Est 8:1-17

Est 8:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ni ijọ na ni Ahaswerusi ọba fi ile Hamani ọta awọn Ju, jìn Esteri, ayaba; Mordekai si wá siwaju ọba; nitori Esteri ti sọ bi o ti ri si on. Ọba si bọ́ oruka rẹ̀, ti o ti gbà lọwọ Hamani, o si fi i fun Mordekai. Esteri si fi Mordekai ṣe olori ile Hamani. Esteri si tun sọ niwaju ọba, o wolẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀, o si fi omijé bẹ̀ ẹ pe, ki o mu buburu Hamani, ara Agagi kuro, ati ete ti o ti pa si awọn Ju. Nigbana ni ọba nà ọpá-alade wura si Esteri. Bẹ̃ni Esteri dide, o si duro niwaju ọba. O si wi pe, bi o ba wù ọba, bi mo ba si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀, ti nkan na ba si tọ́ loju ọba, bi mo ba si wù ọba, jẹ ki a kọwe lati yí iwe ete Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi nì pada, ti o ti kọ lati pa awọn Ju run, ti o wà ni gbogbo ìgberiko ọba. Nitori pe, emi ti ṣe le ri ibi ti yio wá ba awọn enia mi? tabi emi ti ṣe le ri iparun awọn ibatan mi? Nigbana ni Ahaswerusi ọba wi fun Esteri ayaba, ati fun Mordekai ara Juda na pe, Sa wò o, emi ti fi ile Hamani fun Esteri; on ni nwọn si ti so rọ̀ lori igi, nitoripe o ti gbe ọwọ le awọn Ju. Ẹnyin kọwe ẹ̀wẹ li orukọ ọba, nitori awọn Ju bi ẹnyin ti fẹ́, ki ẹ si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀: nitori iwe ti a ba fi orukọ ọba kọ, ti a ba si fi òruka ọba ṣe edidi, ẹnikan kò le yi i pada. Nigbana li a si pè awọn akọwe ọba li akokò na ni oṣù kẹta, eyini ni oṣù Sifani, li ọjọ kẹtalelogun rẹ̀; a si kọ ọ gẹgẹ bi Mordekai ti paṣẹ si awọn Ju, ati si awọn bãlẹ, ati awọn onidajọ, ati olori awọn ìgberiko metadilãdoje, si olukulùku ìgberiko gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati si olukulùku enia gẹgẹ bi ède wọn ati si awọn Ju gẹgẹ bi ikọwe wọn, ati gẹgẹ bi ède wọn. Orukọ Ahaswerusi ọba li a fi kọ ọ, a si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀; o si fi iwe wọnni rán awọn ojiṣẹ lori ẹṣin, ti o gùn ẹṣin yiyara, ani ibãka, ọmọ awọn abo ẹṣin. Ninu eyiti ọba fi aṣẹ fun gbogbo awọn Ju, ti o wà ni ilu gbogbo, lati kó ara wọn jọ, ati lati duro gbà ẹmi ara wọn là, lati parun, lati pa, ati lati mu ki gbogbo agbara awọn enia, ati ìgberiko na, ti o ba fẹ kọlu wọn, pẹlu awọn ọmọ wẹwẹ ati awọn obinrin ki o ṣegbe; ki nwọn ki o si kó ìni wọn fun ara wọn, Li ọjọ kanṣoṣo ni gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, li ọjọ kẹtala, oṣù kejila ti iṣe oṣù Adari. Ọ̀ran inu iwe na ni lati paṣẹ ni gbogbo ìgberiko lati kede rẹ̀ fun gbogbo enia, ki awọn Ju ki o le mura de ọjọ na, lati gbẹsan ara wọn lara awọn ọta wọn. Bẹ̃ni awọn ojiṣẹ́ ti nwọn gun ẹṣin yiyara ati ibãka jade lọ, nitori aṣẹ ọba, nwọn yara, nwọn sare. A si pa aṣẹ yi ni Ṣuṣani ãfin. Mordekai si jade kuro niwaju ọba, ninu aṣọ ọba, alaro ati funfun, ati ade wura nla, ati ẹ̀wu okùn ọ̀gbọ kikuná, ati elese aluko; ayọ̀ ati inu didùn si wà ni ilu Ṣuṣani. Awọn Ju si ni imọlẹ, ati inu didùn, ati ayọ̀ ati ọlá. Ati ni olukulùku ìgberiko, ati ni olukuluku ilu nibikibi ti ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀ ba de, awọn Ju ni ayọ̀ ati inu-didùn, àse, ati ọjọ rere. Ọ̀pọlọpọ awọn enia ilẹ na si di enia Juda; nitori ẹ̀ru awọn Ju ba wọn.

