Eks 1:17-19
Eks 1:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn awọn iyãgbà bẹ̀ru Ọlọrun, nwọn kò si ṣe bi ọba Egipti ti fi aṣẹ fun wọn, nwọn si da awọn ọmọkunrin si. Ọba Egipti si pè awọn iyãgbà na, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ṣe irú nkan yi ti ẹnyin si da awọn ọmọkunrin si? Awọn iyãgbà si wi fun Farao pe, nitoriti awọn obinrin Heberu kò ri bi awọn obinrin Egipti; nitoriti ara yá wọn, nwọn a si ti bí ki awọn iyãgbà to wọle tọ̀ wọn lọ.
Eks 1:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Ejibiti ti wí fún wọn; wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wà láààyè. Ọba Ejibiti pe àwọn agbẹ̀bí ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí? Èéṣe tí ẹ̀yin fi dá àwọn ọmọkùnrin si?” Àwọn agbẹ̀bí náà sì dá Farao lóhùn pé, “Àwọn obìnrin Heberu kò rí bí àwọn obìnrin Ejibiti, wọ́n ní agbára, wọ́n sì ti máa ń bí ọmọ kí àwọn agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”
Eks 1:17-19 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọrun; wọn kò tẹ̀lé àṣẹ tí ọba Ijipti pa fún wọn, pé kí wọn máa pa àwọn ọmọkunrin tí àwọn obinrin Heberu bá ń bí. Ọba Ijipti bá pe àwọn agbẹ̀bí náà, ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dá àwọn ọmọkunrin tí àwọn Heberu bí sí?” Wọ́n dá Farao lóhùn pé, “Àwọn obinrin Heberu yàtọ̀ sí àwọn obinrin Ijipti. Wọ́n lágbára, wọn a sì ti máa bímọ kí á tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”