Eks 14:10-11
Eks 14:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Farao si nsunmọtosi, awọn ọmọ Israeli gbé oju soke, si kiyesi i, awọn ara Egipti mbọ̀ lẹhin wọn; ẹ̀ru si bà wọn gidigidi: awọn ọmọ Israeli si kigbe pè OLUWA. Nwọn si wi fun Mose pe, Nitoriti isà kò sí ni Egipti, ki iwọ ṣe mú wa wá lati kú ni ijù? ẽṣe ti iwọ fi ṣe wa bẹ̃, lati mú wa jade ti Egipti wá?
Eks 14:10-11 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Farao súnmọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú sókè tí wọ́n rí àwọn ará Ijipti tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wọn; ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Wọ́n kígbe sí OLUWA; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Mose pé, “Ṣé kò sí ibojì ní Ijipti ni o fi kó wa kúrò láti wá kú sí ààrin aṣálẹ̀? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí, tí o kó wa kúrò ní Ijipti?
Eks 14:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí Farao ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Ejibiti tó súnmọ́ wọn. Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Israẹli, wọ́n kígbe sókè sí OLúWA. Wọ́n sọ fún Mose pé, “Ṣe nítorí pé kò sí ibojì ni Ejibiti ní ìwọ ṣe mú wa wá láti kú sínú aginjù? Kí ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa ti ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti wá?