Est 8:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ náà gan-an ni ọba Ahasu-erusi fún Ẹsita Ayaba ní ilé Hamani, ọ̀tá àwọn Juu. Ẹsita wá sọ fún ọba pé eniyan òun ni Modekai. Láti ìgbà náà ni ọba sì ti mú Modekai wá siwaju rẹ̀. Ọba mú òrùka tí ó gbà lọ́wọ́ Hamani, ó fi bọ Modekai lọ́wọ́. Ẹsita sì fi Modekai ṣe olórí ilé Hamani. Ẹsita tún bẹ ọba, ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pẹlu omijé, pé kí ọba yí ète burúkú tí Hamani, ará Agagi, pa láti run àwọn Juu pada. Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá àṣẹ wúrà sí Ẹsita. Ó dìde, ó sì dúró níwájú ọba, ó ní, “Bí inú kabiyesi bá dùn sí mi, tí mo sì rí ojurere rẹ̀, bí ó bá fẹ́ràn mi, tí ọ̀rọ̀ náà bá tọ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí ìwé àṣẹ kan ti ọ̀dọ̀ ọba jáde, láti yí ète burúkú tí Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, pa pada, àní ète tí ó pa láti run gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà ní ìjọba rẹ̀. Mo ṣe lè rí jamba tí ń bọ̀, tabi ìparun tí ń bọ̀ sórí àwọn eniyan mi, kí n sì dákẹ́?” Ahasu-erusi ọba dá Ẹsita Ayaba ati Modekai Juu lóhùn pé, “Mo ti so Hamani kọ́ sórí igi, nítorí ète tí ó pa lórí àwọn Juu, mo sì ti fún Ẹsita ní ilé rẹ̀. Kọ ohunkohun tí ó bá wù ọ́ nípa àwọn Juu ní orúkọ ọba, kí o sì fi òrùka ọba tẹ̀ ẹ́ bí èdìdì. Nítorí pé òfin tí a bá kọ ní orúkọ ọba, tí ó sì ní èdìdì ọba, ẹnikẹ́ni kò lè yí i pada mọ́.” Ọjọ́ kẹtalelogun oṣù kẹta, tíí ṣe oṣù Sifani ni Modekai pe àwọn akọ̀wé ọba, wọ́n sì kọ òfin sílẹ̀ nípa àwọn Juu gẹ́gẹ́ bí Modekai ti sọ fún wọn. Wọ́n fi ranṣẹ sí àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn gomina, ati àwọn olórí àwọn agbègbè, láti India títí dé Etiopia, gbogbo wọn jẹ́ agbègbè mẹtadinlaadoje (127). Wọ́n kọ ọ́ sí agbègbè kọ̀ọ̀kan ati ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, wọ́n sì kọ sí àwọn Juu náà ní èdè wọn. Wọ́n kọ ìwé náà ní orúkọ Ahasu-erusi ọba, wọ́n sì fi òrùka ọba tẹ̀ ẹ́ bí èdìdì. Wọ́n fi rán àwọn iranṣẹ tí wọn ń gun àwọn ẹṣin tí wọ́n lè sáré dáradára, àwọn ẹṣin tí wọn ń lò fún iṣẹ́ ọba, àwọn tí wọ́n ń bọ́ fún ìlò ọba. Òfin náà fún àwọn Juu ní àṣẹ láti kó ara wọn jọ, láti gba ara wọn sílẹ̀, ati láti run orílẹ̀-èdè tabi ìgbèríko tí ó bá dojú ìjà kọ wọ́n, ati àwọn ọmọ wọn, ati àwọn obinrin wọn. Wọ́n lè run ọ̀tá wọn láì ku ẹnìkan, kí wọ́n sì gba gbogbo ìní wọn. Àṣẹ yìí gbọdọ̀ múlẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Pasia, ní ọjọ́ tí wọ́n yàn láti pa gbogbo àwọn Juu, ní ọjọ́ kẹtala oṣù kejila, tíí ṣe oṣù Adari. Àkọsílẹ̀ yìí di òfin fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèríko, kí àwọn Juu baà lè múra láti gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn ní ọjọ́ náà. Pẹlu àṣẹ ọba, àwọn iranṣẹ gun àwọn ẹṣin ọba, wọ́n sì yára lọ. Wọ́n pa àṣẹ náà ní Susa tíí ṣe olú-ìlú. Modekai jáde ní ààfin ninu aṣọ ọba aláwọ̀ aró ati funfun pẹlu adé wúrà ńlá. Ó wọ aṣọ ìlékè aláwọ̀ elése-àlùkò, ìlú Susa sì ń hó fún ayọ̀. Àwọn Juu sì ní ìmọ́lẹ̀ ati inú dídùn, ayọ̀ ati ọlá. Ní gbogbo agbègbè, ati ní àwọn ìlú tí ìkéde yìí dé, ìdùnnú ati ayọ̀ kún inú àwọn Juu, wọ́n se àsè pẹlu ayẹyẹ, wọ́n sì gba ìsinmi. Àwọn ẹ̀yà mìíràn sọ ara wọn di Juu, nítorí pé ẹ̀rù àwọn Juu ń bà wọ́n.

