Eks 1:15-16
Eks 1:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọba Egipti si wi fun awọn iyãgbà Heberu; orukọ ọkan ninu ẹniti ijẹ Ṣifra, ati orukọ ekeji ni Pua: O si wipe, Nigbati ẹnyin ba nṣe iṣẹ iyãgbà fun awọn obinrin Heberu, ti ẹnyin ba ri wọn ni ikunlẹ; bi o ba ṣe ọmọkunrin ni, njẹ ki ẹnyin ki o pa a; ṣugbọn bi o ba ṣe ọmọbinrin ni, njẹ on o yè.
Eks 1:15-16 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, ọba Ijipti pe àwọn obinrin Heberu tí wọ́n ń gbẹ̀bí, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣifira ati Pua, ó sọ fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá ń gbẹ̀bí fún àwọn obinrin Israẹli, tí ẹ sì rí i pé ọmọ tí wọ́n fẹ́ bí jẹ́ ọkunrin, ẹ pa á, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ obinrin ni, ẹ dá a sí.”
Eks 1:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọba Ejibiti sọ fún àwọn agbẹ̀bí Heberu ti orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣifura àti Pua pé: “Nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Heberu, tí ẹ sì kíyèsi wọn lórí ìkúnlẹ̀ ìrọbí wọn, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin ni ọmọ náà, ẹ pa á; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, ẹ jẹ́ kí ó wà láààyè.”