Est 7:1-10

Est 7:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)

Bẹ̃ni ọba ati Hamani wá iba Esteri ayaba jẹ àse. Ọba si tun wi fun Esteri ni ijọ keji ni ibi àse ti nwọn nmu ọti-waini pe, kini ẹbẹ rẹ, Esteri ayaba? a o si fi fun ọ: ki si ni ibère rẹ? a o si ṣe e, ani lọ ide idaji ijọba. Nigbana ni Esteri ayaba dahùn wi pe, bi mo ba ri ore-ọfẹ loju rẹ ọba, bi o ba si wù ọba, mo bẹbẹ ki a fi ẹmi mi bùn mi nipa ẹbẹ mi, ati awọn enia mi nipa ibère mi. Nitori a ti tà wa, emi ati awọn enia mi, lati run wa, lati pa wa, ki a le parun. Ṣugbọn bi o ṣe pe, a ti tà wa fun ẹrúkunrin, ati ẹrúbirin ni, emi iba pa ẹnu mi mọ́, bi o tilẹ jẹ pe ọta na kò le di ofò ọba. Nigbana ni Ahaswerusi ọba dahùn, o si wi fun Esteri ayaba pe, Tali oluwa rẹ̀ na, nibo li o si wà, ti o jẹ gbe e le ọkàn rẹ̀ lati ṣe bẹ̃? Esteri si wi pe, ọlọtẹ enia ati ọta na ni Hamani, ẹni buburu yi. Nigbana ni ẹ̀ru ba Hamani niwaju ọba ati ayaba. Ọba si dide ni ibinu rẹ̀ kuro ni ibi àse ti nwọn nmu ọti-waini, o bọ́ si àgbala ãfin. Hamani si dide duro lati tọrọ ẹmi rẹ̀ lọwọ Esteri ayaba; nitori o ti ri pe ọba ti pinnu ibi si on. Nigbana ni ọba pẹhinda lati inu àgbala ãfin sinu ibiti nwọn ti nmu ọti-waini, Hamani si ṣubu le ibi ìrọgbọkú lori eyi ti Esteri joko; nigbana ni ọba wi pe, yio ha tẹ́ ayaba lọdọ mi ninu ile bi? Bi ọ̀rọ na ti ti ẹnu ọba jade, nwọn bò oju Hamani. Harbona ọkan ninu awọn ìwẹfa si wi niwaju ọba pe, Sa wò o, igi ti o ga ni ãdọta igbọnwọ ti Hamani ti rì nitori Mordekai ti o ti sọ ọ̀rọ rere fun ọba, o wà li oró ni ile Hamani. Ọba si wi pe, Ẹ so o rọ̀ lori rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn so Hamani rọ̀ sori igi ti o ti rì fun Mordekai; ibinu ọba si rọ̀.

