Eks 16:23-30
Eks 16:23-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun wọn pe, Eyi na li OLUWA ti wi pe, Ọla li ọjọ́ isimi, isimi mimọ́ fun OLUWA; ẹ yan eyiti ẹnyin ni iyan, ki ẹ si bọ̀ eyiti ẹnyin ni ibọ̀; eyiti o si kù, ẹ fi i silẹ lati pa a mọ́ dé owurọ̀. Nwọn si fi i silẹ titi di owurọ̀, bi Mose ti paṣẹ fun wọn; kò si rùn, bẹ̃ni kò sí idin ninu rẹ̀. Mose si wi pe, Ẹ jẹ eyinì li oni; nitori oni li ọjọ́ isimi fun OLUWA: li oni ẹnyin ki yio ri i ninu igbẹ́. Li ọjọ́ mẹfa li ẹ o ma kó o; ṣugbọn li ọjọ́ keje li ọjọ́ isimi, ninu rẹ̀ ni ki yio si nkan. O si ṣe li ọjọ́ keje awọn kan ninu awọn enia jade lọ ikó, nwọn kò si ri nkan. OLUWA si wi fun Mose pe, Ẹ o ti kọ̀ lati pa aṣẹ mi ati ofin mi mọ́ pẹ to? Wò o, OLUWA sa ti fi ọjọ́ isimi fun nyin, nitorina li o ṣe fi onjẹ ijọ́ meji fun nyin li ọjọ́ kẹfa; ki olukuluku ki o joko ni ipò rẹ̀, ki ẹnikẹni ki o máṣe jade kuro ni ipò rẹ̀ li ọjọ́ keje. Bẹ̃li awọn enia na simi li ọjọ́ keje.
Eks 16:23-30 Yoruba Bible (YCE)
ó wí fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘Ọ̀la ni ọjọ́ ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀, ọjọ́ ìsinmi mímọ́ fún OLUWA. Ẹ dín ohun tí ẹ bá fẹ́ dín, kí ẹ sì se ohun tí ẹ bá fẹ́ sè, ohun tí ó bá ṣẹ́kù, ẹ fi pamọ́ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.’ ” Wọ́n bá fi ìyókù pamọ́ títí di òwúrọ̀ gẹ́gẹ́ bí Mose ti sọ fún wọn; kò sì rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò yọ ìdin. Mose wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ èyí lónìí, nítorí pé òní ni ọjọ́ ìsinmi OLUWA, ẹ kò ní rí kó rárá ní òní. Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi máa rí oúnjẹ kó, ṣugbọn ní ọjọ́ keje tíí ṣe ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí níbẹ̀ rárá.” Ní ọjọ́ keje, àwọn mìíràn ninu àwọn eniyan náà jáde láti lọ kó oúnjẹ, ṣugbọn wọn kò rí ohunkohun. OLUWA bá wí fún Mose pé, “Yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo fi kọ̀ láti pa àṣẹ ati òfin mi mọ́. Ẹ wò ó! OLUWA ti fún yín ní ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà ni ó fi jẹ́ pé, ní ọjọ́ kẹfa ó fún yín ní oúnjẹ fún ọjọ́ meji, kí olukuluku lè dúró sí ààyè rẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe jáde ní ilé rẹ̀ ní ọjọ́ keje.” Àwọn eniyan náà bá sinmi ní ọjọ́ keje.
Eks 16:23-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA pàṣẹ: ‘Ọ̀la jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ìsinmi mímọ́ fún OLúWA. Ẹ yan èyí ti ẹ̀yin ní yan, kí ẹ sì bọ èyí ti ẹ̀yin ní bọ̀. Ẹ tọ́jú èyí ti ó kù sílẹ̀, kí ẹ pa á mọ́ di òwúrọ̀.’ ” Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mose ti pàṣẹ; kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin. Mose sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ ẹ́ ní òní nítorí òní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi OLúWA. Ẹ̀yin kò ni rí i ni orí ilẹ̀ ní ọjọ́ òní. Ní ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi kó o, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ keje ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí i fún un yín ni ọjọ́ náà.” Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó. OLúWA sì sọ fún Mose pé, “Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́? Wò ó? OLúWA ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni oúnjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọ̀ọ̀kan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.” Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje.