Eks 14:21-27
Eks 14:21-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si oju okun; OLUWA si fi afẹfẹ lile ìla-õrùn mu okun bì sẹhin ni gbogbo oru na, o si mu okun gbẹ: omi na si pinya. Awọn ọmọ Israeli si lọ sinu ãrin okun ni ilẹ gbigbẹ: omi si ṣe odi si wọn li ọwọ ọtún, ati ọwọ́ òsi. Awọn ara Egipti si lepa wọn, nwọn si wọ̀ ọ tọ̀ wọn lọ lãrin okun, ati gbogbo ẹṣin Farao, ati kẹkẹ́ rẹ̀, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀. O si ṣe, nigba iṣọ owurọ̀, OLUWA bojuwò ogun ara Egipti lãrin ọwọ̀n iná, ati ti awọsanma, o si pá ogun awọn ara Egipti làiya. O si yẹ̀ kẹkẹ́ wọn, nwọn si nwọ́ turu, awọn ara Egipti si wipe, Ẹ jẹ ki a sá kuro niwaju Israeli; nitoriti OLUWA mbá awọn ara Egipti jà fun wọn. OLUWA si wi fun Mose pe; Nà ọwọ́ rẹ si oju okun, ki omi ki o tun pada wá sori awọn ara Egipti, sori kẹkẹ́ wọn, ati sori ẹlẹṣin wọn. Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si oju okun, okun si pada bọ̀ si ipò rẹ̀ nigbati ilẹ mọ́; awọn ara Egipti si sá lù u. OLUWA si bì awọn ara Egipti ṣubu lãrin okun.
Eks 14:21-27 Yoruba Bible (YCE)
Mose na ọwọ́ rẹ̀ sórí Òkun Pupa; OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ líle kan fẹ́ wá láti ìhà ìlà oòrùn ní gbogbo òru náà, afẹ́fẹ́ náà bi omi òkun sẹ́yìn, ó sì mú kí ààrin òkun náà di ìyàngbẹ ilẹ̀, omi rẹ̀ sì pín sí ọ̀nà meji. Àwọn ọmọ Israẹli bọ́ sí ààrin òkun náà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi òkun wá dàbí ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ní ẹ̀gbẹ́ òsì wọn. Àwọn ará Ijipti lé wọn wọ inú òkun, tàwọn ti gbogbo ẹṣin Farao ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati gbogbo ẹlẹ́ṣin rẹ̀. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ kutukutu, OLUWA bojú wo ogun Ijipti láti òkè wá, ninu ọ̀wọ̀n iná, ati ọ̀wọ̀n ìkùukùu, ó sì dẹ́rùbà wọ́n. Ó mú kí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọ́n há, tí ó fi jẹ́ pé àwọn kẹ̀kẹ́ náà wúwo rinrin. Àwọn ọmọ ogun Ijipti bá wí láàrin ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun ń bá wa jà nítorí wọn.” Ọlọrun bá sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun pupa kí omi lè bo àwọn ará Ijipti ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn, ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn mọ́lẹ̀.” Mose bá na ọwọ́ sórí òkun, òkun bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣàn tẹ́lẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji yóo fi mọ́; àwọn ará Ijipti gbìyànjú láti jáde, ṣugbọn OLUWA pa wọ́n run sinu òkun náà.
Eks 14:21-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Mose na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, ni gbogbo òru náà ni OLúWA fi lé Òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀. Omi Òkun sì pínyà, àwọn ọmọ Israẹli sì la ìyàngbẹ ilẹ̀ kọjá nínú Òkun pẹ̀lú ògiri omi ní ọ̀tún àti òsì. Àwọn ará Ejibiti sì ń lépa wọn, gbogbo ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ́ tọ̀ wọ́n lọ sínú Òkun. Ní ìṣọ́ òwúrọ̀ OLúWA bojú wo ogun àwọn ará Ejibiti láàrín ọ̀wọ̀n iná àti ìkùùkuu, ó sì kó ìpayà bá àwọn ọmọ-ogun Ejibiti. Ó sì yọ àgbá ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn kí ó bá à le ṣòro fún wọn láti fi kẹ̀kẹ́ ogun náà rìn. Àwọn ará Ejibiti wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá àsálà kúrò ní iwájú àwọn ará Israẹli nítorí OLúWA ń bá wa jà nítorí wọn.” OLúWA sì wí fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sí orí Òkun kí omi Òkun lè ya padà sórí àwọn ará Ejibiti, kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti sórí ẹlẹ́ṣin wọn.” Mose sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, Òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ilẹ̀ mọ́. Àwọn ará Ejibiti ń sá fún omi Òkun, OLúWA sì gbá wọn sínú Òkun.