Est 7:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Ọba ati Hamani lọ bá Ayaba Ẹsita jẹ àsè. Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń mu ọtí, ọba tún bi Ẹsita pé, “Ẹsita, Ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ, a óo ṣe é fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ, gbogbo rẹ̀ ni yóo sì tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́, àní títí kan ìdajì ìjọba mi.” Ẹsita ayaba dáhùn, ó ní, “Kabiyesi, bí mo bá rí ojurere rẹ, bí ó bá sì wù ọ́, dá ẹ̀mí mi ati ti àwọn eniyan mi sí. Wọ́n ti ta èmi ati àwọn eniyan mi fún pípa, wọn ó sì pa wá run. Bí ó bá jẹ́ pé wọ́n ta tọkunrin tobinrin wa bí ẹrú lásán ni, n kì bá tí yọ ìwọ kabiyesi lẹ́nu rárá, nítorí a kò lè fi ìnira wa wé àdánù tí yóo jẹ́ ti ìwọ ọba.” Ahasu-erusi ọba bi Ẹsita Ayaba pé, “Ta ni olúwarẹ̀, níbo ni ẹni náà wà, tí ń gbèrò láti dán irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wò?” Ẹsita bá dá a lóhùn pé, “Ọlọ̀tẹ̀ ati ọ̀tá náà ni Hamani eniyan burúkú yìí.” Ẹ̀rù ba Hamani gidigidi níwájú ọba ati ayaba. Ọba dìde kúrò ní ibi àsè náà pẹlu ibinu, ó jáde lọ sinu àgbàlá ààfin. Nígbà tí Hamani rí i pé ọba ti pinnu ibi fún òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Ẹsita Ayaba fún ẹ̀mí rẹ̀. Bí ọba ti pada wá láti inú àgbàlá sí ibi tí wọ́n ti ń mu ọtí, ó rí Hamani tí ó ṣubú sí ibi àga tí Ẹsita rọ̀gbọ̀kú sí. Ọba ní, “Ṣé yóo tún máa fi ọwọ́ pa Ayaba lára lójú mi ni, ninu ilé mi?” Ní kété tí ọba sọ̀rọ̀ yìí tán, wọ́n faṣọ bo Hamani lójú. Habona, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, bá sọ fún ọba pé, “Igi kan, tí ó ga ní aadọta igbọnwọ (mita 22) wà ní ilé rẹ̀, tí ó ti rì mọ́lẹ̀ láti gbé Modekai kọ́ sí, Modekai tí ó gba ẹ̀mí rẹ là.” Ọba bá ní kí wọ́n lọ gbé Hamani kọ́ sí orí rẹ̀. Wọ́n bá gbé Hamani kọ́ sí orí igi tí ó ti rì mọ́lẹ̀ fún Modekai, nígbà náà ni inú ọba tó rọ̀.

Est 7:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọba àti Hamani sì lọ sí àpèjẹ pẹ̀lú Esteri ayaba, Bí wọ́n sì ṣe ń mu wáìnì ní ọjọ́ kejì yìí, ọba sì tún béèrè pé, “Esteri ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọba à mi, n ó fi fún ọ.” Nígbà náà ni ayaba Esteri dáhùn, “Bí èmi bá rí ojúrere rẹ, ìwọ ọba, bí ó bá sì tẹ́ ọláńlá à rẹ lọ́rùn, fún mi ní ẹ̀mí mi, èyí ni ẹ̀bẹ̀ mi. Kí o sì pa àwọn ènìyàn mi mọ́—èyí ni ìbéèrè mi. Nítorí a ti ta èmi àti àwọn ènìyàn mi fún àwọn tí yóò pa wá run, à ti ṣe ìdájọ́ wa fún pípa àti píparẹ́. Bí a bá tilẹ̀ tà wá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ǹ bá dákẹ́, nítorí irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ kò tó èyí tí à ń yọ ọba lẹ́nu sí.” Ọba Ahaswerusi bi Esteri ayaba léèrè pé, “Ta a ni ẹni náà? Níbo ni ẹni náà wà tí kò bẹ̀rù láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀?” Esteri sọ wí pé, “Alátakò àti ọ̀tá náà ni Hamani aláìníláárí yìí.” Nígbà náà ni Hamani wárìrì níwájú ọba àti ayaba. Ọba sì dìde pẹ̀lú ìbínú, ó fi wáìnì sílẹ̀ ó sì jáde lọ sí àgbàlá ààfin. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hamani, ti rí i dájú pé ọba ti pinnu láti pa òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Esteri ayaba nítorí ẹ̀mí rẹ̀. Bí ọba ṣe padà dé láti àgbàlá ààfin wá sí gbọ̀ngàn àsè náà, Hamani ṣubú sórí àga tí Esteri ayaba fẹ̀yìn tì. Ọba sì pariwo pé, “Yóò ha tún tẹ́ ayaba níbí yìí, nínú ilé, ní ojú mi bí?” Ní kété tí ọba sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde, wọ́n da aṣọ bo Hamani lójú. Nígbà náà Harbona ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà tó ń dúró níwájú ọba, sọ wí pé, “igi tí ó ga tó ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà marunlélaadọrin ni Hamani ti rì sí ẹ̀gbẹ́ ilé e rẹ̀. Ó ṣe é fún Mordekai, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọba.” Ọba wí pé, ẹ so ó rọ̀ sórí i rẹ́! Wọ́n sì so Hamani sórí igi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún Mordekai, ìbínú ọba sì rọ̀.