Eks 22:1-31

Eks 22:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

BI ọkunrin kan ba ji akọmalu, tabi agutan kan, ti o si pa a, tabi ti o tà a; yio san akọmalu marun dipò akọmalu kan, ati agutan mẹrin dipò agutan kan. Bi a ba ri olè ti nrunlẹ wọle, ti a si lù u ti o kú, a ki yio ta ẹ̀jẹ silẹ fun u. Bi õrùn ba là bá a, a o ta ẹ̀jẹ silẹ fun u; sisan li on iba san; bi kò ni nkan, njẹ a o tà a nitori olè rẹ̀. Bi a ba ri ohun ti o ji na li ọwọ́ rẹ̀ nitõtọ li ãye, iba ṣe akọmalu, tabi kẹtẹkẹtẹ, tabi agutan; on o san a pada ni meji. Bi ọkunrin kan ba mu ki a jẹ oko tabi agbalá-àjara kan, ti o si tú ẹran rẹ̀ silẹ, ti o si jẹ li oko ẹlomiran; ninu ãyo oko ti ara rẹ̀, ati ninu ãyo agbalá-àjara tirẹ̀, ni yio fi san ẹsan. Bi iná ba ṣẹ̀, ti o si mu ẹwọn, ti abà ọkà, tabi ọkà aiṣá, tabi oko li o joná; ẹniti o ràn iná na yio san ẹsan nitõtọ. Bi ẹnikan ba fi owo tabi ohunèlo fun ẹnikeji rẹ̀ pamọ́; ti a ji i ni ile ọkunrin na; bi a ba mu olè na, ki o san a ni meji. Bi a kò ba mú olè na, njẹ ki a mú bale na wá siwaju awọn onidajọ, bi on kò ba fọwọkàn ẹrù ẹnikeji rẹ̀. Nitori irú ẹ̀ṣẹ gbogbo, iba ṣe ti akọmalu, ti kẹtẹkẹtẹ, ti agutan, ti aṣọ, tabi ti irũru ohun ti o nù, ti ẹlomiran pè ni ti on, ẹjọ́ awọn mejeji yio wá siwaju awọn onidajọ; ẹniti awọn onidajọ ba dẹbi fun, on o san a ni iṣẹmeji fun ẹnikeji rẹ̀. Bi enia ba fi kẹtẹkẹtẹ, tabi akọmalu, tabi agutan, tabi ẹrankẹran lé ẹnikeji rẹ̀ lọwọ lati ma sìn; ti o ba si kú, tabi ti o farapa, tabi ti a lé e sọnù, ti ẹnikan kò ri i; Ibura OLUWA yio wà lãrin awọn mejeji, pe, on kò fọwọkàn ẹrù ẹnikeji on; ki on ki o si gbà, on ki yio si san ẹsan. Bi o ba ṣepe a ji i lọwọ rẹ̀, on o san ẹsan fun oluwa rẹ̀. Bi o ba ṣepe a si fà a ya, njẹ ki o mú u wa ṣe ẹrí, on ki yio si san ẹsan eyiti a fàya. Bi enia ba si yá ohun kan lọwọ ẹnikeji rẹ̀, ti o si farapa, tabi ti o kú, ti olohun kò si nibẹ̀, on o san ẹsan nitõtọ. Ṣugbọn bi olohun ba wà nibẹ̀, on ki yio san ẹsan: bi o ba ṣe ohun ti a fi owo gbà lò ni, o dé fun owo igbàlo rẹ̀. Bi ọkunrin kan ba si tàn wundia kan ti a kò ti ifẹ́, ti o si mọ̀ ọ, fifẹ́ ni yio si fẹ́ ẹ li aya rẹ̀. Bi baba rẹ̀ ba kọ̀ jalẹ lati fi i fun u, on o san ojì gẹgẹ bi ifẹ́ wundia. Iwọ kò gbọdọ jẹ ki ajẹ́ ki o wà lãye. Ẹnikẹni ti o ba bá ẹranko dàpọ pipa li a o pa a. Ẹnikẹni ti o ba rubọ si oriṣakoriṣa, bikoṣe si JEHOFA nikanṣoṣo, a o pa a run tútu. Iwọ kò gbọdọ ṣìka si alejò, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ni i lara: nitoripe alejò li ẹnyin ti jẹ́ ni ilẹ Egipti. Ẹnyin kò gbọdọ jẹ opó ni ìya, tabi ọmọ alainibaba. Bi iwọ ba jẹ wọn ni ìyakiya, ti nwọn si kigbe pè mi, emi o gbọ́ igbe wọn nitõtọ. Ibinu mi yio si gboná, emi o si fi idà pa nyin; awọn aya nyin yio si di opó, awọn ọmọ nyin a si di alainibaba. Bi iwọ ba yá ẹnikẹni ninu awọn enia mi li owo ti o ṣe talaka lọdọ rẹ, iwọ ki yio jẹ́ bi agbẹ̀da fun u; bẹ̃ni iwọ ki yio gbẹ̀da lọwọ rẹ̀. Bi o ba ṣepe iwọ gbà aṣọ ẹnikeji rẹ ṣe ògo, ki iwọ ki o si fi i fun u, ki õrùn to wọ̀: Nitori kìki eyi ni ibora rẹ̀, aṣọ rẹ̀ ti yio fi bora ni: kini on o fi bora sùn? yio si ṣe bi o ba kigbe pè mi, emi o gbọ́; nitori alãnu li emi. Iwọ kò gbọdọ gàn awọn onidajọ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bú ijoye kan ninu awọn enia rẹ. Iwọ kò gbọdọ jafara lati mú irè oko rẹ wá, ati ọti rẹ. Akọ́bi awọn ọmọ rẹ ọkunrin ni iwọ o fi fun mi. Bẹ̃ gẹgẹ ni ki iwọ ki o fi akọmalu ati agutan rẹ ṣe: ijọ́ meje ni ki o ba iya rẹ̀ gbọ́; ni ijọ́ kẹjọ ni ki iwọ ki o fi i fun mi. Ẹnyin o si jẹ́ enia mimọ́ fun mi; nitorina ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹran ti a ti ọwọ ẹranko igbẹ́ fàya; ajá ni ki ẹnyin ki o wọ́ ọ fun.

Eks 22:1-31 Yoruba Bible (YCE)

“Bí ẹnìkan bá jí akọ mààlúù kan tabi aguntan kan gbé, tí ó bá pa á, tabi tí ó tà á, yóo san akọ mààlúù marun-un dípò ẹyọ kan ati aguntan mẹrin dípò aguntan kan. Tí kò bá ní ohun tí yóo fi tán ọ̀ràn náà, wọn yóo ta òun fúnra rẹ̀ láti san ohun tí ó jí. Bí a bá ká olè mọ́ ibi tí ó ti ń fọ́lé lóru, tí a sì lù ú pa, ẹni tí ó lù ú pa kò jẹ̀bi. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ pé lojumọmọ ni, ẹ̀bi wà fún ẹni tí ó lù ú pa. Ṣugbọn tí ọwọ́ bá tẹ olè lojumọmọ, ó níláti san ohun tí ó jí pada. Bí wọ́n bá ká ẹran ọ̀sìn tí olè jí gbé mọ́ ọn lọ́wọ́ láàyè, kì báà ṣe akọ mààlúù, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tabi aguntan; ìlọ́po meji ni yóo fi san pada. “Bí ẹnìkan bá jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ jẹ oko olóko, tabi ọgbà àjàrà ẹlòmíràn, tabi tí ó bá da ẹran wọ inú oko olóko tí wọ́n sì jẹ nǹkan ọ̀gbìn inú rẹ̀, ibi tí ó dára jùlọ ninu oko tabi ọgbà àjàrà tirẹ̀ ni yóo fi dí i fún ẹni tí ó ni oko tabi ọgbà àjàrà tí ẹran rẹ̀ jẹ. “Bí ẹnìkan bá dáná, tí iná náà bá ràn mọ́ koríko, tí ó bá jó oko olóko, tí ó sì jó ọkà tí wọ́n ti kórè jọ tabi tí ó wà lóòró, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ san òmíràn pada fún olóko. “Bí ẹnìkan bá fi owó tabi ìṣúra kan pamọ́ sí ọwọ́ aládùúgbò rẹ̀, tí olè bá gbé e lọ mọ́ aládùúgbò rẹ̀ yìí lọ́wọ́, bí ọwọ́ bá tẹ olè yìí, ìlọ́po meji ohun tí ó gbé ni yóo fi san. Bí ọwọ́ kò bá wá tẹ olè, ẹni tí ó gba ìṣúra pamọ́ yìí gbọdọ̀ wá sí ilé Ọlọrun kí ó fi Ọlọrun ṣẹ̀rí pé òun kò fi ọwọ́ kan ìṣúra tí aládùúgbò òun fi pamọ́ sí òun lọ́wọ́. “Nígbàkúùgbà tí ohun ìní bá di àríyànjiyàn láàrin eniyan meji, kì báà jẹ́ mààlúù, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tabi aguntan, tabi aṣọ, tabi ohunkohun tí ó bá ti sọnù, tí ó sì di àríyànjiyàn, àwọn