Eks 2:3-4
Eks 2:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati kò si le pa a mọ́ mọ́, o ṣe apoti ẽsu fun u, o si fi ọ̀da ilẹ ati oje igi ṣán a; o si tẹ́ ọmọ na sinu rẹ̀; o si gbé e sinu koriko odò li ẹba odò na. Arabinrin rẹ̀ si duro li òkere, lati mọ̀ ohun ti yio ṣe ọmọ na.
Pín
Kà Eks 2Eks 2:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí kò lè gbé e pamọ́ mọ́, ó fi koríko kan tí ó dàbí èèsún ṣe apẹ̀rẹ̀ kan, ó fi oje igi ati ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ, ó gbé ọmọ náà sinu rẹ̀, ó sì gbé apẹ̀rẹ̀ náà sí ààrin koríko lẹ́bàá odò. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obinrin dúró ní òkèèrè, ó ń wo ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i.
Pín
Kà Eks 2Eks 2:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé papirusi hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà àti òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú eèsún ni etí odò Naili. Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà.
Pín
Kà Eks 2