Eks 16:2-3
Eks 16:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni ni ijù na: Awọn ọmọ Israeli si wi fun wọn pe, Awa iba ti ti ọwọ́ OLUWA kú ni Egipti, nigbati awa joko tì ìkoko ẹran, ti awa njẹ ajẹyo; ẹnyin sá mú wa jade wá si ijù yi, lati fi ebi pa gbogbo ijọ yi.
Eks 16:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni ninu aṣálẹ̀, wọ́n ń wí pé, “Ìbá sàn kí OLUWA pa wá sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí olukuluku wa ti jókòó ti ìsaasùn ọbẹ̀ ẹran, tí a sì ń jẹ oúnjẹ àjẹyó, ju bí ẹ ti kó wa wá sí ààrin aṣálẹ̀ yìí lọ, láti fi ebi pa gbogbo wa kú.”
Eks 16:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì ń kùn sí Mose àti Aaroni ní ijù náà. Àwọn ọmọ Israẹli wí fún wọn pé, “Àwa ìbá ti ọwọ́ OLúWA kú ni Ejibiti! Níbi tí àwa ti jókòó ti ìkòkò ẹran ti a sì ń jẹ ohun gbogbo tí a fẹ́ ni àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin mú wa wá sí inú ijù yìí láti fi ebi pa wá tí a ó fi kú.”