Eks 20:1-23

Eks 20:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌLỌRUN si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi pe, Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ jade lati ilẹ Egipti, lati oko-ẹrú jade wá. Iwọ kò gbọdọ lí Ọlọrun miran pẹlu mi. Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti mbẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti mbẹ ninu omi ni isalẹ̀ ilẹ. Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori ara rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitori emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, lati irandiran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi; Emi a si ma fi ãnu hàn ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si npa ofin mi mọ́. Iwọ kò gbọdọ pè orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ lasan; nitoriti OLUWA ki yio mu awọn ti o pè orukọ rẹ̀ lasan bi alailẹ̀ṣẹ li ọrùn. Ranti ọjọ́ isimi, lati yà a simimọ́. Ọjọ́ mẹfa ni iwọ o ṣiṣẹ, ti iwọ o si ṣe iṣẹ rẹ gbogbo: Ṣugbọn ọjọ́ keje li ijọ́ isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ohunọ̀sin rẹ, ati alejò rẹ̀ ti mbẹ ninu ibode rẹ: Nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, okun ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn, o si simi ni ijọ́ keje: nitorina li OLUWA ṣe busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́. Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. Iwọ kò gbọdọ pania. Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga. Iwọ kò gbọdọ jale. Iwọ kò gbọdọ jẹri eke si ẹnikeji rẹ. Iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si aya ẹnikeji rẹ, tabi si ọmọ-ọdọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ-ọdọ rẹ̀ obinrin, akọmalu rẹ̀, kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, tabi ohun gbogbo ti iṣe ti ẹnikeji rẹ. Gbogbo awọn enia na si ri ãrá na, ati mànamána na, ati ohùn ipè na, nwọn ri oke na nṣe ẽfi: nigbati awọn enia si ri i, nwọn ṣí, nwọn duro li òkere rére. Nwọn si wi fun Mose pe, Iwọ ma bá wa sọ̀rọ̀, awa o si gbọ́: ṣugbọn máṣe jẹ ki Ọlọrun ki o bá wa sọ̀rọ, ki awa ki o má ba kú. Mose si wi fun awọn enia pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitoriti Ọlọrun wá lati dan nyin wò, ati ki ẹ̀ru rẹ̀ ki o le ma wà li oju nyin, ki ẹnyin ki o máṣe ṣẹ̀. Awọn enia si duro li òkere rére, Mose si sunmọ ibi òkunkun ṣiṣu na nibiti Ọlọrun gbé wà. OLUWA si wi fun Mose pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin ri bi emi ti bá nyin sọ̀rọ lati ọrun wá. Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ọlọrun miran pẹlu mi; Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ọlọrun fadaka, tabi ọlọrun wurà, fun ara nyin.

Eks 20:1-23 Yoruba Bible (YCE)

Ọlọrun sì sọ ọ̀rọ̀ wọnyii, ó ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ní oko ẹrú tí ẹ wà: “O kò gbọdọ̀ ní ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. “O kò gbọdọ̀ yá èrekére fún ara rẹ, kì báà ṣe àwòrán ohun tí ó wà ní òkè ọ̀run, tabi ti ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀, tabi ti ohun tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀. O kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bọ wọ́n; nítorí Ọlọrun tí í máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ẹ̀ṣẹ̀ baba bi ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ẹkẹrin lára àwọn tí wọ́n kórìíra mi. Ṣugbọn èmi a máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn tí wọ́n fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́. “O kò gbọdọ̀ pe orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ lásán, nítorí pé, èmi OLUWA yóo dá ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ mi lásán lẹ́bi. “Ranti ọjọ́ ìsinmi kí o sì yà á sí mímọ́. Ọjọ́ mẹfa ni kí olukuluku máa fi ṣiṣẹ́, kí ó sì máa fi parí ohun tí ó bá níláti ṣe. Ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí olukuluku níláti yà sọ́tọ̀ fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà; olukuluku yín ati ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, ati ẹrú rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, ati ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati àlejò tí ó wà ninu ilé rẹ̀. Nítorí pé, ọjọ́ mẹfa ni èmi OLUWA fi dá ọ̀run ati ayé, ati òkun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn; mo sì sinmi ní ọjọ́ keje. Nítorí náà ni mo ṣe bukun ọjọ́ ìsinmi náà, tí mo sì yà á sí mímọ́. “Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn lórí ilẹ̀ tí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ fi fún ọ. “O kò gbọdọ̀ paniyan. “O kò gbọdọ̀ ṣe panṣaga. “O kò gbọdọ̀ jalè. “O kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnikeji rẹ. “O kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ọmọnikeji rẹ, tabi sí aya rẹ̀ tabi sí iranṣẹ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, tabi sí akọ mààlúù rẹ̀, tabi sí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tabi sí ohunkohun tí ó jẹ́ ti ọmọnikeji rẹ.” Nígbà tí àwọn eniyan náà gbọ́ bí ààrá ti ń sán, tí wọ́n rí i bí mànàmáná ti ń kọ, tí wọ́n gbọ́ dídún ìró fèrè, tí wọ́n rí i tí òkè ń rú èéfín, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì wárìrì. Wọ́n dúró lókèèrè, wọ́n sì wí fún Mose pé, “Ìwọ ni kí o máa bá wa sọ̀rọ̀, a óo máa gbọ́; má jẹ́ kí Ọlọrun bá wa sọ̀rọ̀ mọ́, kí a má baà kú.” Mose bá dá àwọn eniyan náà lóhùn pé, “Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín, Ọlọrun wá dán yín wò ni, kí ẹ lè máa bẹ̀rù rẹ̀, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀.” Àwọn eniyan náà dúró lókèèrè, bí Mose tí ń súnmọ́ òkùnkùn biribiri tí ó ṣú bo ibi tí Ọlọrun wà. OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Ẹ ti rí i fúnra yín pé mo ba yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá. Ẹ kò gbọdọ̀ fi wúrà tabi fadaka yá ère láti máa bọ, àfi èmi nìkan ni kí ẹ máa sìn.

Eks 20:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọlọ́run sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé: “Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi OLúWA Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi. Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́. Ẹ má ṣe ṣi orúkọ OLúWA Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi. Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́. Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ, Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi OLúWA Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ, tí ń bẹ nínú ibodè rẹ. Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni OLúWA dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ó sì sinmi ní ọjọ́ keje: nítorí náà ni OLúWA ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́. Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí OLúWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ. Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà. Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéjì rẹ.” Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n ṣìgàṣìgà fún ìbẹ̀rù. Wọ́n wí fún Mose pé, “Ìwọ fúnrarẹ̀ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.” Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣẹ̀.” Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mose súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà. OLúWA sì sọ fún Mose pé, “Sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli: ‘Ẹ̀yin ti rí i fúnrayín bí èmi ti bá a yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi: ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín.