Eks 24:1-18
Eks 24:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI wi fun Mose pe, Goke tọ̀ OLUWA wá, iwọ, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli; ki ẹnyin ki o si ma sìn li òkere rére. Mose nikanṣoṣo ni yio si sunmọ OLUWA; ṣugbọn awọn wọnyi kò gbọdọ sunmọ tosi; bẹ̃li awọn enia kò gbọdọ bá a gòke lọ. Mose si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ OLUWA, ati gbogbo idajọ fun awọn enia: gbogbo enia si fi ohùn kan dahùn wipe, Gbogbo ọ̀rọ ti OLUWA wi li awa o ṣe. Mose si kọwe gbogbo ọ̀rọ OLUWA, o si dide ni kùtukutu owurọ̀, o si tẹ́ pẹpẹ kan nisalẹ òke na, o mọ ọwọ̀n mejila, gẹgẹ bi ẹ̀ya Israeli mejila. O si rán awọn ọdọmọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, nwọn si ru ẹbọ sisun, nwọn si fi akọmalu ru ẹbọ alafia si OLUWA. Mose si mú àbọ ẹ̀jẹ na o si fi i sinu awokòto; ati àbọ ẹ̀jẹ na o fi wọ́n ara pẹpẹ na. O si mú iwé majẹmu nì, o si kà a li eti awọn enia: nwọn si wipe, Gbogbo eyiti OLUWA wi li awa o ṣe, awa o si gbọràn. Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si wọ́n ọ sara awọn enia, o si wipe, Kiyesi ẹ̀jẹ majẹmu, ti OLUWA bá nyin dá nipasẹ ọ̀rọ gbogbo wọnyi. Nigbana ni Mose, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli gòke lọ: Nwọn si ri Ọlọrun Israeli; bi iṣẹ okuta Safire wà li abẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, o si dabi irisi ọrun ni imọ́toto rẹ̀. Kò si nà ọwọ́ rẹ̀ lé awọn ọlọlá ọmọ Israeli: nwọn si ri Ọlọrun, nwọn si jẹ, nwọn si mu. OLUWA si wi fun Mose pe, Gòke tọ̀ mi wá sori òke, ki o si duro nibẹ̀; emi o si fi walã okuta fun ọ, ati aṣẹ kan, ati ofin ti mo ti kọ, ki iwọ ki o le ma kọ́ wọn. Mose si dide, ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀: Mose si gòke lọ si oke Ọlọrun. O si wi fun awọn àgba na pe, Ẹ duro dè wa nihinyi, titi awa o fi tun pada tọ̀ nyin wá: si kiyesi i, Aaroni ati Huri mbẹ pẹlu nyin: bi ẹnikan ba li ọ̀ran kan, ki o tọ̀ wọn wá. Mose si gòke lọ sori òke na, awọsanma si bò òke na mọlẹ. Ogo OLUWA si sọkalẹ sori òke Sinai, awọsanma na si bò o mọlẹ ni ijọ́ mẹfa: ni ijọ́ keje o ké si Mose lati ãrin awọsanma wá. Iwò ogo OLUWA dabi iná ajonirun li ori òke na li oju awọn ọmọ Israeli. Mose si lọ sãrin awọsanma na, o sì gùn ori òke na: Mose si wà lori òke li ogoji ọsán ati ogoji oru.
