Eks 18:13-26

Eks 18:13-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe ni ijọ́ keji ni Mose joko lati ma ṣe idajọ awọn enia: awọn enia si duro tì Mose lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ. Nigbati ana Mose si ri gbogbo eyiti on nṣe fun awọn enia, o ni, Kili eyiti iwọ nṣe fun awọn enia yi? ẽṣe ti iwọ nikan fi dá joko, ti gbogbo enia si duro tì ọ, lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ? Mose si wi fun ana rẹ̀ pe, Nitoriti awọn enia ntọ̀ mi wá lati bère lọwọ Ọlọrun ni: Nigbati nwọn ba li ẹjọ́, nwọn a tọ̀ mi wá; emi a si ṣe idajọ larin ẹnikini ati ẹnikeji, emi a si ma mú wọn mọ̀ ìlana Ọlọrun, ati ofin rẹ̀. Ana Mose si wi fun u pe, Eyiti iwọ nṣe nì kò dara. Dajudaju iwọ o dá ara rẹ lagara, ati iwọ, ati awọn enia yi ti o pẹlu rẹ: nitoriti nkan yi wuwo jù fun ọ; iwọ nikan ki yio le ṣe e tikalãrẹ. Fetisilẹ nisisiyi si ohùn mi; emi o fun ọ ni ìmọ, Ọlọrun yio si pẹlu rẹ: iwọ wà niwaju Ọlọrun fun awọn enia yi, ki iwọ ki o ma mú ọ̀ran wọn wá si ọdọ Ọlọrun. Ki o si ma kọ́ wọn ni ìlana ati ofin wọnni, ki o si ma fi ọ̀na ti nwọn o ma rìn hàn fun wọn ati iṣẹ ti nwọn o ma ṣe. Pẹlupẹlu iwọ o si ṣà ninu gbogbo awọn enia yi awọn ọkunrin ti o to, ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awọn ọkunrin olõtọ, ti o korira ojukokoro; irú awọn wọnni ni ki o fi jẹ́ olori wọn, lati ṣe olori ẹgbẹgbẹrun, ati olori ọrọrún, ati olori arãdọta, ati olori mẹwamẹwa. Ki nwọn ki o si ma ṣe idajọ awọn enia nigbakugba: yio si ṣe, gbogbo ẹjọ́ nla ni ki nwọn ki o ma mú tọ̀ ọ wá, ṣugbọn gbogbo ẹjọ́ kekeké ni ki nwọn ki o ma dá: yio si rọrùn fun iwọ tikalarẹ, nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù na. Bi iwọ ba jẹ ṣe nkan yi, bi Ọlọrun ba si fi aṣẹ fun ọ bẹ̃, njẹ iwọ o le duro pẹ, ati gbogbo awọn enia yi pẹlu ni yio si dé ipò wọn li alafia. Mose si gbà ohùn ana rẹ̀ gbọ́, o si ṣe ohun gbogbo ti o wi. Mose si yàn awọn enia ti o to ninu gbogbo Israeli, o si fi wọn ṣe olori awọn enia, olori ẹgbẹgbẹrun, olori ọrọrún, olori arãdọta, olori mẹwamẹwa. Nwọn si nṣe idajọ awọn enia nigbakugba: ọ̀ran ti o ṣoro, nwọn a mútọ̀ Mose wá, ṣugbọn awọn tikalawọn ṣe idajọ gbogbo ọ̀ran kekeké.

