Est 6:1-14

Est 6:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)

Li oru na ọba kò le sùn, o si paṣẹ pe, ki a mu iwe iranti, ani irohin awọn ọjọ wá, a si kà wọn niwaju ọba. A si ri pe, ati kọ ọ pe, Mordekai ti sọ ti Bigtani, ati Tereṣi, awọn ìwẹfa ọba meji, oluṣọ iloro, awọn ẹniti nwá ọ̀na lati gbe ọwọ le Ahaswerusi ọba. Ọba si wi pe, Iyìn ati ọlá wo li a fi fun Mordekai nitori eyi? Nigbana ni awọn ọmọ-ọdọ ọba ti nṣe iranṣẹ fun u wi pe, a kò ṣe nkankan fun u. Ọba si wi pe, Tani mbẹ ni àgbala? Hamani si ti de àgbala akọkàn ile ọba, lati ba ọba sọ ọ lati so Mordekai rọ̀ sori igi giga ti o ti rì fun u. Awọn ọmọ-ọdọ ọba si wi fun u pe, Sa wò o, Hamani duro ni agbala, Ọba si wi pe, jẹ ki o wọle. Bẹ̃ni Hamani si wọle wá, Ọba si wi fun u pe, kini a o ṣe fun ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun? Njẹ Hamani rò ninu ọkàn ara rẹ̀ pe, Tani inu ọba le dùn si lati bù ọlá fun jù emi tikalami lọ? Hamani si da ọba lohùn pe, ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun. Jẹ ki a mu aṣọ ọba ti ọba ima wọ̀, ati ẹṣin ti ọba ima gùn, ati ade ọba ti ima gbe kà ori rẹ̀ wá; Ki a si fi ẹ̀wu ati ẹṣin yi le ọwọ ọkan ninu awọn ijoye ọba ti o lọlajùlọ, ki nwọn fi ṣe ọṣọ fun ọkunrin na, ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun, ki o si mu u gẹṣin là igboro ilu, ki o si ma kigbe niwaju rẹ̀ pe, Bayi li a o ṣe fun ọkunrin na, ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun. Nigbana ni ọba wi fun Hamani pe, yara kánkán, mu ẹ̀wu ati ẹṣin na, bi iwọ ti wi, ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ fun Mordekai, ara Juda nì, ti njoko li ẹnu ọ̀na ile ọba: ohunkohun kò gbọdọ yẹ̀ ninu ohun ti iwọ ti sọ. Nigbana ni Hamani mu aṣọ ati ẹṣin na, o si ṣe Mordekai li ọṣọ́, o si mu u là igboro ilu lori ẹṣin, o si kigbe niwaju rẹ̀ pe, Bayi li a o ṣe fun ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun. Mordekai si tun pada wá si ẹnu-ọ̀na ile ọba, ṣugbọn Hamani yara lọ si ile rẹ̀ ti on ti ibinujẹ, o si bò ori rẹ̀. Hamani si sọ gbogbo ohun ti o ba a, fun Sereṣi obinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀. Nigbana ni awọn enia rẹ̀, amoye, ati Sereṣi obinrin rẹ̀, wi fun u pe, Bi Mordekai ba jẹ iru-ọmọ awọn Ju, niwaju ẹniti iwọ ti bẹ̀rẹ si iṣubu na, iwọ, kì yio le bori rẹ̀, ṣugbọn iwọ o ṣubu niwaju rẹ̀ dandan. Bi nwọn si ti mba a sọ̀rọ lọwọ, awọn ìwẹfa ọba de, lati wá mu Hamani yára wá si ibi àse ti Esteri sè.

Est 6:1-14 Yoruba Bible (YCE)