mejeeji tí wọn ń lọ́ nǹkan mọ́ ara wọn lọ́wọ́ gbọdọ̀ wá sí ilé Ọlọrun, kí wọ́n sì fi Ọlọrun ṣẹ̀rí, ẹni tí Ọlọrun bá dá lẹ́bi yóo san ìlọ́po meji nǹkan náà fún ẹnìkejì rẹ̀. “Bí ẹnìkan bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní ẹran sìn, kì báà ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi mààlúù, tabi aguntan, bí ẹran náà bá kú tabi kí ó farapa, tabi tí ó bá rìn lọ tí kò sì sí ẹni tí ó rí i, aládùúgbò náà yóo lọ sí ilé Ọlọrun, yóo sì fi OLUWA ṣẹ̀rí pé òun kọ́ ni òun jí ẹran tí wọn fún òun sìn. Ẹni tí ó fún un ní ẹran sìn yóo faramọ́ ìbúra yìí, kò sì ní gbẹ̀san mọ́. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé wọ́n jí i gbé mọ́ ọn lọ́wọ́ ni, yóo san ẹ̀san fún ẹni tí ó ni ín. Bí ó bá jẹ́ pé ẹranko burúkú ni ó pa á, bí ó bá ní ohun tí ó lè fi ṣe ẹ̀rí, tí ó sì fi ohun náà han ẹni tí ó ni ẹran náà, kò ní san ẹ̀san ẹran náà pada. “Bí ẹnìkan bá yá ẹran ọ̀sìn kẹ́ran ọ̀sìn lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹran náà bá farapa tabi tí ó kú, tí kò sì sí olówó ẹran náà níbẹ̀, ẹni tí ó yá ẹran náà níláti san án pada. Ṣugbọn bí ẹni tí ó ni ẹran náà bá wà níbẹ̀ nígbà tí ó kú, ẹni tí ó yá a kò ní san ẹ̀san pada. Bí ó bá jẹ́ pé owó ni wọ́n fi yá ẹran náà lọ tí ó fi kú, a jẹ́ pé orí iṣẹ́ owó rẹ̀ ni ó kú sí. “Bí ẹnìkan bá tan wundia tí kì í ṣe àfẹ́sọ́nà ẹnikẹ́ni, tí ó sì bá wundia náà lòpọ̀, ó gbọdọ̀ san owó orí rẹ̀ kí ó sì gbé e níyàwó. Bí baba wundia náà bá kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò ní fi ọmọ òun fún un, yóo san iye owó tí wọ́n bá ń san ní owó orí wundia tí kò mọ ọkunrin. “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àjẹ́ wà láàyè. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹranko lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa á. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá rúbọ sí oriṣa-koriṣa kan lẹ́yìn OLUWA, píparun ni kí wọ́n pa á run. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú tabi kí ó ni ín lára, nítorí pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fìyà jẹ opó tabi aláìníbaba. Bí ẹnikẹ́ni bá fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n bá ké pè mí, dájúdájú n óo gbọ́ igbe wọn; ibinu mi yóo sì ru sí yín, n óo fi idà pa yín, àwọn aya yín yóo di opó, àwọn ọmọ yín yóo sì di aláìníbaba. “Bí o bá yá ẹnikẹ́ni lówó ninu àwọn eniyan mi, tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, tí ó ṣe aláìní, má ṣe bí àwọn tí wọn ń fi owó wọn gba èlé, má gba èlé lórí owó tí o yá a. Bí aládùúgbò rẹ bá fi ẹ̀wù rẹ̀ dógò lọ́dọ̀ rẹ, tí o sì gbà á, dá a pada fún un kí oòrùn tó wọ̀; nítorí pé ẹ̀wù yìí ni àwọ̀lékè kan ṣoṣo tí ó ní, òun kan náà sì ni aṣọ ìbora rẹ̀. Àbí aṣọ wo ni ó tún ní tí yóo fi bora sùn? