Eks 14:13-14
Eks 14:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ má bẹ̀ru, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri ìgbala OLUWA, ti yio fihàn nyin li oni: nitori awọn ara Egipti ti ẹnyin ri li oni yi, ẹnyin ki yio si tun ri wọn mọ́ lailai. Nitoriti OLUWA yio jà fun nyin, ki ẹnyin ki o si pa ẹnu nyin mọ́.
Eks 14:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Mose bá dá àwọn eniyan náà lóhùn, ó ní, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró gbọningbọnin, kí ẹ wá máa wo ohun tí OLUWA yóo ṣe. Ẹ óo rí i bí yóo ṣe gbà yín là lónìí; nítorí pé àwọn ará Ijipti tí ẹ̀ ń wò yìí, ẹ kò tún ní rí wọn mọ́ laelae. OLUWA yóo jà fún yín, ẹ̀yin ẹ ṣá dúró jẹ́.”
Eks 14:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí OLúWA yóò fi fún un yín lónìí; Àwọn ará Ejibiti ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́. OLúWA yóò jà fún un yín; kí ẹ̀yin kí ó sá à mu sùúrù.”