Eks 1:1-22

Eks 1:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti pẹlu Jakobu ni wọnyi; olukuluku pẹlu ile rẹ̀. Reubeni, Simeoni, Lefi, ati Judah; Issakari, Sebuluni, ati Benjamini; Dani ati Naftali, Gadi ati Aṣeri. Ati gbogbo ọkàn ti o ti inu Jakobu jade, o jẹ́ ãdọrin ọkàn: Josefu sa ti wà ni Egipti. Josefu si kú, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo iran na. Awọn ọmọ Israeli si bisi i, nwọn si pọ̀si i gidigidi, nwọn si rẹ̀, nwọn si di alagbara nla jọjọ; ilẹ na si kún fun wọn. Ọba titun miran si wa ijẹ ni Egipti, ti kò mọ́ Josefu. O si wi fun awọn enia rẹ̀ pe, kiye si i, enia awọn ọmọ Israeli npọ̀, nwọn si nlagbara jù wa lọ: Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a fi ọgbọ́n ba wọn ṣe; ki nwọn ki o máṣe bisi i, yio si ṣe nigbati ogun kan ba ṣẹ̀, nwọn o dàpọ mọ́ awọn ọtá wa pẹlu, nwọn o ma bá wa jà, nwọn o si jade kuro ni ilẹ yi. Nitorina ni nwọn ṣe yàn akoniṣiṣẹ le wọn, lati fi iṣẹ wọn pọ́n wọn loju. Nwọn si kọ́ ilu iṣura fun Farao, Pitomu ati Ramesesi. Bi nwọn si ti npọ́n wọn loju si i, bẹ̃ni nwọn mbisi i, ti nwọn si npọ̀. Inu wọn si bàjẹ́ nitori awọn ọmọ Israeli. Awọn ara Egipti si mu awọn ọmọ Israeli sìn li asìnpa: Nwọn si fi ìsin lile, li erupẹ ati ni briki ṣiṣe, ati ni oniruru ìsin li oko mu aiye wọn korò: gbogbo ìsin wọn ti nwọn mu wọn sìn, asìnpa ni. Ọba Egipti si wi fun awọn iyãgbà Heberu; orukọ ọkan ninu ẹniti ijẹ Ṣifra, ati orukọ ekeji ni Pua: O si wipe, Nigbati ẹnyin ba nṣe iṣẹ iyãgbà fun awọn obinrin Heberu, ti ẹnyin ba ri wọn ni ikunlẹ; bi o ba ṣe ọmọkunrin ni, njẹ ki ẹnyin ki o pa a; ṣugbọn bi o ba ṣe ọmọbinrin ni, njẹ on o yè. Ṣugbọn awọn iyãgbà bẹ̀ru Ọlọrun, nwọn kò si ṣe bi ọba Egipti ti fi aṣẹ fun wọn, nwọn si da awọn ọmọkunrin si. Ọba Egipti si pè awọn iyãgbà na, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ṣe irú nkan yi ti ẹnyin si da awọn ọmọkunrin si? Awọn iyãgbà si wi fun Farao pe, nitoriti awọn obinrin Heberu kò ri bi awọn obinrin Egipti; nitoriti ara yá wọn, nwọn a si ti bí ki awọn iyãgbà to wọle tọ̀ wọn lọ. Nitorina Ọlọrun ṣe rere fun awọn iyãgbà na: awọn enia na si mbisi i, nwọn si di alagbara koko. O si ṣe, nitoriti awọn iyãgbà bẹ̀ru Ọlọrun, on si kọle fun wọn. Farao si paṣẹ fun gbogbo awọn enia rẹ̀, wipe, Gbogbo ọmọkunrin ti a bí on ni ki ẹnyin gbé jù sinu odò, gbogbo awọn ọmọbinrin ni ki ẹnyin ki o dasi.

Eks 1:1-22 Yoruba Bible (YCE)

Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá Jakọbu wá sí Ijipti nìwọ̀nyí, olukuluku pẹlu ìdílé rẹ̀: Reubẹni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, Bẹnjamini, Dani, Nafutali, Gadi ati Aṣeri. Gbogbo àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Jakọbu jẹ́ aadọrin, Josẹfu ti wà ní Ijipti ní tirẹ̀. Nígbà tí ó yá, Josẹfu kú, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ náà kú ní ọ̀kọ̀ọ̀kan títí tí gbogbo ìran náà fi kú tán. Ṣugbọn àwọn arọmọdọmọ Israẹli pọ̀ sí i, wọ́n di alágbára gidigidi, wọ́n sì pọ̀ káàkiri ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí ó yá, ọba titun kan tí kò mọ Josẹfu gorí oyè, ní ilẹ̀ Ijipti. Ọba yìí sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ wò bí àwọn ọmọ Israẹli wọnyi ti pọ̀ tó, tí wọ́n sì lágbára jù wá lọ. Ẹ jẹ́ kí á fi ọgbọ́n bá wọn lò, nítorí bí wọ́n bá ń pọ̀ lọ báyìí, bí ogun bá bẹ́ sílẹ̀, wọn yóo darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa láti bá wa jà, wọn yóo sì sá kúrò ní ilẹ̀ yìí.” Nítorí náà, wọ́n yan àwọn akóniṣiṣẹ́ láti ni wọ́n lára pẹlu iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n lò wọ́n láti kọ́ ìlú Pitomi ati Ramesesi tíí ṣe àwọn ìlú ìṣúra fún Farao. Ṣugbọn bí wọ́n ti ń da àwọn ọmọ Israẹli láàmú tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, tí wọ́n sì ń tàn kálẹ̀. Ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí ba àwọn ará Ijipti. Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi iṣẹ́ àṣekára ni àwọn ọmọ Israẹli lára, wọ́n sì ń fòòró ẹ̀mí wọn pẹlu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ líle. Wọ́n ń po yẹ̀ẹ̀pẹ̀, wọ́n ń mọ bíríkì, wọ́n ń ṣiṣẹ́ ninu oko. Pẹlu ìnira ni wọ́n sì ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọn ń ṣe. Nígbà tí ó yá, ọba Ijipti pe àwọn obinrin Heberu tí wọ́n ń gbẹ̀bí, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣifira ati Pua, ó sọ fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá ń gbẹ̀bí fún àwọn obinrin Israẹli, tí ẹ sì rí i pé ọmọ tí wọ́n fẹ́ bí jẹ́ ọkunrin, ẹ pa á, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ obinrin ni, ẹ dá a sí.” Ṣugbọn àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọrun; wọn kò tẹ̀lé àṣẹ tí ọba Ijipti pa fún wọn, pé kí wọn máa pa àwọn ọmọkunrin tí àwọn obinrin Heberu bá ń bí. Ọba Ijipti bá pe àwọn agbẹ̀bí náà, ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dá àwọn ọmọkunrin tí àwọn Heberu bí sí?” Wọ́n dá Farao lóhùn pé, “Àwọn obinrin Heberu yàtọ̀ sí àwọn obinrin Ijipti. Wọ́n lágbára, wọn a sì ti máa bímọ kí á tó dé ọ̀dọ̀ wọn.” Nítorí náà, Ọlọrun ṣe àwọn agbẹ̀bí náà dáradára; àwọn eniyan Israẹli ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ń lágbára sí i. Nítorí pé àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọrun, ìdílé tiwọn náà pọ̀ síi. Farao bá pàṣẹ fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Gbogbo ọmọkunrin tí àwọn Heberu bá bí, ẹ máa gbé wọn sọ sinu odò Naili, ṣugbọn kí ẹ dá àwọn ọmọbinrin wọn sí.”

Eks 1:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìwọ̀nyí ni àwọn orúkọ ọmọ Israẹli tí wọ́n bá Jakọbu lọ sí Ejibiti, ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìdílé rẹ̀: Reubeni, Simeoni, Lefi àti Juda; Isakari, Sebuluni àti Benjamini; Dani àti Naftali; Gadi àti Aṣeri. Àwọn ìran Jakọbu sì jẹ́ àádọ́rin ní àpapọ̀; Josẹfu sì ti wà ní Ejibiti. Wàyí o, Josẹfu àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran náà kú, Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ń bí sí i, wọ́n ń pọ̀ sí i gidigidi, wọ́n kò sì ní òǹkà tí ó fi jẹ́ pé wọ́n kún ilẹ̀ náà. Nígbà náà ni ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti. Ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ “Ẹ wò ó, àwọn ará Israẹli ti pọ̀ ní iye àti agbára jù fún wa. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti dá wọn lẹ́kun, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ogun bá sì bẹ́ sílẹ̀, wọn yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa, wọn yóò sì da ojú ìjà kọ wá, wọn yóò sì sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ yìí.” Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pitomi àti Ramesesi gẹ́gẹ́ bí ìlú ìṣúra pamọ́ sí fún Farao. Ṣùgbọ́n bí a ti ń ni wọ́n lára tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, tiwọn sì ń tànkálẹ̀; Nítorí náà, àwọn ará Ejibiti bẹ̀rù nítorí àwọn ará Israẹli. Àwọn ará Ejibiti sì mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àsìnpa. Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Ejibiti ń lò wọ́n ní ìlòkulò. Ọba Ejibiti sọ fún àwọn agbẹ̀bí Heberu ti orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣifura àti Pua pé: “Nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Heberu, tí ẹ sì kíyèsi wọn lórí ìkúnlẹ̀ ìrọbí wọn, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin ni ọmọ náà, ẹ pa á; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, ẹ jẹ́ kí ó wà láààyè.” Ṣùgbọ́n àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Ejibiti ti wí fún wọn; wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wà láààyè. Ọba Ejibiti pe àwọn agbẹ̀bí ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí? Èéṣe tí ẹ̀yin fi dá àwọn ọmọkùnrin si?” Àwọn agbẹ̀bí náà sì dá Farao lóhùn pé, “Àwọn obìnrin Heberu kò rí bí àwọn obìnrin Ejibiti, wọ́n ní agbára, wọ́n sì ti máa ń bí ọmọ kí àwọn agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.” Nítorí náà Ọlọ́run ṣàánú fún àwọn agbẹ̀bí náà, àwọn ọmọ Israẹli sì ń le sí i, wọ́n sì ń pọ̀ sí i jọjọ. Nítorí pé àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, Ọlọ́run sì fún wọn ni ìdílé tiwọn. Nígbà náà ni Farao pàṣẹ yìí fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ pé; “Gbogbo ọmọkùnrin tí a bí ni kí ẹ gbé jù sínú odò Naili, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọbìnrin ni kí ẹ jẹ́ kí wọn ó wà láààyè.”