Eks 15:1-27

Eks 15:1-27 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni Mose ati awọn ọmọ Israeli kọ orin yi si OLUWA nwọn si wipe, Emi o kọrin si OLUWA, nitoriti o pọ̀ li ogo: ati ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun. OLUWA li agbara ati orin mi, on li o si di ìgbala mi: eyi li Ọlọrun mi, emi o si fi ìyin fun u; Ọlọrun baba mi, emi o gbé e leke. Ologun li OLUWA; OLUWA li orukọ rẹ̀. Kẹkẹ́ Farao ati ogun rẹ̀ li o mu wọ̀ inu okun: awọn ãyo olori ogun rẹ̀ li o si rì ninu Okun Pupa. Ibú bò wọn mọlẹ: nwọn rì si isalẹ bi okuta. OLUWA, ọwọ́ ọtún rẹ li ogo ninu agbara: OLUWA, ọwọ́ ọtún rẹ fọ́ ọtá tútu. Ati ni ọ̀pọlọpọ ọlá rẹ ni iwọ bì awọn ti o dide si ọ ṣubu; iwọ rán ibinu rẹ, ti o run wọn bi akemọlẹ idi koriko. Ati nipa ẽmi imu rẹ, li omi si fi wọjọ pọ̀, ìṣan omi dide duro gangan bi ogiri; ibú si dìlu lãrin okun. Ọtá wipe, Emi o lepa, emi o bá wọn, emi o pín ikogun: a o tẹ́ ifẹkufẹ mi lọrùn lara wọn; emi o fà dà mi yọ, ọwọ́ mi ni yio pa wọn run. Iwọ si mu afẹfẹ rẹ fẹ́, okun bò wọn mọlẹ: nwọn rì bi ojé ninu omi nla. Tali o dabi iwọ, OLUWA, ninu awọn alagbara? tali o dabi iwọ, ologo ni mimọ́, ẹlẹru ni iyìn, ti nṣe ohun iyanu? Iwọ nà ọwọ́ ọtún rẹ, ilẹ gbe wọn mì. Ninu ãnu rẹ ni iwọ fi ṣe amọ̀na awọn enia na ti iwọ ti rapada: iwọ si nfi agbara rẹ tọ́ wọn lọ si ibujoko mimọ́ rẹ. Awọn enia gbọ́, nwọn warìri; ikãnu si mú awọn olugbe Palestina. Nigbana li ẹnu yà awọn balẹ Edomu; iwarìri si mú awọn alagbara Moabu: gbogbo awọn olugbe Kenaani yọ́ dànu. Ibẹru-bojo mú wọn; nipa titobi apa rẹ nwọn duro jẹ bi okuta; titi awọn enia rẹ fi rekọja, OLUWA, titi awọn enia rẹ ti iwọ ti rà fi rekọja. Iwọ o mú wọn wọle, iwọ o si gbìn wọn sinu oke ilẹ-iní rẹ, OLUWA, ni ibi ti iwọ ti ṣe fun ara rẹ, lati mã gbé, OLUWA; ni ibi mimọ́ na, ti ọwọ́ rẹ ti gbekalẹ. OLUWA yio jọba lai ati lailai. Nitori ẹṣin Farao wọ̀ inu okun lọ, pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀ ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀, OLUWA si tun mú omi okun pada si wọn lori; ṣugbọn awọn ọmọ Israeli rìn ni ilẹ gbigbẹ lãrin okun. Ati Miriamu wolĩ obinrin, arabinrin Aaroni, o mú ìlu li ọwọ́ rẹ̀: gbogbo awọn obinrin si jade tẹle e ti awọn ti ìlu ati ijó. Miriamu si da wọn li ohùn pe, Ẹ kọrin si OLUWA nitoriti o pọ̀ li ogo; ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun. Bẹ̃ni Mose mú Israeli jade lati Okun Pupa wá, nwọn si jade lọ si ijù Ṣuri; nwọn si lọ ni ìrin ijọ́ mẹta ni ijù na, nwọn kò si ri omi. Nigbati nwọn dé Mara, nwọn ko le mu ninu omi Mara, nitoriti o korò; nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Mara. Awọn enia na si nkùn si Mose wipe, Kili awa o mu? O si kepè OLUWA; OLUWA si fi igi kan hàn a, nigbati o si sọ ọ sinu omi na, omi si di didùn. Nibẹ̀ li o si gbé ṣe ofin ati ìlana fun wọn, nibẹ̀ li o si gbé dán wọn wò; O si wipe, Bi iwọ o ba tẹtisilẹ gidigidi si ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o ba si ṣe eyiti o tọ́ li oju rẹ̀, ti iwọ o ba si fetisi ofin rẹ̀, ti iwọ o ba si pa gbogbo aṣẹ rẹ̀ mọ́, emi ki yio si fi ọkan ninu àrun wọnni ti mo múwa sara awọn ara Egipti si ọ lara: nitori emi li OLUWA ti o mu ọ lara dá. Nwọn si dé Elimu, nibiti kanga omi mejila gbé wà, ati ãdọrin ọpẹ: nwọn si dó si ìha omi wọnni nibẹ̀.

