Eks 17:6-7
Eks 17:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kiyesi i, emi o duro niwaju rẹ nibẹ̀ lori okuta ni Horebu; iwọ o si lù okuta na, omi yio si jade ninu rẹ̀, ki awọn enia ki o le mu. Mose si ṣe bẹ̃ li oju awọn àgbagba Israeli. O si sọ orukọ ibẹ̀ ni Massa, ati Meriba, nitori asọ̀ awọn ọmọ Israeli, ati nitoriti nwọn dan OLUWA wò pe, OLUWA ha mbẹ lãrin wa, tabi kò si?
Eks 17:6-7 Yoruba Bible (YCE)
N óo dúró níwájú rẹ lórí àpáta ní òkè Horebu. Nígbà tí o bá fi ọ̀pá lu àpáta náà, omi yóo ti inú rẹ̀ jáde, àwọn eniyan náà yóo sì mu ún.” Mose bá ṣe bẹ́ẹ̀ níwájú gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli. Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Masa ati Meriba, nítorí ìwà ìka-ẹ̀sùn-síni-lẹ́sẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli hù, ati nítorí dídán tí wọn dán OLUWA wò, wọ́n ní, “Ṣé OLUWA tún wà láàrin wa ni tabi kò sí mọ́?”
Eks 17:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò dúró ni ibẹ̀ dè ọ ni orí àpáta ni Horebu. Ìwọ ó sì lu àpáta, omi yóò sì jáde nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti mu.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀ ni iwájú àwọn àgbàgbà Israẹli. Ó sì sọ orúkọ ibẹ̀ ni Massa (ìdánwò) àti Meriba (kíkùn) nítorí àwọn ọmọ Israẹli sọ̀, wọ́n sì dán OLúWA wò, wọ́n wí pé, “Ǹjẹ́ OLúWA ń bẹ láàrín wa tàbí kò sí?”