Est 9:1-32

Est 9:1-32 Bibeli Mimọ (YBCV)

Njẹ li oṣù kejila, eyini ni oṣù Adari, li ọjọ kẹtala rẹ̀, ti ofin ọba ati aṣẹ rẹ̀ sunmọle lati mu u ṣẹ, li ọjọ ti awọn ọta awọn Ju ti rò pe, awọn o bori wọn, (bi o tilẹ ti jẹ pe, ati yi i pada pe, ki awọn Ju ki o bori awọn ti o korira wọn;) Awọn Ju kó ara wọn jọ ninu ilu wọn ninu gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, lati gbe ọwọ le iru awọn ti o nwá ifarapa wọn: ẹnikẹni kò si le kò wọn loju; nitori ẹ̀ru wọn bà gbogbo enia. Gbogbo awọn olori ìgberiko, ati awọn bãlẹ, ati awọn onidajọ, ati awọn ti nṣe iṣẹ ọba, ràn awọn Ju lọwọ, nitori ẹ̀ru Mordekai bà wọn. Nitori Mordekai tobi ni ile ọba, okiki rẹ̀ si kàn ja gbogbo ìgberiko: nitori ọkunrin yi Mordekai ntobi siwaju ati siwaju. Bayi ni awọn Ju a fi idà ṣá gbogbo awọn ọta wọn pa, ni pipa ati piparun, nwọn si ṣe awọn ọta ti o korira wọn bi nwọn ti fẹ. Ati ni Ṣuṣani ãfin awọn Ju pa ẹ̃dẹgbẹta ọkunrin run. Ati Farṣandata, ati Dalfoni, ati Aspata, Ati Porata, ati Adalia, ati Aridata, Ati Farmaṣta, ati Arisai, ati Aridai, ati Faisata, Awọn ọmọ Hamani, ọmọ Medata, mẹwẹwa, ọta awọn Ju ni nwọn pa; ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kàn nkan wọn. Li ọjọ na a mu iye awọn ti a pa ni Ṣuṣani ãfin wá siwaju ọba. Ọba si wi fun Esteri ayaba pe, Awọn Ju pa, nwọn si ti pa ẹ̃dẹgbẹta enia run ni Ṣuṣani ãfin, ati awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa: kini nwọn ha ṣe ni gbogbo ìgberiko ọba iyokù? nisisiyi kini ẹbẹ rẹ? a o si fi fun ọ tabi kini iwọ o si tun bère si i? a o si ṣe e. Nigbana ni Esteri wipe, Bi o ba wù ọba, jẹ ki a fi aṣẹ fun awọn Ju ti o wà ni Ṣuṣani ki nwọn ki o ṣe li ọ̀la pẹlu gẹgẹ bi aṣẹ ti oni, ki a si so awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa rọ̀ lori igi. Ọba si paṣẹ pe, ki a ṣe bẹ̃; a si pa aṣẹ na ni Ṣuṣani; a si so awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa rọ̀. Nitorina awọn Ju ti o wà ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹrinla oṣù Adari pẹlu, nwọn si pa ọ̃durun ọkunrin ni Ṣuṣani; ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kàn nkan wọn. Ṣugbọn awọn Ju miran, ti o wà ni ìgberiko ọba, kó ara wọn jọ, nwọn dide duro lati gbà ẹmi ara wọn là, nwọn si simi kuro lọwọ awọn ọta wọn, nwọn si pa ẹgbã mẹtadilogoji enia o le ẹgbẹrin ninu awọn ọta wọn, ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kan nkan wọn. Li ọjọ kẹtala oṣù Adari, ati li ọjọ kẹrinla rẹ̀ ni nwọn simi, nwọn si ṣe e li ọjọ àse ati ayọ̀. Ṣugbọn awọn Ju ti mbẹ ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹtala rẹ̀, ati li ọjọ kẹrinla rẹ̀; ati li ọjọ kẹ̃dogun rẹ̀ nwọn simi, nwọn si ṣe e li ọjọ àse ati inu didùn. Nitorina awọn Ju ti o wà ni iletò wọnni, ti nwọn ngbe ilu ti kò li odi, nwọn ṣe ọjọ kẹrinla oṣù Adari li ọjọ inu-didùn, ati àse, ati ọjọ rere, ati ọjọ ti olukulùku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀. Mordekai si kọwe nkan wọnyi, o si fi iwe ranṣẹ si gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, si awọn ti o sunmọ etile, ati awọn ti o jina. Lati fi eyi lelẹ larin wọn, ki nwọn ki o le ma pa ọjọ kẹrinla oṣù Adari, ati ọjọ kẹ̃dogun rẹ̀ mọ́ li ọdọdun. Bi ọjọ lọwọ eyiti awọn Ju simi kuro ninu awọn ọta wọn, ati oṣù ti a sọ ibanujẹ wọn di ayọ̀, ati ọjọ ọ̀fọ di ọjọ rere; ki nwọn ki o le sọ wọn di ọjọ àse, ati ayọ̀, ati ọjọ ti olukuluku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀, ati ẹbun fun awọn talaka. Awọn Ju si gbà lati ṣe bi nwọn ti bẹ̀rẹ si iṣe, ati bi Mordekai si ti kọwe si wọn. Pe, Hamani ọmọ Medata, ara Agagi nì, ọta gbogbo awọn Ju ti gbiro lati pa awọn Ju run, o si ti da Puri, eyinì ni ibo, lati pa wọn, ati lati run wọn; Ṣugbọn nigbati Esteri tọ̀ ọba wá, o fi iwe paṣẹ pe, ki ete buburu ti a ti pa si awọn Ju ki o le pada si ori on tikalarẹ̀, ati ki a so ati on ati awọn ọmọ rẹ̀ rọ̀ sori igi. Nitorina ni nwọn ṣe npè ọjọ wọnni ni Purimu bi orukọ Puri. Nitorina gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ inu iwe yi, ati nitori gbogbo eyi ti oju wọn ti ri nitori ọ̀ran yi, ati eyiti o ti ba wọn, Awọn Ju lanà rẹ̀, nwọn si gbà a kanri wọn, ati fun iru-ọmọ wọn, ati fun gbogbo awọn ti o dà ara wọn pọ̀ mọ wọn, pe ki o máṣe yẹ̀, ki nwọn ki o ma pa ọjọ mejeji wọnyi mọ́ gẹgẹ bi ikọwe wọn, ati gẹgẹ bi akokò wọn ti a yàn lọdọdun. Ati pe, ki nwọn ma ranti ọjọ wọnyi, ki nwọn si ma kiyesi i ni irandiran wọn gbogbo; olukuluku idile, olukuluku ìgberiko, ati olukuluku ilu; ati pe, ki Purimu wọnyi ki o máṣe yẹ̀ larin awọn Ju, tabi ki iranti wọn ki o máṣe parun ninu iru-ọmọ wọn. Nigbana ni Esteri ayaba, ọmọbinrin Abihaili, ati Mordekai, ara Juda, fi ọlá gbogbo kọwe, lati fi idi iwe keji ti Purimu yi mulẹ. O si fi iwe ranṣẹ si gbogbo awọn Ju, si ẹtadilãdoje ìgberiko ijọba Ahaswerusi, ọ̀rọ alafia ati otitọ. Lati fi idi ọjọ Purimu wọnyi mulẹ, li akokò wọn ti a yàn gẹgẹ bi Mordekai, ara Juda, ati Esteri ayaba ti paṣẹ fun wọn, ati bi nwọn ti pinnu rẹ̀ fun ara wọn, ati fun iru-ọmọ wọn, ọ̀ran ãwẹ ati ẹkún wọn. Aṣẹ Esteri si fi idi ọ̀ran Purimu yi mulẹ; a si kọ ọ sinu iwe.

