Eks 14:26-28
Eks 14:26-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si wi fun Mose pe; Nà ọwọ́ rẹ si oju okun, ki omi ki o tun pada wá sori awọn ara Egipti, sori kẹkẹ́ wọn, ati sori ẹlẹṣin wọn. Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si oju okun, okun si pada bọ̀ si ipò rẹ̀ nigbati ilẹ mọ́; awọn ara Egipti si sá lù u. OLUWA si bì awọn ara Egipti ṣubu lãrin okun. Omi si pada, o si bò kẹkẹ́, ati awọn ẹlẹṣin, ati gbogbo ogun Farao ti o wọ̀ inu okun tọ̀ wọn lẹhin lọ; ọkanṣoṣo kò kù ninu wọn.
Eks 14:26-28 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun bá sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun pupa kí omi lè bo àwọn ará Ijipti ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn, ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn mọ́lẹ̀.” Mose bá na ọwọ́ sórí òkun, òkun bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣàn tẹ́lẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji yóo fi mọ́; àwọn ará Ijipti gbìyànjú láti jáde, ṣugbọn OLUWA pa wọ́n run sinu òkun náà. Omi òkun pada sí ipò rẹ̀, ó sì bo gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin, ati àwọn ọmọ ogun Farao tí wọ́n lépa àwọn ọmọ Israẹli wọ inú Òkun Pupa, ẹyọ kan kò sì yè ninu wọn.
Eks 14:26-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì wí fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sí orí Òkun kí omi Òkun lè ya padà sórí àwọn ará Ejibiti, kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti sórí ẹlẹ́ṣin wọn.” Mose sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, Òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ilẹ̀ mọ́. Àwọn ará Ejibiti ń sá fún omi Òkun, OLúWA sì gbá wọn sínú Òkun. Omi Òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin: àní, gbogbo ọmọ-ogun Farao tiwọn wọ inú Òkun tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yè.