Est 8:1-6
Est 8:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni ijọ na ni Ahaswerusi ọba fi ile Hamani ọta awọn Ju, jìn Esteri, ayaba; Mordekai si wá siwaju ọba; nitori Esteri ti sọ bi o ti ri si on. Ọba si bọ́ oruka rẹ̀, ti o ti gbà lọwọ Hamani, o si fi i fun Mordekai. Esteri si fi Mordekai ṣe olori ile Hamani. Esteri si tun sọ niwaju ọba, o wolẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀, o si fi omijé bẹ̀ ẹ pe, ki o mu buburu Hamani, ara Agagi kuro, ati ete ti o ti pa si awọn Ju. Nigbana ni ọba nà ọpá-alade wura si Esteri. Bẹ̃ni Esteri dide, o si duro niwaju ọba. O si wi pe, bi o ba wù ọba, bi mo ba si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀, ti nkan na ba si tọ́ loju ọba, bi mo ba si wù ọba, jẹ ki a kọwe lati yí iwe ete Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi nì pada, ti o ti kọ lati pa awọn Ju run, ti o wà ni gbogbo ìgberiko ọba. Nitori pe, emi ti ṣe le ri ibi ti yio wá ba awọn enia mi? tabi emi ti ṣe le ri iparun awọn ibatan mi?
Est 8:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ náà gan-an ni ọba Ahasu-erusi fún Ẹsita Ayaba ní ilé Hamani, ọ̀tá àwọn Juu. Ẹsita wá sọ fún ọba pé eniyan òun ni Modekai. Láti ìgbà náà ni ọba sì ti mú Modekai wá siwaju rẹ̀. Ọba mú òrùka tí ó gbà lọ́wọ́ Hamani, ó fi bọ Modekai lọ́wọ́. Ẹsita sì fi Modekai ṣe olórí ilé Hamani. Ẹsita tún bẹ ọba, ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pẹlu omijé, pé kí ọba yí ète burúkú tí Hamani, ará Agagi, pa láti run àwọn Juu pada. Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá àṣẹ wúrà sí Ẹsita. Ó dìde, ó sì dúró níwájú ọba, ó ní, “Bí inú kabiyesi bá dùn sí mi, tí mo sì rí ojurere rẹ̀, bí ó bá fẹ́ràn mi, tí ọ̀rọ̀ náà bá tọ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí ìwé àṣẹ kan ti ọ̀dọ̀ ọba jáde, láti yí ète burúkú tí Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, pa pada, àní ète tí ó pa láti run gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà ní ìjọba rẹ̀. Mo ṣe lè rí jamba tí ń bọ̀, tabi ìparun tí ń bọ̀ sórí àwọn eniyan mi, kí n sì dákẹ́?”
Est 8:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kan náà ni ọba Ahaswerusi fún Esteri ayaba ní ilé e Hamani, ọ̀tá àwọn Júù. Mordekai sì wá síwájú ọba, nítorí Esteri ti sọ bí ó ṣe jẹ́ sí ọba. Ọba sì bọ́ òrùka dídán an rẹ̀, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ Hamani ó sì fi fún Mordekai, Esteri sì yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí ilé e Hamani. Esteri sì tún bẹ ọba lórí ìkúnlẹ̀, pẹ̀lú omijé lójú. Ó bẹ̀ ẹ́ kí ó fi òpin sí ètò búburú Hamani ará Agagi, èyí tí ó ti pète fún àwọn Júù. Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá aládé wúrà sí Esteri ó sì dìde, ó dúró níwájú rẹ̀. Ó wí pé, “Bí ó bá wu ọba, tí ó bá sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ojúrere tí ó sì rò pé ohun tí ó dára ni láti ṣe, tí ó bá sì ní inú dídùn pẹ̀lú mi, jẹ́ kí a kọ ìwé àṣẹ láti yí ète tí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, tí ó kọ́ pàṣẹ pé kí a pa àwọn Júù tí wọ́n wà ní gbogbo àgbáyé ìjọba ọba run. Nítorí báwo ni èmi yóò ṣe fi ara dà á tí èmi yóò sì rí kí ibi máa ṣubú lu àwọn ènìyàn mi? Báwo ni èmi yóò ṣe fi ara dà á, tí èmi yóò sì máa wo ìparun àwọn ìdílé mi?”