Eks 17:8-16
Eks 17:8-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana li Amaleki wá, o si bá Israeli jà ni Refidimu. Mose si wi fun Joṣua pe, Yàn enia fun wa, ki o si jade lọ ibá Amaleki jà: li ọla li emi o duro lori oke ti emi ti ọpá Ọlọrun li ọwọ́ mi. Joṣua si ṣe bi Mose ti wi fun u, o si bá Amaleki jà: ati Mose, Aaroni, on Huri lọ sori oke na. O si ṣe, nigbati Mose ba gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, Israeli a bori: nigbati o ba si rẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ silẹ, Amaleki a bori. Ṣugbọn ọwọ́ kún Mose; nwọn si mú okuta kan, nwọn si fi si abẹ rẹ̀, o si joko lé e; Aaroni ati Huri si mu u li ọwọ́ ró, ọkan li apa kini, ekeji li apa keji; ọwọ́ rẹ̀ si duro gan titi o fi di ìwọ-õrùn. Joṣua si fi oju idà ṣẹgun Amaleki ati awọn enia rẹ̀ tútu. OLUWA si wi fun Mose pe, Kọ eyi sinu iwe fun iranti, ki o si kà a li eti Joṣua; nitoriti emi o pa iranti Amaleki run patapata kuro labẹ ọrun. Mose si tẹ́ pẹpẹ kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni JEHOFA-nissi: O si wipe, OLUWA ti bura: OLUWA yio bá Amaleki jà lati irandiran.
Eks 17:8-16 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn èyí ni àwọn ará Amaleki wá, wọ́n sì bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní Refidimu. Mose bá wí fún Joṣua pé, “Yan àwọn akọni ọkunrin láàrin yín kí o sì jáde lọ láti bá àwọn ará Amaleki jagun lọ́la, n óo dúró ní orí òkè pẹlu ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ mi.” Joṣua ṣe bí Mose ti pàṣẹ fún un, ó bá àwọn ará Amaleki jagun. Mose ati Aaroni ati Huri bá gun orí òkè lọ. Nígbà tí Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, àwọn ọmọ Israẹli a máa borí àwọn ará Amaleki, nígbà tí ó bá sì rẹ ọwọ́ sílẹ̀, àwọn ará Amaleki a máa borí àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí ó yá, apá bẹ̀rẹ̀ sí ro Mose, wọ́n gbé òkúta kan fún un láti fi jókòó, ó sì jókòó lórí rẹ̀. Aaroni ati Huri bá a gbé apá rẹ̀ sókè, ẹnìkan gbé apá ọ̀tún, ẹnìkejì sì gbé apá òsì. Apá rẹ̀ wà lókè títí tí oòrùn fi ń lọ wọ̀. Joṣua bá fi idà pa Amaleki ati àwọn eniyan rẹ̀ ní ìpakúpa. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Kọ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sinu ìwé kan fún ìrántí, sì kà á sí etígbọ̀ọ́ Joṣua, pé n óo pa Amaleki rẹ́ patapata, a kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́ láyé.” Mose bá tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni àsíá mi.” Ó ní, “Gbé àsíá OLUWA sókè! OLUWA yóo máa bá ìrandíran àwọn ará Amaleki jà títí lae.”
Eks 17:8-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ara Amaleki jáde, wọ́n sì dìde ogun sí àwọn ọmọ Israẹli ni Refidimu. Mose sì sọ fún Joṣua pé, “Yàn lára àwọn ọkùnrin fún wa, kí wọn ó sì jáde lọ bá àwọn ará Amaleki jà. Ní ọ̀la, èmi yóò dúró ni orí òkè pẹ̀lú ọ̀pá Ọlọ́run ní ọwọ́ mi.” Joṣua ṣe bí Mose ti wí fún un, ó sì bá àwọn ará Amaleki jagun; nígbà tí Mose, Aaroni àti Huri lọ sí orí òkè náà. Níwọ́n ìgbà tí Mose bá gbé apá rẹ̀ sókè, Israẹli n borí ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá sì rẹ apá rẹ̀ sílẹ̀, Amaleki a sì borí. Ṣùgbọ́n apá ń ro Mose; Wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà: Aaroni àti Huri sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti oòrùn wọ. Joṣua sì fi ojú idà ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki. OLúWA sì sọ fun Mose pé. “Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Joṣua pẹ̀lú; nítorí èmi yóò pa ìrántí Amaleki run pátápátá kúrò lábẹ́ ọ̀run.” Mose sì tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì sọ orúkọ pẹpẹ náà ní OLúWA ni àsíá mi (Jehofa-Nisi). Ó wí pé, “A gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ OLúWA. OLúWA yóò bá Amaleki jagun láti ìran dé ìran.”