Est 6:11-14
Est 6:11-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Hamani mu aṣọ ati ẹṣin na, o si ṣe Mordekai li ọṣọ́, o si mu u là igboro ilu lori ẹṣin, o si kigbe niwaju rẹ̀ pe, Bayi li a o ṣe fun ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun. Mordekai si tun pada wá si ẹnu-ọ̀na ile ọba, ṣugbọn Hamani yara lọ si ile rẹ̀ ti on ti ibinujẹ, o si bò ori rẹ̀. Hamani si sọ gbogbo ohun ti o ba a, fun Sereṣi obinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀. Nigbana ni awọn enia rẹ̀, amoye, ati Sereṣi obinrin rẹ̀, wi fun u pe, Bi Mordekai ba jẹ iru-ọmọ awọn Ju, niwaju ẹniti iwọ ti bẹ̀rẹ si iṣubu na, iwọ, kì yio le bori rẹ̀, ṣugbọn iwọ o ṣubu niwaju rẹ̀ dandan. Bi nwọn si ti mba a sọ̀rọ lọwọ, awọn ìwẹfa ọba de, lati wá mu Hamani yára wá si ibi àse ti Esteri sè.
Est 6:11-14 Yoruba Bible (YCE)
Hamani lọ mú ẹ̀wù ati ẹṣin náà, ó ṣe Modekai lọ́ṣọ̀ọ́, ó gbé e gun ẹṣin, ó sì ń ké níwájú rẹ̀ bí ó ti ń fà á káàkiri gbogbo ìlú pé, “Ẹ wo ohun tí ọba ṣe fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí láti dá lọ́lá.” Lẹ́yìn náà, Modekai pada sí ẹnu ọ̀nà ààfin, ṣugbọn Hamani sáré pada lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́, ó sì bo orí rẹ̀. Ó sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi, iyawo rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ ati iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí Modekai, ẹni tí o ti bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀ níwájú rẹ̀ bá jẹ́ Juu, o kò ní lè ṣẹgun rẹ̀, òun ni yóo ṣẹgun rẹ.” Bí wọ́n ti ń bá Hamani sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni àwọn ìwẹ̀fà ọba dé láti yára mú un lọ sí ibi àsè Ẹsita.
Est 6:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni Hamani ṣe mú aṣọ àti ẹṣin náà. Ó fi wọ Mordekai, Mordekai sì wà lórí ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, ó sì ń kéde níwájú rẹ̀ pé, “Èyí ni a ó ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!” Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Mordekai padà sí ẹnu-ọ̀nà ọba. Ṣùgbọ́n Hamani sáré lọ ilé, ó sì bo orí rẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, Hamani sì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn olùbádámọ̀ràn rẹ̀ àti ìyàwó o rẹ̀ sọ fún un pé, “Níwọ́n ìgbà tí Mordekai ti jẹ́ ẹ̀yà Júù, níwájú ẹni tí ìṣubú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀, ìwọ kò lè rí ẹ̀yìn in rẹ̀—dájúdájú ìwọ yóò parun!” Bí wọ́n ṣe ń bá a sọ̀rọ̀, àwọn ìwẹ̀fà ọba wọlé, wọ́n sì kán Hamani lójú láti lọ sí ibi àsè tí Esteri ti pèsè.