Eks 1:8-10
Eks 1:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọba titun miran si wa ijẹ ni Egipti, ti kò mọ́ Josefu. O si wi fun awọn enia rẹ̀ pe, kiye si i, enia awọn ọmọ Israeli npọ̀, nwọn si nlagbara jù wa lọ: Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a fi ọgbọ́n ba wọn ṣe; ki nwọn ki o máṣe bisi i, yio si ṣe nigbati ogun kan ba ṣẹ̀, nwọn o dàpọ mọ́ awọn ọtá wa pẹlu, nwọn o ma bá wa jà, nwọn o si jade kuro ni ilẹ yi.
Eks 1:8-10 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, ọba titun kan tí kò mọ Josẹfu gorí oyè, ní ilẹ̀ Ijipti. Ọba yìí sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ wò bí àwọn ọmọ Israẹli wọnyi ti pọ̀ tó, tí wọ́n sì lágbára jù wá lọ. Ẹ jẹ́ kí á fi ọgbọ́n bá wọn lò, nítorí bí wọ́n bá ń pọ̀ lọ báyìí, bí ogun bá bẹ́ sílẹ̀, wọn yóo darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa láti bá wa jà, wọn yóo sì sá kúrò ní ilẹ̀ yìí.”
Eks 1:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti. Ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ “Ẹ wò ó, àwọn ará Israẹli ti pọ̀ ní iye àti agbára jù fún wa. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti dá wọn lẹ́kun, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ogun bá sì bẹ́ sílẹ̀, wọn yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa, wọn yóò sì da ojú ìjà kọ wá, wọn yóò sì sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ yìí.”