Eks 15:1-27 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, Mose ati àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLUWA, wọ́n ní: “N óo kọrin sí OLUWA, nítorí pé, ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo. Àtẹṣin, àtẹni tí ń gùn ún ni ó dà sinu Òkun Pupa. OLUWA ni agbára ati orin mi, ó ti gbà mí là, òun ni Ọlọrun mi, n óo máa yìn ín. Òun ni Ọlọrun àwọn baba ńlá mi; n óo máa gbé e ga. Jagunjagun ni OLUWA, OLUWA sì ni orúkọ rẹ̀. Ó da kẹ̀kẹ́ ogun Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sinu òkun, ó sì ri àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀ sinu Òkun Pupa. Ìkún omi bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n rilẹ̀ sinu ibú omi bí òkúta. Agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ pọ̀ jọjọ, OLUWA; OLUWA, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú. Ninu títóbi ọláńlá rẹ, o dojú àwọn ọ̀tá rẹ bolẹ̀, o fa ibinu yọ, ó sì jó wọn bí àgékù koríko. Èémí ihò imú rẹ mú kí omi gbájọ, ìkún omi dúró lóòró bí òkítì, ibú omi sì dì ní ìsàlẹ̀ òkun. Ọ̀tá wí pé, ‘N óo lé wọn, ọwọ́ mi yóo sì tẹ̀ wọ́n; n óo pín ìkógun, n óo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi lọ́rùn lára wọn. N óo fa idà mi yọ, ọwọ́ mi ni n óo sì fi pa wọ́n run.’ Ṣugbọn o fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n, òkun sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n rì bí òjé ninu ibú ńlá. “Ta ló dàbí rẹ OLUWA ninu àwọn oriṣa? Ta ló dàbí rẹ, ológo mímọ̀ jùlọ? Ẹlẹ́rù níyìn tíí ṣe ohun ìyanu. O na ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ilẹ̀ sì yanu, ó gbé wọn mì. O ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ṣe amọ̀nà àwọn eniyan rẹ tí o rà pada, o ti fi agbára rẹ tọ́ wọn lọ sí ibùgbé mímọ́ rẹ. Àwọn eniyan ti gbọ́, wọ́n wárìrì, jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ Filistini. Ẹnu ya àwọn ìjòyè Edomu, ojora sì mú gbogbo àwọn olórí ní ilẹ̀ Moabu, gbogbo àwọn tí ń gbé Kenaani sì ti kú sára. Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati jìnnìjìnnì ti dà bò wọ́n, nítorí títóbi agbára rẹ, OLUWA, wọ́n dúró bí òkúta, títí tí àwọn eniyan rẹ fi kọjá lọ, àní àwọn tí o ti rà pada. O óo kó àwọn eniyan rẹ wọlé, o óo sì fi ìdí wọn múlẹ̀ lórí òkè mímọ́ rẹ, níbi tí ìwọ OLUWA ti pèsè fún ibùgbé rẹ, ibi mímọ́ rẹ tí ìwọ OLUWA ti fi ọwọ́ ara rẹ pèsè sílẹ̀. OLUWA yóo jọba títí lae ati laelae.” Nígbà tí àwọn ẹṣin Farao, ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọ inú òkun, OLUWA mú kí omi òkun pada bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣugbọn àwọn eniyan Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ láàrin òkun. Nígbà náà ni Miriamu, wolii obinrin, tíí ṣe arabinrin Aaroni, gbé ìlù timbireli lọ́wọ́, gbogbo àwọn obinrin sì tẹ̀lé e, wọ́n ń lu timbireli, wọ́n sì ń jó. Miriamu bá dá orin fún wọn pé, “Ẹ kọrin sí OLUWA, nítorí tí ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo, ó ti da ati ẹṣin ati àwọn ẹlẹ́ṣin sinu Òkun Pupa.” Mose bá bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú láti ibi Òkun Pupa, wọ́n ń lọ sí aṣálẹ̀ Ṣuri, ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi rìn ninu aṣálẹ̀ láìrí omi. Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi tí wọ́n rí níbẹ̀, nítorí pé ó korò. Nítorí náà, wọ́n sọ orúkọ ibẹ̀ ní Mara, ìtumọ̀ èyí tíí ṣe ìkorò. Ni àwọn eniyan náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose, wọ́n ní, “Kí ni a óo mu?” Mose bá kígbe sí OLUWA, OLUWA fi igi kan hàn án. Mose ju igi náà sinu omi, omi náà sì di dídùn. Ibẹ̀ ni OLUWA ti fún wọn ní ìlànà ati òfin, ó sì dán wọn wò, ó ní, “Bí ẹ bá farabalẹ̀ gbọ́ ohùn èmi OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, tí ẹ pa gbogbo òfin mi mọ́, tí ẹ sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà mi, èmi OLUWA kò ní fi èyíkéyìí ninu àwọn àrùn tí mo fi ṣe àwọn ará Ijipti ṣe yín, nítorí pé, èmi ni OLUWA, olùwòsàn yín.” Lẹ́yìn náà ni wọ́n dé Elimu, níbi tí orísun omi mejila ati aadọrin igi ọ̀pẹ wà, wọ́n sì pàgọ́ sẹ́bàá àwọn orísun omi náà.

