Eks 17:12-14
Eks 17:12-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ọwọ́ kún Mose; nwọn si mú okuta kan, nwọn si fi si abẹ rẹ̀, o si joko lé e; Aaroni ati Huri si mu u li ọwọ́ ró, ọkan li apa kini, ekeji li apa keji; ọwọ́ rẹ̀ si duro gan titi o fi di ìwọ-õrùn. Joṣua si fi oju idà ṣẹgun Amaleki ati awọn enia rẹ̀ tútu. OLUWA si wi fun Mose pe, Kọ eyi sinu iwe fun iranti, ki o si kà a li eti Joṣua; nitoriti emi o pa iranti Amaleki run patapata kuro labẹ ọrun.
Eks 17:12-14 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, apá bẹ̀rẹ̀ sí ro Mose, wọ́n gbé òkúta kan fún un láti fi jókòó, ó sì jókòó lórí rẹ̀. Aaroni ati Huri bá a gbé apá rẹ̀ sókè, ẹnìkan gbé apá ọ̀tún, ẹnìkejì sì gbé apá òsì. Apá rẹ̀ wà lókè títí tí oòrùn fi ń lọ wọ̀. Joṣua bá fi idà pa Amaleki ati àwọn eniyan rẹ̀ ní ìpakúpa. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Kọ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sinu ìwé kan fún ìrántí, sì kà á sí etígbọ̀ọ́ Joṣua, pé n óo pa Amaleki rẹ́ patapata, a kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́ láyé.”
Eks 17:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n apá ń ro Mose; Wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà: Aaroni àti Huri sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti oòrùn wọ. Joṣua sì fi ojú idà ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki. OLúWA sì sọ fun Mose pé. “Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Joṣua pẹ̀lú; nítorí èmi yóò pa ìrántí Amaleki run pátápátá kúrò lábẹ́ ọ̀run.”