Eks 24:1-18 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA wí fún Mose pé, “Ẹ gòkè tọ èmi OLUWA wá, ìwọ ati Aaroni, ati Nadabu, ati Abihu, ati aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli, kí ẹ sì sin èmi OLUWA ní òkèèrè. Ìwọ Mose nìkan ni kí o súnmọ́ mi, kí àwọn yòókù má ṣe súnmọ́ mi, má sì jẹ́ kí àwọn eniyan ba yín gòkè wá rárá.” Mose bá tọ àwọn eniyan náà lọ, ó sọ gbogbo ohun tí OLUWA sọ fún un fún wọn, ati gbogbo ìlànà tí ó là sílẹ̀, gbogbo àwọn eniyan náà sì fi ẹnu kò, wọ́n dáhùn pé, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe.” Mose bá kọ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ kutukutu, ó dìde, ó tẹ́ pẹpẹ kan sí ìsàlẹ̀ òkè náà, ó ri ọ̀wọ̀n mejila mọ́lẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan. Ó sì rán àwọn kan ninu àwọn ọdọmọkunrin Israẹli, pé kí wọ́n lọ fi mààlúù rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. Mose gba ìdajì ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran náà sinu àwo ńlá, ó sì da ìdajì yòókù sí ara pẹpẹ náà. Ó mú ìwé majẹmu náà, ó kà á sí etígbọ̀ọ́ gbogbo àwọn eniyan, wọ́n sì dáhùn pé, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe, a óo sì gbọ́ràn.” Ni Mose bá gba ẹ̀jẹ̀ ẹran yòókù tí ó wà ninu àwo, ó wọ́n ọn sí àwọn eniyan náà lára, ó ní, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí OLUWA bá yín dá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí mo sọ.” Mose ati Aaroni, ati Nadabu, ati Abihu, ati aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli bá gòkè lọ, wọ́n sì rí Ọlọrun Israẹli. Wọ́n rí kinní kan ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó dàbí pèpéle tí a fi òkúta safire ṣe, ó mọ́lẹ̀ kedere bí ojú ọ̀run. Ọlọrun kò sì pa àwọn àgbààgbà Israẹli náà lára rárá, wọ́n rí Ọlọrun, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu. OLUWA wí fún Mose pé, “Gun orí òkè tọ̀ mí wá, kí o dúró sibẹ, n óo sì kó wàláà tí wọ́n fi òkúta ṣe fún ọ, tí mo kọ àwọn òfin ati ìlànà sí, fún ìtọ́ni àwọn eniyan yìí.” Mose bá gbéra, òun ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ó gun orí òkè Ọlọrun lọ. Ó sọ fún àwọn àgbààgbà pé, “Ẹ dúró níhìn-ín dè wá títí a óo fi pada wá bá yín. Aaroni ati Huri wà pẹlu yín, bí ẹnikẹ́ni bá ní àríyànjiyàn kan, kí ó kó o tọ̀ wọ́n lọ.” Mose bá gun orí òkè náà lọ, ìkùukùu sì bo orí òkè náà. Ògo OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, ìkùukùu sì bò ó fún ọjọ́ mẹfa, ní ọjọ́ keje, OLUWA pe Mose láti inú ìkùukùu náà. Lójú àwọn eniyan Israẹli, ìrísí ògo OLUWA lórí òkè náà dàbí iná ńlá tí ń jóni ní àjórun. Mose wọ inú ìkùukùu náà lọ, ó gun orí òkè náà, ó sì wà níbẹ̀ fún ogoji ọjọ́, tọ̀sán-tòru.

Eks 24:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ìgbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Gòkè tọ OLúWA wá, ìwọ àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin (70) àwọn àgbàgbà Israẹli. Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré. Ṣùgbọ́n Mose nìkan ṣoṣo ni yóò súnmọ́ OLúWA; àwọn tókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò gbọdọ̀ gòkè wá pẹ̀lú rẹ̀.” Nígbà ti Mose lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ àti òfin OLúWA, wọ́n wí ní ohùn kan pé, “Gbogbo ohun ti OLúWA wí ni àwa yóò ṣe.” Nígbà náà ni Mose kọ gbogbo ohun tí OLúWA sọ sílẹ̀. Ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mọ pẹpẹ ni ẹsẹ̀ òkè náà. Ó ṣe ọ̀wọ́n òkúta méjìlá. Èyí ti ó dúró fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá. Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si OLúWA. Mose bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ. Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí OLúWA wí: Àwa yóò sì gbọ́rọ̀.” Nígbà náà ni Mose gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.” Mose àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli gòkè lọ. Wọ́n sì rí Ọlọ́run Israẹli. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta safire ṣe wà. Èyí ti ó mọ́ nigínnigín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnrarẹ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn àgbàgbà Israẹli wọ̀nyí; wọ́n ri Ọlọ́run, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu. OLúWA sì sọ fún Mose pé, “Gòkè wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí o sì dúró níhìn-ín. Èmi yóò sì fún ọ ní wàláà òkúta pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí mo ti kọ sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn.” Nígbà náà ni Mose jáde lọ pẹ̀lú Joṣua arákùnrin rẹ̀. Mose lọ sí orí òkè Ọlọ́run. Ó sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsi i, Aaroni àti Huri ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnìkan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ. Nígbà tí Mose gun orí òkè lọ, ìkùùkuu bo orí òkè náà. Ògo OLúWA sì wà ní orí òkè Sinai. Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni OLúWA kọ sí Mose láti inú ìkùùkuu náà wá. Ni ojú àwọn ọmọ Israẹli ògo OLúWA náà dàbí iná ajónirun ni orí òkè. Nígbà náà ni Mose wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.