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ké pè mí, n óo dá a lóhùn, nítorí pé aláàánú ni mí. “O kò gbọdọ̀ kẹ́gàn Ọlọrun, o kò sì gbọdọ̀ gbé ìjòyè àwọn eniyan rẹ ṣépè. “O kò gbọdọ̀ jáfara láti mú ninu ọpọlọpọ ọkà rẹ ati ọpọlọpọ ọtí waini rẹ láti fi rúbọ sí mi. “O níláti fún mi ní àkọ́bí rẹ ọkunrin pẹlu. Bákan náà ni àkọ́bí mààlúù rẹ ati ti aguntan rẹ, tí wọ́n bá jẹ́ akọ. Fi wọ́n sílẹ̀ pẹlu ìyá wọn fún ọjọ́ meje, ní ọjọ́ kẹjọ o níláti fi wọ́n rúbọ sí mi. “Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí a yà sọ́tọ̀ fún mi, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ òkú ẹran tí ẹranko bá pa ninu ìgbẹ́, ajá ni kí ẹ gbé irú ẹran bẹ́ẹ̀ fún.

Eks 22:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Bí ọkùnrin kan bá jí akọ màlúù tàbí àgùntàn, tí ó sì pa á tàbí tà á. Ó gbọdọ̀ san akọ màlúù márùn-ún padà fún ọ̀kan tí ó jí, àti àgùntàn mẹ́rin mìíràn fún ọ̀kan tí ó jí. “Bí a bá mú olè níbi ti ó ti ń fọ́lé, ti a sì lù ú pa, ẹni tí ó lù ú pa náà kò ní ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ti ó bá ṣẹlẹ̀ ni ojú ọ̀sán, a ó kà á si ìpànìyàn. Ọkùnrin ti ó lù ú pa náà yóò ni ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀. “Olè gbọdọ̀ san ohun tí ó jí padà. Ṣùgbọ́n tí kò bá ni ohun ti ó lè fi san án padà, a ó tà á, a ó sì fi sanwó ohun tí ó jí gbé padà. Bí a bá rí ẹran tí ó jí gbé náà ni ọwọ́ rẹ̀ ní ààyè: ìbá ṣe akọ màlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àgùntàn, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì. “Bí ọkùnrin kan bá ń bọ́ ẹran ọ̀sìn rẹ̀ lórí pápá tàbí nínú ọgbà àjàrà, tí ó sì jẹ́ kí ó lọ jẹ nínú oko ẹlòmíràn, a ó mú kí ó san ohun ti ẹran rẹ̀ jẹ padà pẹ̀lú èyí tí ó dára jù nínú oko tàbí nínú ọgbà rẹ̀ (ẹlòmíràn padà fún un). “Bí iná bá ṣẹ́ tí ó kán lu igbó tí ó sì jó àká ọkà tàbí gbogbo oko náà, ẹni tí iná ṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ yóò san ohun tí iná ti ó ṣẹ́ jó padà. “Bí ọkùnrin kan bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní fàdákà tàbí ohun èlò fún ìtọ́jú, ti wọ́n sì jí gbé lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí a bá mú irú olè bẹ́ẹ̀, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì. Ṣùgbọ́n ti a kò bá rí olè náà mú, baálé ilé náà yóò fi ara hàn níwájú ìdájọ́ láti jẹ́ kí a mọ̀ bí òun fúnrarẹ̀ ni ó gbé ohun ti ó sọnù náà. Bí ẹnìkan bá ni akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, aṣọ tàbí ohun ìní mìíràn tí ó sọnù ní ọ̀nà ti kò bá òfin mu, tí a sì rí ẹni ti ó sọ pé òun ni ó ní ín, àwọn méjèèjì yóò mú ẹjọ́ wọn wá sí iwájú adájọ́. Ẹnikẹ́ni tí adájọ́ bá dá lẹ́bi yóò san án ni ìlọ́po méjì padà fún ẹnìkejì rẹ̀. “Bí ẹnikẹ́ni bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, akọ màlúù, àgùntàn tàbí ẹranko mìíràn láti