Eks 2:11-15
Eks 2:11-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe li ọjọ́ wọnni, ti Mose dàgba, o jade tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wò iṣẹ wọn: o si ri ara Egipti kan o nlù Heberu kan, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀. O si wò ihin, o wò ọhún, nigbati o si ri pe, kò si ẹnikan, o lù ara Egipti na pa, o si bò o ninu yanrin. Nigbati o si jade lọ ni ijọ́ keji, kiyesi i, ọkunrin meji ara Heberu mbá ara wọn jà: o si wi fun ẹniti o firan si ẹnikeji rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nlù ẹgbẹ rẹ? On si wipe, Tali o fi ọ jẹ́ olori ati onidajọ lori wa? iwọ fẹ́ pa mi bi o ti pa ara Egipti? Mose si bẹ̀ru, o si wipe, Lõtọ ọ̀ran yi di mimọ̀. Nigbati Farao si gbọ́ ọ̀ran yi, o nwá ọ̀na lati pa Mose. Ṣugbọn Mose sá kuro niwaju Farao, o si ngbé ilẹ Midiani: o si joko li ẹba kanga kan.
Eks 2:11-15 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Mose dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ó sì rí i bí ìyà tí ń jẹ wọ́n. Ó rí i tí ará Ijipti kan ń lu ọ̀kan ninu àwọn Heberu, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nígbà tí ó wo ọ̀tún, tí ó wo òsì, tí kò rí ẹnìkankan, ó lu ará Ijipti náà pa, ó sì bò ó mọ́ inú yanrìn. Nígbà tí ó tún jáde lọ ní ọjọ́ keji, ó rí i tí àwọn Heberu meji ń jà; ó bá bi ẹni tí ó jẹ̀bi pé, “Kí ló dé tí o fi ń lu ẹnìkejì rẹ?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Ta ló fi ọ́ jẹ olórí ati onídàájọ́ wa? Ṣé o fẹ́ pa èmi náà bí o ti pa ará Ijipti níjelòó ni?” Ẹ̀rù ba Mose, ó sì rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Láìsí àní àní, ọ̀rọ̀ yìí ti di mímọ̀.” Nígbà tí Farao gbọ́, ó ń wá ọ̀nà àtipa Mose. Ṣugbọn Mose sálọ mọ́ ọn lọ́wọ́, ó lọ sí ilẹ̀ Midiani, ó sì jókòó lẹ́bàá kànga kan.
Eks 2:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mose ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, O ri ará Ejibiti tí ń lu ará Heberu, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó wo ìhín, ó wo ọ̀hún, nígbà tí kò rí ẹnìkankan, ni ó bá pa ará Ejibiti náà, ó sì bò ó mọ́ inú iyanrìn. Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Heberu méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Heberu arákùnrin rẹ?” Ọkùnrin náà sì dáhùn pé “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mose, ó sì wí pé, “lóòótọ́ ni ọ̀ràn yìí ti di mí mọ̀.” Nígbà ti Farao sì gbọ́ nípa èyí, ó wá ọ̀nà láti pa Mose, ṣùgbọ́n Mose sá kúrò ní àrọ́wọ́tó o Farao, ó lọ sí Midiani láti máa gbé, nígbà tí ó dé bẹ̀, ó jókòó ni ẹ̀bá a kànga kan.