Eks 12:21-23
Eks 12:21-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Mose pè gbogbo awọn àgba Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ imú ọdọ-agutan fun ara nyin, gẹgẹ bi idile nyin, ki ẹ si pa irekọja na. Ẹnyin o si mú ìdi ewe-hissopu, ẹ o si fi bọ̀ ẹ̀jẹ ti o wà ninu awokoto, ẹ o si fi ẹ̀jẹ na ti o wà ninu awokoto kùn ara atẹrigba, ati opó ìha mejeji; ẹnikẹni ninu nyin kò si gbọdọ jade lati ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀ titi yio fi di owurọ̀. Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin.
Eks 12:21-23 Yoruba Bible (YCE)
Mose bá pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣa ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan ní ìdílé yín kọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì pa á fún ìrékọjá. Ẹ mú ìdì ewé hisopu, kí ẹ tì í bọ ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá gbè sinu àwo kòtò kan, kí ẹ fi ẹ̀jẹ̀ náà kun àtẹ́rígbà ati òpó ìlẹ̀kùn mejeeji. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò sì gbọdọ̀ jáde ninu ilé títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Nítorí pé, OLUWA yóo rékọjá, yóo sì pa àwọn ará Ijipti. Ṣugbọn nígbà tí ó bá rí ẹ̀jẹ̀ lára àtẹ́rígbà ati lára òpó ẹnu ọ̀nà mejeeji, OLUWA yóo ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kò sì ní jẹ́ kí apanirun wọ ilé yín láti pa yín.
Eks 12:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ìgbà náà ni Mose pé gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ jáde lọ, kí ẹ sì yan ọ̀dọ́-àgùntàn fún àwọn ìdílé yín, kí ẹ sì pa ẹran àjọ ìrékọjá OLúWA. Ẹ̀yin yóò sì mú ìdí-ewé hísópù, ẹ tì í bọ inú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà nínú ọpọ́n kí ẹ sì fi kun òkè à bá wọ ẹnu-ọ̀nà ilé yín àti ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìlẹ̀kùn yín. Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ jáde sí òde títí di òwúrọ̀. Ní ìgbà tí OLúWA bá ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Ejibiti láti kọlù wọn, yóò rí ẹ̀jẹ̀ ni òkè ẹnu-ọ̀nà àti ni ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà ilé yín, yóò sì ré ẹnu-ọ̀nà ilé náà kọjá, kì yóò gba apanirun láààyè láti wọ inú ilé e yín láti kọlù yín.