́-iná tí ń jó láàrín igbó. Mose rí i pé iná ń jó nínú igbó ṣùgbọ́n igbó kò run Nígbà náà ni Mose sọ pé, “Èmi yóò lọ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná kò fi jó igbó run.” Nígbà tí OLúWA rí i pe Mose ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárín igbó náà, “Mose! Mose!” Mose sì dáhùn ó wí pé, “Èmi nìyìí.” Olúwa sì wí fún Mose pé, “Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.” Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.” Nítorí ìdí èyí, Mose sì pa ojú rẹ̀ mọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti bojú wo Ọlọ́run. Ọlọ́run si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára. Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, igbe àwọn ará Israẹli ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Ejibiti ti ṣe ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, lọ, Èmi yóò rán ọ sí Farao láti kó àwọn ènìyàn Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.” Ṣùgbọ́n Mose wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Farao lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti?” Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Mose pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èyí ni yóò jẹ́ ààmì fún ọ, tí yóò fihàn pé Èmi ni ó rán ọ lọ; Nígbà tí ìwọ bá kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ẹ̀yin yóò sin Ọlọ́run ni orí òkè yìí.” Mose sì wí fún Ọlọ́run pé, “Bí mo bá tọ àwọn ará Israẹli lọ tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ tí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn ní ìgbà náà?” Ọlọ́run sì sọ fún Mose pé, “èMI NI TI ń Jẹ́ èMI NI. Èyí ni ìwọ yóò sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘èMI NI ni ó rán mi sí i yín.’ ” Ọlọ́run sì wí fún Mose pẹ̀lú pé, “Báyìí ni kí ìwọ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘OLúWA Ọlọ́run àwọn baba yín; Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu; ni ó rán mi sí i yín.’ “Èyí ni orúkọ Mi títí ayérayé, orúkọ ti ẹ ó fi máa rántí Mi láti ìran dé ìran. “Lọ, kó àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, kí o sì wí fún wọn pé, ‘OLúWA Ọlọ́run àwọn baba yín, Ọlọ́run Abrahamu, ti Isaaki, àti ti Jakọbu; ni ó farahàn mi, ó sì wí pé: Lóòótọ́ èmi ti ń bojú wò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Ejibiti. Èmi sì ti ṣe ìlérí láti mú un yín jáde kúrò nínú ìpọ́njú yín ni ilẹ̀ Ejibiti wá sí ilẹ̀ Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.’ “Àwọn àgbàgbà Israẹli yóò fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ, àti àwọn àgbàgbà yóò jọ tọ ọba Ejibiti lọ, ẹ ó sì wí fún un pé, ‘OLúWA, Ọlọ́run àwọn ará Heberu ti pàdé wa. Jẹ́ kí a lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti lọ rú ẹbọ sí OLúWA Ọlọ́run.’ Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ọba Ejibiti kò ní jẹ́ kí ẹ lọ bí kò ṣe pé ọwọ́ ńlá Ọlọ́run wà ni ara rẹ̀. Nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mí láti lu àwọn ará Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ohun ìyanu tí èmi yóò ṣe ni àárín wọn. Lẹ́yìn náà, òun yóò jẹ́ kí ẹ máa lọ.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa