Eks 25:1-9
Eks 25:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o mú ọrẹ fun mi wá: lọwọ olukuluku enia ti o ba fifunni tinutinu ni ki ẹnyin ki o gbà ọrẹ mi. Eyi si li ọrẹ ti ẹnyin o gbà lọwọ wọn; wurà, ati fadakà, ati idẹ; Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ, ati irun ewurẹ; Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu. Oróro fun fitila, olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn; Okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya. Ki nwọn ki o si ṣe ibi mimọ́ kan fun mi; ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn. Gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo fihàn ọ, nipa apẹrẹ agọ́, ati apẹrẹ gbogbo ohunèlo inu rẹ̀, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe e.
Eks 25:1-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA rán Mose ó ní, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n gba ọrẹ jọ fún mi, ọwọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ọkàn rẹ̀ wá láti ṣe ọrẹ àtinúwá ni kí wọ́n ti gba ọrẹ náà. Àwọn nǹkan ọrẹ tí wọn yóo gbà lọ́wọ́ wọn ni: wúrà, fadaka, idẹ; aṣọ aláró, aṣọ elése àlùkò, aṣọ pupa, aṣọ funfun, ati irun ewúrẹ́; awọ àgbò tí wọ́n ṣe, tí ó jẹ́ pupa, ati ti ewúrẹ́, igi akasia; òróró fún àwọn fìtílà, ati àwọn èròjà olóòórùn dídùn fún òróró tí wọn ń ta sí eniyan lórí, ati turari, òkúta onikisi ati àwọn òkúta tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ ọnà sára efodu tí àwọn alufaa ń wọ̀, ati ohun tí wọn ń dà bo àyà; kí wọ́n sì ṣe ibùgbé fún mi, kí n lè máa gbé ààrin wọn. Bí mo ti júwe fún ọ gan-an ni kí o ṣe àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀.
Eks 25:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì wí fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn mú ọrẹ wá fún mi, ìwọ yóò gba ọrẹ náà fún mi ni ọwọ́ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ti ọkàn rẹ bá fẹ́ láti fi fún mi. “Wọ̀nyí ni ọrẹ ti ìwọ yóò gbà ni ọwọ́ wọn: “wúrà, fàdákà àti idẹ; aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó, ọ̀gbọ̀; irun ewúrẹ́. Awọ àgbò tí a rẹ ní pupa àti awọ ewúrẹ́ igbó; igi kasia; Òróró olifi fún iná títàn; òróró olóòórùn dídùn fún ìtasórí àti fún tùràrí olóòórùn dídùn; àti òkúta óníkìsì àti òkúta olówó iyebíye ti a fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí ara ẹ̀wù efodu àti ẹ̀wù ìgbàyà. “Nígbà náà ni ìwọ yóò jẹ́ kí wọn kọ́ ibi mímọ́ fún mi. Èmi yóò sì máa gbé ní àárín wọn. Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí ti mo fihàn ọ́, nípa àpẹẹrẹ àgọ́, àti àpẹẹrẹ gbogbo ohun èlò inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe é.