Eks 18:19-23
Eks 18:19-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Fetisilẹ nisisiyi si ohùn mi; emi o fun ọ ni ìmọ, Ọlọrun yio si pẹlu rẹ: iwọ wà niwaju Ọlọrun fun awọn enia yi, ki iwọ ki o ma mú ọ̀ran wọn wá si ọdọ Ọlọrun. Ki o si ma kọ́ wọn ni ìlana ati ofin wọnni, ki o si ma fi ọ̀na ti nwọn o ma rìn hàn fun wọn ati iṣẹ ti nwọn o ma ṣe. Pẹlupẹlu iwọ o si ṣà ninu gbogbo awọn enia yi awọn ọkunrin ti o to, ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awọn ọkunrin olõtọ, ti o korira ojukokoro; irú awọn wọnni ni ki o fi jẹ́ olori wọn, lati ṣe olori ẹgbẹgbẹrun, ati olori ọrọrún, ati olori arãdọta, ati olori mẹwamẹwa. Ki nwọn ki o si ma ṣe idajọ awọn enia nigbakugba: yio si ṣe, gbogbo ẹjọ́ nla ni ki nwọn ki o ma mú tọ̀ ọ wá, ṣugbọn gbogbo ẹjọ́ kekeké ni ki nwọn ki o ma dá: yio si rọrùn fun iwọ tikalarẹ, nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù na. Bi iwọ ba jẹ ṣe nkan yi, bi Ọlọrun ba si fi aṣẹ fun ọ bẹ̃, njẹ iwọ o le duro pẹ, ati gbogbo awọn enia yi pẹlu ni yio si dé ipò wọn li alafia.
Eks 18:19-23 Yoruba Bible (YCE)
Gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí, ìmọ̀ràn ni mo fẹ́ gbà ọ́, Ọlọrun yóo sì wà pẹlu rẹ. Ó dára kí o máa ṣe aṣojú àwọn eniyan náà níwájú Ọlọrun, kí o sì máa bá wọn kó ẹ̀dùn ọkàn wọn tọ Ọlọrun lọ; ó sì dára bákan náà pẹlu kí o máa kọ́ wọn ní òfin ati ìlànà, kí o sì máa fi ọ̀nà tí wọn yóo tọ̀ hàn wọ́n, ati ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe. Ohun tí ó yẹ kí o ṣe nìyí, yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jẹ́ alákòóso, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun, tí wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, tí wọ́n sì kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀; fi wọ́n ṣe alákòóso àwọn eniyan wọnyi, fi àwọn kan ṣe alákòóso lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn kan lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn kan lórí araadọta, ati àwọn mìíràn lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá. Jẹ́ kí wọn máa ṣe onídàájọ́ fún àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá jẹ́ pataki pataki nìkan ni wọn yóo máa kó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, kí wọ́n máa parí àwọn ẹjọ́ kéékèèké láàrin ara wọn. Èyí yóo mú kí ó rọ̀ ọ́ lọ́rùn, wọn yóo sì máa bá ọ gbé ninu ẹrù náà. Bí Ọlọrun bá gbà fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí o sì ṣe é, ẹ̀mí rẹ yóo gùn, gbogbo àwọn eniyan wọnyi náà yóo sì pada sí ilé wọn ní alaafia.”
Eks 18:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nísinsin yìí, fetísílẹ̀ sí mi, èmi yóò sì gbà ọ́ ni ìmọ̀ràn, Ọlọ́run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ. Ìwọ gbọdọ̀ jẹ́ aṣojú àwọn ènìyàn wọ̀nyí níwájú Ọlọ́run, ìwọ yóò sì mú èdè-àìyedè wá sí iwájú rẹ̀. Kọ́ wọn ní òfin àti ìlànà Ọlọ́run, fi ọ̀nà igbe ayé ìwà-bí-Ọlọ́run hàn wọ́n àti iṣẹ́ tí wọn yóò máa ṣe. Ṣa àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn: àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòtítọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ: yàn wọ́n ṣe olórí: lórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún-ọgọ́rùn-ún, àádọ́ta-dọ́ta àti mẹ́wàá mẹ́wàá. Jẹ́ kí wọn ó máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ni gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn mú ẹjọ́ tí ó bá nira fún wọn láti dá tọ̀ ọ́ wá; kí wọn kí ó máa dá ẹjọ́ kéékèèkéé. Èyí ni yóò mú iṣẹ́ rẹ rọrùn, wọn yóò sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí ìdájọ́ ṣíṣe. Bí ìwọ bá ṣe èyí, bí Ọlọ́run bá sì fi àṣẹ sí i fún ọ bẹ́ẹ̀, àárẹ̀ kò sì ní tètè mu ọ, àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò sì padà lọ ilé wọn ni àlàáfíà.”