Ní òru ọjọ́ náà, ọba kò lè sùn. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n gbé ìwé àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìjọba rẹ̀ wá, kí wọ́n sì kà á sí etígbọ̀ọ́ òun. Wọ́n kà á ninu àkọsílẹ̀ pé Modekai tú àṣírí Bigitana ati Tereṣi, àwọn ìwẹ̀fà meji tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọba, tí wọ́n dìtẹ̀ láti pa Ahasu-erusi ọba. Ọba bèèrè pé irú ọlá wo ni a dá Modekai fún ohun tí ó ṣe yìí? Wọ́n dá a lóhùn pé ẹnikẹ́ni kò ṣe nǹkankan fún un. Ọba bèèrè pé, “Ta ló wà ninu àgbàlá?” Àkókò náà ni Hamani wọ inú àgbàlá ààfin ọba, láti bá ọba sọ̀rọ̀ láti so Modekai rọ̀ sórí igi tí ó rì mọ́lẹ̀. Àwọn iranṣẹ ọba dá a lóhùn pé, “Hamani wà níbẹ̀ tí ó ń duro ní àgbàlá.” Ọba sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí ó wọlé.” Bí Hamani tí ń wọlé ni ọba bi í pé, “Kí ló yẹ kí á ṣe fún ẹni tí inú ọba dùn sí?” Hamani rò ó ninu ara rẹ̀ pé, ta ni ọba ìbá tún dá lọ́lá bíkòṣe òun. Nítorí náà, ó dá ọba lóhùn pé, “Báyìí ni ó ṣe yẹ kí á dá ẹni tí inú ọba dùn sí lọ́lá: kí wọ́n mú aṣọ ìgúnwà ọba, tí ọba ti wọ̀ rí, ati ẹṣin tí ó ti gùn rí, kí wọ́n sì fi adé ọba dé ẹni náà lórí, kí wọ́n kó wọn fún ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ, kí ó fi ṣe ẹni náà lọ́ṣọ̀ọ́, kí ó gbé e gun ẹṣin, kí ó sì fà á káàkiri gbogbo ìlú, kí ó máa kéde pé, ‘Ẹ wo ohun tí ọba ṣe fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí láti dá a lọ́lá.’ ” Ọba bá sọ fún Hamani pé, “Yára lọ mú aṣọ ìgúnwà, ati ẹṣin náà, kí o sì ṣe bí o ti wí sí Modekai, Juu, tí ó máa ń jókòó sí ẹnu ọ̀nà ààfin.” Hamani lọ mú ẹ̀wù ati ẹṣin náà, ó ṣe Modekai lọ́ṣọ̀ọ́, ó gbé e gun ẹṣin, ó sì ń ké níwájú rẹ̀ bí ó ti ń fà á káàkiri gbogbo ìlú pé, “Ẹ wo ohun tí ọba ṣe fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí láti dá lọ́lá.” Lẹ́yìn náà, Modekai pada sí ẹnu ọ̀nà ààfin, ṣugbọn Hamani sáré pada lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́, ó sì bo orí rẹ̀. Ó sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi, iyawo rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ ati iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí Modekai, ẹni tí o ti bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀ níwájú rẹ̀ bá jẹ́ Juu, o kò ní lè ṣẹgun rẹ̀, òun ni yóo ṣẹgun rẹ.” Bí wọ́n ti ń bá Hamani sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni àwọn ìwẹ̀fà ọba dé láti yára mú un lọ sí ibi àsè Ẹsita.

Est 6:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní òru ọjọ́ náà ọba kò le è sùn; nítorí náà, ó pàṣẹ kí wọn mú ìwé ìrántí wá, àkọsílẹ̀ ìjọba rẹ̀, wọ́n mú un wá wọ́n sì kà á sí létí. Wọ́n rí àkọsílẹ̀ níbẹ̀ pé Mordekai tí sọ àṣírí Bigitana àti Tereṣi, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà, tí wọ́n ń gbèrò láti pa ọba Ahaswerusi. Ọba béèrè pé, “Kí ni ọlá àti iyì tí Mordekai ti gbà fún èyí?” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Kò tí ì sí ohun tí a ṣe fún un.” Ọba wí pé, “Ta ni ó wà nínú àgbàlá?” Nísinsin yìí, Hamani ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ àgbàlá ìta ààfin ni láti sọ fún ọba nípa síso Mordekai lórí igi tí ó ti rì fún un. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Hamani ni ó wà níbẹ̀ ó dúró sí inú àgbàlá.” Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ mú un wọlé wá.” Nígbà tí Hamani wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni kí a ṣe fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti bu ọlá fún?” Nísinsin yìí Hamani sì ro èyí fúnrarẹ̀ pé, “Ta ni ó wà níbẹ̀ tí ọba fẹ́ dá lọ́lá ju èmi lọ?” Nítorí náà Hamani dá ọba lóhùn pé, “Fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, jẹ́ kí wọn kí ó mú aṣọ ọba èyí tí ọba ń wọ̀ àti ẹṣin tí ọba máa ń gùn, pẹ̀lú ọ̀kan lára adé ọba kí a fi dé e ní orí. Jẹ́ kí a fi aṣọ àti ẹṣin lé ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ lọ́wọ́, kí wọn wọ aṣọ náà fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, kí wọn sì sìn ín gun ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, kí wọn máa kéde níwájú rẹ̀ pé, ‘Èyí ni a ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!’ ” Ọba pàṣẹ fún Hamani pé, “Lọ lẹ́sẹ̀kan náà. Mú aṣọ náà àti ẹṣin kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ fún Mordekai ará a Júù, ẹni tí ó jókòó sí ẹnu-ọ̀nà ọba. Má ṣe fi ohunkóhun sílẹ̀ nínú ohun tí o ti yàn.” Bẹ́ẹ̀ ni Hamani ṣe mú aṣọ àti ẹṣin náà. Ó fi wọ Mordekai, Mordekai sì wà lórí ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, ó sì ń kéde níwájú rẹ̀ pé, “Èyí ni a ó ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!” Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Mordekai padà sí ẹnu-ọ̀nà ọba. Ṣùgbọ́n Hamani sáré lọ ilé, ó sì bo orí rẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, Hamani sì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn olùbádámọ̀ràn rẹ̀ àti ìyàwó o rẹ̀ sọ fún un pé, “Níwọ́n ìgbà tí Mordekai ti jẹ́ ẹ̀yà Júù, níwájú ẹni tí ìṣubú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀, ìwọ kò lè rí ẹ̀yìn in rẹ̀—dájúdájú ìwọ yóò parun!” Bí wọ́n ṣe ń bá a sọ̀rọ̀, àwọn ìwẹ̀fà ọba wọlé, wọ́n sì kán Hamani lójú láti lọ sí ibi àsè tí Esteri ti pèsè.