Eks 15:1-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLúWA: Èmi yóò kọrin sí OLúWA, nítorí òun pọ̀ ní ògo. Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún ni ó ti sọ sínú Òkun. OLúWA ni agbára àti orin mi; òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga. Ológun ni OLúWA, OLúWA ni orúkọ rẹ, Kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀ ni ó mú wọ inú Òkun. Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ ni ó rì sínú Òkun pupa. Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀; wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi Òkun bí òkúta. “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, OLúWA, pọ̀ ní agbára. Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, OLúWA, fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú. “Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú. Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ; Tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ń wọ́jọ pọ̀. Ìṣàn omi dìde dúró bí odi; ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun. Ọ̀tá ń gbéraga, ó ń wí pé: ‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn. Èmi ó pín ìkógun; Èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn. Èmi yóò fa idà mi yọ, ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’ Ìwọ fẹ́ èémí rẹ, òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n rì bí òjé ni àárín omi ńlá. Ta ni nínú àwọn òrìṣà tó dàbí rẹ, OLúWA? Ta ló dàbí rẹ: ní títóbi, ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn, tí ń ṣe ohun ìyanu? “Ìwọ na apá ọ̀tún rẹ, Ilẹ̀ si gbé wọn mì. Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í sákí Ìwọ ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn náà tí Ìwọ ti rà padà. Nínú agbára rẹ Ìwọ yóò tọ́ wọn, lọ sí ibi ìjókòó rẹ mímọ́. Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrì Ìkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn Filistia. Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Edomu, Àwọn olórí Moabu yóò wárìrì Àwọn ènìyàn Kenaani yóò sì yọ́ dànù; Ìbẹ̀rù bojo yóò ṣubú lù wọ́n nítorí nína títóbi apá rẹ̀ wọn yóò dúró jẹ́ẹ́ láì mira bí i òkúta Títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi rékọjá, OLúWA, Títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi rékọjá. Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́n ni orí òkè ti ìwọ jogún; Ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, OLúWA. Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbé kalẹ̀, OLúWA. “OLúWA yóò jẹ ọba láé àti láéláé.” Nígbà ti ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ inú Òkun, OLúWA mú kí omi Òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la Òkun kọjá. Miriamu wòlíì obìnrin, arábìnrin Aaroni, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin sì jáde tẹ̀lé e pẹ̀lú ìlù òun ijó. Miriamu kọrin sí wọn báyìí pé: “Ẹ kọrin sí OLúWA Nítorí òun ni ológo jùlọ Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún Ni òun bi ṣubú sínú Òkun.” Nígbà náà ni Mose ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn Israẹli jáde láti Òkun pupa lọ sínú ijù Ṣuri. Wọ́n lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù náà, wọn kò sì rí omi. Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi Mara nítorí omi náà korò (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Mara: ibi ìkorò). Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mose wí pé, “Kí ni àwa yóò mu?” Mose sì ké pe OLúWA, OLúWA sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn. Níbẹ̀ ni OLúWA ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí òfin OLúWA Ọlọ́run, ti ìwọ sì ṣe ohun tí ó tọ́ ni ojú rẹ̀, ti ìwọ sì tẹ̀lé ohun tí ó pàṣẹ, ti ìwọ si pa ìlànà rẹ̀ mọ́. Èmi kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn ààrùn wọ̀n-ọn-nì ti mo mú wá sórí àwọn ará Ejibiti wá sí ara rẹ, nítorí èmi ni OLúWA ti ó mú ọ láradá.” Nígbà ti wọ́n dé Elimu, níbi ti kànga omi méjìlá (12) àti àádọ́rin (70) ọ̀pẹ gbé wà, wọ́n pàgọ́ síbẹ̀ ni etí omi.