Eks 18:13-26 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ keji, Mose jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan wà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti òwúrọ̀ títí di àṣáálẹ́. Nígbà tí baba iyawo Mose rí gbogbo ohun tí Mose ń ṣe fún àwọn eniyan, ó pè é, ó ní, “Kí ni gbogbo ohun tí ò ń ṣe fún àwọn eniyan wọnyi? Kí ló dé tí o fi wà lórí àga ìdájọ́ láti òwúrọ̀ títí di àṣáálẹ́, tí àwọn eniyan ń kó ẹjọ́ wá bá ìwọ nìkan?” Mose dáhùn pé, “Ọ̀dọ̀ mi ni àwọn eniyan náà ti máa ń bèèrè ohun tí Ọlọrun fẹ́ kí wọ́n ṣe. Nígbà tí èdè-àìyedè bá wà láàrin àwọn aládùúgbò meji, èmi ni mo máa ń parí rẹ̀ fún wọn. Èmi náà ni mo sì máa ń sọ òfin Ọlọrun, ati àwọn ìpinnu rẹ̀ fún wọn.” Baba iyawo rẹ̀ bá bá a wí pé, “Ohun tí ò ń ṣe yìí kò dára. Àtìwọ àtàwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ, ẹ óo pa ara yín; ohun tí ò ń ṣe yìí ti pọ̀ jù fún ọ, o kò lè dá a ṣe. Gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí, ìmọ̀ràn ni mo fẹ́ gbà ọ́, Ọlọrun yóo sì wà pẹlu rẹ. Ó dára kí o máa ṣe aṣojú àwọn eniyan náà níwájú Ọlọrun, kí o sì máa bá wọn kó ẹ̀dùn ọkàn wọn tọ Ọlọrun lọ; ó sì dára bákan náà pẹlu kí o máa kọ́ wọn ní òfin ati ìlànà, kí o sì máa fi ọ̀nà tí wọn yóo tọ̀ hàn wọ́n, ati ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe. Ohun tí ó yẹ kí o ṣe nìyí, yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jẹ́ alákòóso, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun, tí wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, tí wọ́n sì kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀; fi wọ́n ṣe alákòóso àwọn eniyan wọnyi, fi àwọn kan ṣe alákòóso lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn kan lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn kan lórí araadọta, ati àwọn mìíràn lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá. Jẹ́ kí wọn máa ṣe onídàájọ́ fún àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá jẹ́ pataki pataki nìkan ni wọn yóo máa kó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, kí wọ́n máa parí àwọn ẹjọ́ kéékèèké láàrin ara wọn. Èyí yóo mú kí ó rọ̀ ọ́ lọ́rùn, wọn yóo sì máa bá ọ gbé ninu ẹrù náà. Bí Ọlọrun bá gbà fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí o sì ṣe é, ẹ̀mí rẹ yóo gùn, gbogbo àwọn eniyan wọnyi náà yóo sì pada sí ilé wọn ní alaafia.” Mose gba ọ̀rọ̀ tí baba iyawo rẹ̀ sọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí ó fún un. Mose yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè ṣe alákòóso ninu àwọn eniyan Israẹli, ó fi wọ́n ṣe olórí àwọn eniyan náà, àwọn kan jẹ́ alákòóso fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn, fún ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn, fún araadọta, àwọn mìíràn fún eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá. Wọ́n ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá fẹ́ díjú nìkan ni wọ́n ń kó tọ Mose lọ, wọ́n ń yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké láàrin ara wọn.

Eks 18:13-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kejì, Mose jókòó láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀; àwọn ènìyàn sì dúró ti Mose fún ìdájọ́ wọn láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí àna Mose rí bí àkókò ti èyí ń gba ti pọ̀ tó àti ti àwọn ènìyàn ti ń dúró pẹ́ tó, ó wí pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ń ṣe sí àwọn ènìyàn? Èéṣe ti ìwọ nìkan jókòó gẹ́gẹ́ bí adájọ́, nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró yí ọ ká láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́?” Mose dá a lóhùn pé, “Nítorí àwọn ènìyàn ń tọ̀ mí wá láti mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tí wọ́n bá ní ẹjọ́, wọn a mú un tọ̀ mí wá, èmi a sì ṣe ìdájọ́ láàrín ẹnìkínní àti ẹnìkejì, èmi a sì máa mú wọn mọ òfin àti ìlànà Ọlọ́run.” Àna Mose dá a lóhùn pé, “Ohun tí o ń ṣe yìí kò dára. Ìwọ àti àwọn ènìyàn ti ń tọ̀ ọ́ wá yìí yóò dá ara yín ní agara; iṣẹ́ yìí pọ̀jù fún ọ, ìwọ nìkan kò lè dá a ṣe Nísinsin yìí, fetísílẹ̀ sí mi, èmi yóò sì gbà ọ́ ni ìmọ̀ràn, Ọlọ́run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ. Ìwọ gbọdọ̀ jẹ́ aṣojú àwọn ènìyàn wọ̀nyí níwájú Ọlọ́run, ìwọ yóò sì mú èdè-àìyedè wá sí iwájú rẹ̀. Kọ́ wọn ní òfin àti ìlànà Ọlọ́run, fi ọ̀nà igbe ayé ìwà-bí-Ọlọ́run hàn wọ́n àti iṣẹ́ tí wọn yóò máa ṣe. Ṣa àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn: àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòtítọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ: yàn wọ́n ṣe olórí: lórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún-ọgọ́rùn-ún, àádọ́ta-dọ́ta àti mẹ́wàá mẹ́wàá. Jẹ́ kí wọn ó máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ni gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn mú ẹjọ́ tí ó bá nira fún wọn láti dá tọ̀ ọ́ wá; kí wọn kí ó máa dá ẹjọ́ kéékèèkéé. Èyí ni yóò mú iṣẹ́ rẹ rọrùn, wọn yóò sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí ìdájọ́ ṣíṣe. Bí ìwọ bá ṣe èyí, bí Ọlọ́run bá sì fi àṣẹ sí i fún ọ bẹ́ẹ̀, àárẹ̀ kò sì ní tètè mu ọ, àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò sì padà lọ ilé wọn ni àlàáfíà.” Mose fetísílẹ̀ sí àna rẹ̀, ó sì ṣe ohun gbogbo tí ó wí fún un. Mose sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo Israẹli; ó sì fi wọ́n jẹ olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá. Wọ́n sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ní ìgbà gbogbo. Wọ́n sì ń mú ẹjọ́ tó le tọ Mose wá; ṣùgbọ́n wọ́n ń dá ẹjọ́ tí kò le fúnrawọn.