Est 9:1-32 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kẹtala oṣù Adari tíí ṣe oṣù kejila, nígbà tí wọ́n ń múra láti ṣe ohun tí òfin ọba wí, ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá rò pé ọwọ́ wọn yóo tẹ àwọn Juu, ṣugbọn, tí ó jẹ́ ọjọ́ tí àwọn Juu ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn; àwọn Juu péjọ ninu àwọn ìlú wọn ní àwọn ìgbèríko ilẹ̀ Ahasu-erusi ọba, wọ́n múra láti bá àwọn tí wọ́n fẹ́ pa wọ́n run jà. Kò sí ẹni tí ó lè kò wọ́n lójú nítorí pé gbogbo àwọn eniyan ni wọ́n ń bẹ̀rù wọn. Gbogbo àwọn olórí àwọn agbègbè, àwọn baálẹ̀, àwọn gomina ati àwọn aláṣẹ ọba ran àwọn Juu lọ́wọ́, nítorí pé ẹ̀rù Modekai ń bà wọ́n. Modekai di eniyan pataki ní ààfin; òkìkí rẹ̀ kàn dé gbogbo agbègbè, agbára rẹ̀ sì ń pọ̀ sí i. Àwọn Juu fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n pa wọ́n run. Ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí àwọn tí wọ́n kórìíra wọn. Ní ìlú Susa nìkan, àwọn Juu pa ẹẹdẹgbẹta (500) eniyan. Wọ́n sì pa Paṣandata, Dalifoni, Asipata, Porata, Adalia, Aridata, Pamaṣita, Arisai, Aridai ati Faisata. Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá jẹ́ ọmọ Hamani, ọmọ Hamedata, ọ̀tá àwọn Juu, ṣugbọn wọn kò fọwọ́ kan àwọn ẹrù wọn. Ní ọjọ́ náà, wọ́n mú ìròyìn iye àwọn tí wọ́n pa ní Susa wá fún ọba. Ọba sọ fún Ẹsita Ayaba pé, “Àwọn Juu ti pa ẹẹdẹgbẹta (500) ọkunrin ati àwọn ọmọ Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ní Susa. Kí ni àwọn Juu tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè ṣe? Nisinsinyii, kí ni ìbéèrè rẹ? A óo sì ṣe é fún ọ.” Ẹsita dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, jẹ́ kí á fún àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní sí àwọn ọ̀tá wọn ní ọ̀la, kí á sì so àwọn ọmọ Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá rọ̀ sí orí igi.” Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àṣẹ bá jáde láti Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọ Hamani rọ̀ sí orí igi. Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa tún parapọ̀, wọ́n sì pa ọọdunrun (300) ọkunrin sí i. Ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn. Àwọn Juu tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè kó ara wọn jọ láti gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n pa ẹgbaa mejidinlogoji ó dín ẹgbẹrun (75,000) ninu àwọn tí wọ́n kórìíra wọn, ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn. Ní ọjọ́ kẹtala oṣù Adari ni èyí ṣẹlẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrinla, wọ́n sinmi; ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ àsè ati ayọ̀. Ní Susa, ọjọ́ kẹẹdogun oṣù ni wọ́n tó ṣe ayẹyẹ tiwọn. Ọjọ́ kẹtala ati ọjọ́ kẹrinla ni àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa pa àwọn ọ̀tá wọn, ní ọjọ́ kẹẹdogun, wọ́n sinmi, ó sì jẹ́ ọjọ́ àsè ati ayọ̀ fún wọn. Ìdí nìyí tí àwọn Juu tí wọn ń gbé àwọn agbègbè fi ya ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari sọ́tọ̀ fún ọjọ́ àsè, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn. Modekai kọ gbogbo nǹkan wọnyi sílẹ̀, Ó sì fi ranṣẹ sí àwọn Juu tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi ọba, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní òkèèrè, pé kí wọ́n ya ọjọ́ kẹrinla ati ọjọ́ kẹẹdogun oṣù Adari sọ́tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí àwọn Juu gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí ìbànújẹ́ ati ẹ̀rù wọn di ayọ̀, tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn sì di ọjọ́ àjọ̀dún. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àjọ̀dún ati ayọ̀, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn, tí wọn yóo máa fún àwọn talaka ní ẹ̀bùn. Àwọn Juu gbà láti máa ṣe bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ati bí àṣẹ Modekai. Nítorí Hamani, ọmọ Hamedata, láti ìran Agagi, ọ̀tá àwọn Juu ti pète láti pa àwọn Juu run. Ó ti ṣẹ́ gègé, tí wọn ń pè ní Purimu, láti mọ ọjọ́ tí yóo pa àwọn Juu run patapata. Ṣugbọn nígbà tí Ẹsita lọ sọ́dọ̀ ọba, ọba kọ̀wé àṣẹ tí ó mú kí ìpinnu burúkú tí Hamani ní sí àwọn Juu pada sí orí òun tìkararẹ̀, a sì so òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ rọ̀ sórí igi. