Eks 12:21-28
Eks 12:21-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Mose pè gbogbo awọn àgba Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ imú ọdọ-agutan fun ara nyin, gẹgẹ bi idile nyin, ki ẹ si pa irekọja na. Ẹnyin o si mú ìdi ewe-hissopu, ẹ o si fi bọ̀ ẹ̀jẹ ti o wà ninu awokoto, ẹ o si fi ẹ̀jẹ na ti o wà ninu awokoto kùn ara atẹrigba, ati opó ìha mejeji; ẹnikẹni ninu nyin kò si gbọdọ jade lati ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀ titi yio fi di owurọ̀. Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin. Ẹ o si ma kiyesi nkan yi nipa ìlana fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lailai. O si ṣe, nigbati ẹ ba dé ilẹ na ti OLUWA yio fi fun nyin, gẹgẹ bi o ti wi, bẹ̃li ẹ o si ma kiyesi ìsin yi. Yio si ṣe nigbati awọn ọmọ nyin ba bi nyin pe, Eredi ìsin yi? Ki ẹ wipe, Ẹbọ irekọja OLUWA ni, ẹniti o rekọja ile awọn ọmọ Israeli ni Egipti, nigbati o kọlù awọn ara Egipti, ti o si dá ile wa si. Awọn enia si tẹriba nwọn si sìn. Awọn ọmọ Israeli si lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe.
Eks 12:21-28 Yoruba Bible (YCE)
Mose bá pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣa ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan ní ìdílé yín kọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì pa á fún ìrékọjá. Ẹ mú ìdì ewé hisopu, kí ẹ tì í bọ ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá gbè sinu àwo kòtò kan, kí ẹ fi ẹ̀jẹ̀ náà kun àtẹ́rígbà ati òpó ìlẹ̀kùn mejeeji. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò sì gbọdọ̀ jáde ninu ilé títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Nítorí pé, OLUWA yóo rékọjá, yóo sì pa àwọn ará Ijipti. Ṣugbọn nígbà tí ó bá rí ẹ̀jẹ̀ lára àtẹ́rígbà ati lára òpó ẹnu ọ̀nà mejeeji, OLUWA yóo ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kò sì ní jẹ́ kí apanirun wọ ilé yín láti pa yín. Ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín, ẹ gbọdọ̀ máa pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin títí lae. Nígbà tí ẹ bá sì dé ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ìsìn yìí. Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá sì bi yín léèrè pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ ìsìn yìí?’ ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹbọ ìrékọjá OLUWA ni, nítorí pé ó ré ilé àwọn eniyan Israẹli kọjá ní Ijipti, nígbà tí ó ń pa àwọn ará Ijipti, ṣugbọn ó dá àwọn ilé wa sí.’ ” Àwọn eniyan Israẹli wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose ati Aaroni.
Eks 12:21-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ìgbà náà ni Mose pé gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ jáde lọ, kí ẹ sì yan ọ̀dọ́-àgùntàn fún àwọn ìdílé yín, kí ẹ sì pa ẹran àjọ ìrékọjá OLúWA. Ẹ̀yin yóò sì mú ìdí-ewé hísópù, ẹ tì í bọ inú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà nínú ọpọ́n kí ẹ sì fi kun òkè à bá wọ ẹnu-ọ̀nà ilé yín àti ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìlẹ̀kùn yín. Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ jáde sí òde títí di òwúrọ̀. Ní ìgbà tí OLúWA bá ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Ejibiti láti kọlù wọn, yóò rí ẹ̀jẹ̀ ni òkè ẹnu-ọ̀nà àti ni ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà ilé yín, yóò sì ré ẹnu-ọ̀nà ilé náà kọjá, kì yóò gba apanirun láààyè láti wọ inú ilé e yín láti kọlù yín. “Ẹ pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ ó máa ṣe títí ayérayé láàrín yín àti àwọn ìran yín. Nígbà tí ẹ̀yin bá de ilẹ̀ tí OLúWA yóò fi fún un yín bí òun ti ṣe ìlérí, ẹ máa kíyèsi àjọ yìí. Ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni ohun tí àjọ yìí túmọ̀ sí fún un yín?’ Ẹ sọ fún wọn ni ìgbà náà, ‘Ẹbọ ìrékọjá sí OLúWA ni, ẹni tí ó rékọjá ilé àwọn ọmọ Israẹli ni ìgbà tí ó kọlu àwọn ara Ejibiti. Tí ó si da wa sí nígbà ti ó pa àwọn ara Ejibiti.’ ” Àwọn ènìyàn sì tẹríba láti sìn. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose àti Aaroni.