Est 9:18-22
Est 9:18-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn awọn Ju ti mbẹ ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹtala rẹ̀, ati li ọjọ kẹrinla rẹ̀; ati li ọjọ kẹ̃dogun rẹ̀ nwọn simi, nwọn si ṣe e li ọjọ àse ati inu didùn. Nitorina awọn Ju ti o wà ni iletò wọnni, ti nwọn ngbe ilu ti kò li odi, nwọn ṣe ọjọ kẹrinla oṣù Adari li ọjọ inu-didùn, ati àse, ati ọjọ rere, ati ọjọ ti olukulùku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀. Mordekai si kọwe nkan wọnyi, o si fi iwe ranṣẹ si gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, si awọn ti o sunmọ etile, ati awọn ti o jina. Lati fi eyi lelẹ larin wọn, ki nwọn ki o le ma pa ọjọ kẹrinla oṣù Adari, ati ọjọ kẹ̃dogun rẹ̀ mọ́ li ọdọdun. Bi ọjọ lọwọ eyiti awọn Ju simi kuro ninu awọn ọta wọn, ati oṣù ti a sọ ibanujẹ wọn di ayọ̀, ati ọjọ ọ̀fọ di ọjọ rere; ki nwọn ki o le sọ wọn di ọjọ àse, ati ayọ̀, ati ọjọ ti olukuluku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀, ati ẹbun fun awọn talaka.
Est 9:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn Júù tí ó wà ní Susa, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀. Nítorí náà ni àwọn Júù tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àsè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn. Mordekai ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ó sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù jákèjádò àgbáyé ọba Ahaswerusi, tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó wà ní jìnnà réré, Láti lè máa ṣe àjọyọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù Addari ní ọdọọdún Gẹ́gẹ́ bí àkókò tí àwọn Júù gba ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn, àti bí oṣù tí ìbànújẹ́ ẹ wọn yí padà di ayọ̀ àti tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn di ọjọ́ àjọyọ̀. Ó kọ ọ́ sí wọn láti máa pa ọjọ́ náà mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀ kí wọn sì máa fi oúnjẹ fún ara wọn, kí wọn sì máa fi ẹ̀bùn fún àwọn aláìní.
Est 9:18-22 Yoruba Bible (YCE)
Ní Susa, ọjọ́ kẹẹdogun oṣù ni wọ́n tó ṣe ayẹyẹ tiwọn. Ọjọ́ kẹtala ati ọjọ́ kẹrinla ni àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa pa àwọn ọ̀tá wọn, ní ọjọ́ kẹẹdogun, wọ́n sinmi, ó sì jẹ́ ọjọ́ àsè ati ayọ̀ fún wọn. Ìdí nìyí tí àwọn Juu tí wọn ń gbé àwọn agbègbè fi ya ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari sọ́tọ̀ fún ọjọ́ àsè, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn. Modekai kọ gbogbo nǹkan wọnyi sílẹ̀, Ó sì fi ranṣẹ sí àwọn Juu tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi ọba, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní òkèèrè, pé kí wọ́n ya ọjọ́ kẹrinla ati ọjọ́ kẹẹdogun oṣù Adari sọ́tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí àwọn Juu gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí ìbànújẹ́ ati ẹ̀rù wọn di ayọ̀, tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn sì di ọjọ́ àjọ̀dún. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àjọ̀dún ati ayọ̀, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn, tí wọn yóo máa fún àwọn talaka ní ẹ̀bùn.