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ọjọ́ náà ní Purimu gẹ́gẹ́ bí orúkọ Purimu, gègé tí Hamani ṣẹ́. Nítorí ìwé tí Modekai kọ ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ni àwọn Juu fi sọ ọ́ di òfin fún ara wọn, ati fún arọmọdọmọ wọn, ati fún àwọn tí wọ́n bá di Juu, pé ní àkókò rẹ̀, ní ọdọọdún, ọjọ́ mejeeji yìí gbọdọ̀ jẹ́ ọjọ́ àsè, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Modekai, ati pé kí wọ́n máa ranti àwọn ọjọ́ wọnyi, kí wọ́n sì máa pa wọ́n mọ́ láti ìrandíran, ní gbogbo ìdílé, ní gbogbo agbègbè ati ìlú. Àwọn ọjọ́ Purimu wọnyi kò gbọdọ̀ yẹ̀ láàrin àwọn Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìrántí wọn kò gbọdọ̀ parun láàrin arọmọdọmọ wọn. Ẹsita Ayaba, ọmọbinrin Abihaili, ati Modekai, tíí ṣe Juu kọ ìwé láti fi ìdí ìwé keji nípa Purimu múlẹ̀. Wọ́n kọ ìwé sí gbogbo àwọn Juu ní gbogbo agbègbè mẹtẹẹtadinlaadoje (127) tí ó wà ninu ìjọba Ahasu-erusi. Ìwé náà kún fún ọ̀rọ̀ alaafia ati òtítọ́, pé wọn kò gbọdọ̀ gbàgbé láti máa pa àwọn ọjọ́ Purimu mọ́ ní àkókò wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Modekai ati Ẹsita Ayaba pa fún àwọn Juu, ati irú ìlànà tí wọ́n là sílẹ̀ fún ara wọn ati arọmọdọmọ wọn, nípa ààwẹ̀ ati ẹkún wọn. Àṣẹ tí Ẹsita pa fi ìdí àjọ̀dún Purimu múlẹ̀, wọ́n sì kọ ọ́ sílẹ̀.

Est 9:1-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari, tí ó yẹ kí a mú àṣẹ tí ọba pa wá sí ìmúṣẹ. Ní ọjọ́ yìí ni ọ̀tá àwọn Júù rò pé àwọn yóò borí i wọn, ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ti yìí padà, àwọn Júù sì na ọwọ́ agbára tó ga lórí àwọn tí ó kórìíra wọn. Àwọn Júù péjọ ní àwọn ìlú u wọn ní gbogbo agbègbè ọba Ahaswerusi láti kọlu àwọn tó ń wá ìparun wọn. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè dojúkọ wọ́n, nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ìlú tókù ń bẹ̀rù u wọn. Gbogbo àwọn ọlọ́lá ìgbèríko, àwọn alákòóso, àwọn baálẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ ọba ran àwọn Júù lọ́wọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù u Mordekai. Mordekai sì jẹ́ ẹni pàtàkì ní ààfin ọba, òkìkí rẹ̀ sì tàn jákèjádò àwọn ìgbèríko, ó sì ní agbára kún agbára. Àwọn Júù sì gé gbogbo àwọn ọ̀tá a wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì run wọ́n, wọ́n sì ṣe ohun tí ó wù wọ́n sí àwọn tí ó kórìíra wọn. Ní ilé ìṣọ́ ti Susa, àwọn Júù pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọkùnrin run Wọ́n sì tún pa Parṣandata, Dalfoni, Aspata, Porata, Adalia, Aridata, Parmaṣta, Arisai, Aridai àti Faisata, Àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hamani, ọmọ Hammedata, ọ̀tá àwọn Júù. Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn. Ní ọjọ́ náà gan an ni a mú iye àwọn tí a pa ní ilé ìṣọ́ ti Susa wá fún ọba. Ọba sì sọ fún Esteri ayaba pé, “Àwọn Júù ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí i ṣe ọmọ Hamani ní ilé ìṣọ́ Susa run. Kí ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbèríko ọba tókù? Báyìí kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? A ó sì tún fi fún ọ.” Esteri sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, fún àwọn Júù tí ó wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní kí wọn ṣe bákan náà ní ọ̀la, kí a sì so àwọn ọmọkùnrin Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà rọ̀ sórí igi.” Nítorí náà ọba pàṣẹ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. A sì gbé àṣẹ kan jáde ní Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hamani kọ́. Àwọn Júù tí ó wà ní Susa sì péjọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari, wọ́n sì pa ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin ní Susa, Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn. Lákokò yìí, àwọn tókù nínú àwọn Júù tí wọ́n wà ní agbègbè ọba náà tún kó ara wọn jọ láti dáàbò bo ara wọn kí wọn sì sinmi lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn. Wọ́n sì pa ẹgbàá-mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀rin (75,000) àwọn tí ó kórìíra wọn ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn. Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Addari, wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀. Àwọn Júù tí ó wà ní Susa, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀. Nítorí náà ni àwọn Júù tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àsè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn. Mordekai ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ó sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù jákèjádò àgbáyé ọba Ahaswerusi, tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó wà ní jìnnà réré, Láti lè máa ṣe àjọyọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù Addari ní ọdọọdún Gẹ́gẹ́ bí àkókò tí àwọn Júù gba ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn, àti bí oṣù tí ìbànújẹ́ ẹ wọn yí padà di ayọ̀ àti tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn di ọjọ́ àjọyọ̀. Ó kọ ọ́ sí wọn láti máa pa ọjọ́ náà mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀ kí wọn sì máa fi oúnjẹ fún ara wọn, kí wọn sì máa fi ẹ̀bùn fún àwọn aláìní. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Júù gbà láti máa ṣe àjọyọ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ń ṣe bí Mordekai ti kọ̀wé sí wọn. Nítorí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá gbogbo àwọn Júù, ti gbèrò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di puri (èyí tí í ṣe ìbò) fún ìsọdahoro àti ìparun wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí Esteri sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hamani ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí òun fúnrarẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi. (Nítorí náà a pe àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ní Purimu, láti ara ọ̀rọ̀ puri ). Nítorí ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé yìí àti nítorí ohun tí wọ́n ti rí àti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn, Àwọn Júù fi lélẹ̀, wọ́n sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ara wọn àti fún irú àwọn ọmọ wọn àti gbogbo àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn, kò sì ní kúrò, wọn yóò sì máa pa àwọn ọjọ́ méjèèjì yìí mọ́ ní gbogbo ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ àti àkókò tí a yàn. A gbọdọ̀ máa ṣe ìrántí àwọn ọjọ́ wọ̀nyí kí a sì máa pa wọ́n mọ́ ní ìrandíran ní gbogbo ìdílé, àti ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú. A gbọdọ̀ máa ṣe àwọn ọjọ́ Purimu wọ̀nyí ní àárín àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ di ohun ìgbàgbé láàrín irú àwọn ọmọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni Esteri ayaba, ọmọbìnrin Abihaili, pẹ̀lú Mordekai ará a Júù, kọ̀wé pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìdí ìwé kejì nípa Purimu yìí múlẹ̀. Mordekai sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù, sí ìgbèríko mẹ́tà-dínláàádóje (127) ní ilẹ̀ ọba Ahaswerusi ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́. Láti fi ìdí àwọn ọjọ́ ọ Purimu yìí múlẹ̀ ní àkókò tí wọ́n yàn, gẹ́gẹ́ bí Mordekai ará Juda, àti Esteri ayaba ti pa á láṣẹ fún wọn, àti bí wọ́n ṣe fi lélẹ̀ fún ara wọn àti irú àwọn ọmọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú àkókò àwẹ̀ àti ẹkún wọn. Àṣẹ Esteri sì fi ìdí ìlànà Purimu wọ̀nyí múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé àkọsílẹ̀.