Est 8:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kan náà ni ọba Ahaswerusi fún Esteri ayaba ní ilé e Hamani, ọ̀tá àwọn Júù. Mordekai sì wá síwájú ọba, nítorí Esteri ti sọ bí ó ṣe jẹ́ sí ọba. Ọba sì bọ́ òrùka dídán an rẹ̀, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ Hamani ó sì fi fún Mordekai, Esteri sì yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí ilé e Hamani. Esteri sì tún bẹ ọba lórí ìkúnlẹ̀, pẹ̀lú omijé lójú. Ó bẹ̀ ẹ́ kí ó fi òpin sí ètò búburú Hamani ará Agagi, èyí tí ó ti pète fún àwọn Júù. Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá aládé wúrà sí Esteri ó sì dìde, ó dúró níwájú rẹ̀. Ó wí pé, “Bí ó bá wu ọba, tí ó bá sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ojúrere tí ó sì rò pé ohun tí ó dára ni láti ṣe, tí ó bá sì ní inú dídùn pẹ̀lú mi, jẹ́ kí a kọ ìwé àṣẹ láti yí ète tí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, tí ó kọ́ pàṣẹ pé kí a pa àwọn Júù tí wọ́n wà ní gbogbo àgbáyé ìjọba ọba run. Nítorí báwo ni èmi yóò ṣe fi ara dà á tí èmi yóò sì rí kí ibi máa ṣubú lu àwọn ènìyàn mi? Báwo ni èmi yóò ṣe fi ara dà á, tí èmi yóò sì máa wo ìparun àwọn ìdílé mi?” Ọba Ahaswerusi dá Esteri ayaba àti Mordekai ará a Júù náà lóhùn pé, “Nítorí Hamani kọlu àwọn ará a Júù, èmi ti fi ilé e rẹ̀ fún Esteri, wọ́n sì ti ṣo ó kọ́ sórí igi. Nísinsin yìí, kọ ìwé àṣẹ mìíràn ní orúkọ ọba bí àwọn Júù ṣe jẹ́ pàtàkì sí ọ, kí o sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì dì í, nítorí kò sí àkọsílẹ̀ tí a bá ti kọ ní orúkọ ọba tí a sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì tí a lè yìí padà.” Lẹ́sẹ̀kan náà àwọn akọ̀wé ọba péjọ ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, oṣù Sifani. Wọ́n kọ gbogbo àṣẹ Mordekai sí àwọn Júù, àti sí àwọn alákòóso baálẹ̀ àti àwọn ọlọ́lá ìgbèríko mẹ́tà-dínláàádóje tí ó lọ láti India títí ó fi dé Kuṣi. Kí a kọ àṣẹ náà ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé àti bí èdè olúkúlùkù àti pẹ̀lú sí àwọn Júù ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé àti èdè e wọn. Mordekai sì fi àṣẹ ọba Ahaswerusi kọ̀wé, ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀, ó rán an lọ ní kíákíá, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ ayaba, tiwọn yára bí àṣà àwọn tí wọ́n ń gun ẹṣin tí ó yára, ní pàtàkì èyí tí a ń bọ́ fún ọba. Àṣẹ ọba sì dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní gbogbo ìlú láti kó ara wọn jọ kí wọn sì dáàbò bo ara wọn; láti pa, láti run àti láti kọlu ogunkógun orílẹ̀-èdè kórílẹ̀ èdè kankan tàbí ìgbèríko tí ó bá fẹ́ kọlù wọ́n, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn; kí ẹ sì kó gbogbo ohun ìní àwọn ọ̀tá wọn. Ọjọ́ tí a yàn fún àwọn Júù ní gbogbo agbègbè ọba Ahaswerusi láti ṣe nǹkan yìí ni ọjọ́ kẹtàlá èyí tí í ṣe oṣù kejìlá, oṣù Addari. Ọkàn ìwé àṣẹ náà ni kí a gbé jáde gẹ́gẹ́ bí òfin ní gbogbo ìgbèríko kí ẹ sì jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún gbogbo ènìyàn ìlú nítorí àwọn Júù yóò le è múra ní ọjọ́ náà láti gbẹ̀san fún ara wọn lára àwọn ọ̀tá wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ ayaba tiwọn yára bí àṣà tí wọ́n ń gun ẹṣin ọba, sáré jáde, wọ́n sáré lọ nípa àṣẹ ọba. A sì tún gbé àṣẹ náà jáde ní ilé ìṣọ́ ti Susa. Mordekai sì kúrò níwájú ọba, ó wọ aṣọ aláró àti funfun, ó dé adé e wúrà ńlá pẹ̀lú ìgbànú elése àlùkò dáradára, ìlú Susa sì ṣe àjọyọ̀ ńlá. Àsìkò ìdùnnú àti ayọ̀, inú dídùn àti ọlá ni ó jẹ́ fún àwọn Júù. Ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú, ní gbogbo ibi tí àṣẹ ọba dé, ni ayọ̀ àti inú dídùn ti wà láàrín àwọn Júù, wọ́n sì ń ṣe àsè àti àjọyọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú tókù sọ ara wọn di Júù nítorí ẹ̀rù àwọn Júù bà wọ́n.