bá òun tọ́jú rẹ̀, tí ó sì kú, tàbí tí ó fi ara pa, tàbí tí a jí gbé, níbi tí kò ti sí ẹni tí o ṣe àkíyèsí. Wọn yóò búra sí ọ̀rọ̀ náà láàrín ara wọn ni iwájú OLúWA láti fihàn pé òun kò ní ọwọ́ nínú sísọnù ohun ọ̀sìn náà, olóhun gbọdọ̀ gba bẹ́ẹ̀, a kò sì ní san ohunkóhun fún un. Ṣùgbọ́n ti wọ́n bá jí ẹranko náà gbé ni ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, yóò san ẹ̀san padà fún olúwa rẹ̀. Bí ẹranko búburú bá fà á ya, ó ní láti mú àyakù ẹran náà wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, kò sì ní san ẹran náà padà. “Bí ẹnìkan bá sì yá ẹranko lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹranko náà sì fi ara pa, tàbí kí ó kú nígbà tí ẹni tí ó ni í kò sí nítòsí. O gbọdọ̀ san án padà. Ṣùgbọ́n ti ó bá jẹ́ wí pé olóhun bá wà pẹ̀lú ẹranko náà, ẹni tí ó ya lò kò ní san ẹ̀san padà. Bí a bá yá ẹranko náà lò, owó tí ó fi yá a lò ni yóò fi tan àdánù ẹranko tí ó kú. “Bí ọkùnrin kan bá fi àrékérekè mú wúńdíá kan, ẹni tí kò pinnu láti fẹ́, tí ó sì bá a lòpọ̀, yóò san owó orí rẹ̀, yóò sì fi ṣe aya rẹ̀. Bí baba ọmọbìnrin náà bá kọ̀ jálẹ̀ láti fi fún un ní aya, ó ni láti san owó tó tó owó orí rẹ̀ fún fífẹ́ ẹ ní wúńdíá. “Má ṣe jẹ́ kí àjẹ́ kí ó wà láààyè. “Ẹnikẹ́ni ti ó bá bá ẹranko lòpọ̀ ní a ó pa. “Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú ẹbọ sí òrìṣà yàtọ̀ sí OLúWA nìkan, ni a ó yà sọ́tọ̀ fún ìparun. “Ẹ má ṣe fi ìyà jẹ àlejò tàbí ni wọ́n lára, nítorí ìwọ pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì ni ilẹ̀ Ejibiti rí. “Má ṣe yan opó tàbí ọmọ òrukàn jẹ. Bí ìwọ bá ṣe bẹ́ẹ̀, bí wọn bá ké pè mi. Èmi yóò sì gbọ́ ohùn igbe wọn. Ìbínú mi yóò ru sókè. Èmi yóò sì fi idà pa ọ. Ìyàwó rẹ yóò di opó, àwọn ọmọ rẹ yóò sì di aláìní baba. “Bí ìwọ bá yá ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn mi tí ìyà ń jẹ láàrín yín lówó, má ṣe dàbí ayánilówó, kí o má sì gba èlé. Bí ìwọ bá gba aṣọ aládùúgbò rẹ ni ẹ̀jẹ́, ìwọ gbọdọ̀ fún un padà kí oòrùn tó ó wọ̀, Nítorí aṣọ yìí nìkan ní ó ní ti ó lè fi bo àṣírí ara. Kí ni ohun mìíràn ti yóò fi sùn? Nígbà ti ó bá gbé ohun rẹ̀ sókè sí mi, èmi yóò gbọ́ nítorí aláàánú ni èmi. “Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run tàbí gégùn lé orí ìjòyè àwọn ènìyàn rẹ. “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́ra láti mú ọrẹ wá fún mi láti inú ìre oko rẹ àti láti inú wáìnì rẹ. “Àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin ni ìwọ yóò fi fún mi. Ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú agbo màlúù rẹ àti agbo àgùntàn rẹ. Jẹ́ kí wọn wà lọ́dọ̀ ìyá wọn fún ọjọ́ méje, kí ìwọ kí ó sì fi wọ́n fún mi ní ọjọ́ kẹjọ. “Ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mímọ́ mi. Nítorí náà má ṣe jẹ ẹran ti ẹranko búburú fàya: ẹ fi fún ajá jẹ.