Est 5:3-8
Est 5:3-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni ọba bi i pe, kini iwọ nfẹ́, Esteri ayaba? ati kini ẹ̀bẹ rẹ̀? ani de idajì ijọba li a o si fi fun ọ. Esteri si dahùn pe, bi o ba dara loju ọba, jẹ ki ọba ati Hamani ki o wá loni si àse mi, ti mo ti mura silẹ fun u. Nigbana ni ọba wi pe, ẹ mu ki Hamani ki o yara, ki on ki o le ṣe bi Esteri ti wi. Bẹ̃ni ọba ati Hamani wá si àse na ti Esteri ti sè silẹ. Ọba si wi fun Esteri nibiti nwọn gbe nmu ọti-waini pe, kini ibere rẹ? a o si fi fun ọ: ki si ni ẹ̀bẹ rẹ? ani de idajì ijọba, a o si ṣe e. Nigbana ni Esteri dahùn, o si wi pe, ẹ̀bẹ mi ati ibère mi ni pe, Bi mo ba ri ore-ọfẹ loju ọba, bi o ba si wù ọba lati fi ohun ti emi ntọrọ fun mi, ati lati ṣe ohun ti emi mbère fun mi, jẹ ki ọba ati Hamani ki o wá si àse ti emi o si tun sè fun wọn, emi o si ṣe li ọla bi ọba ti wi.
Est 5:3-8 Yoruba Bible (YCE)
Ọba bi ayaba Ẹsita pé, “Ẹsita, kí ló dé? Kí ni ẹ̀dùn ọkàn rẹ? A óo fún ọ, títí dé ìdajì ìjọba mi.” Ẹsita bá dáhùn pé, “Bí inú kabiyesi bá dùn sí mi, mo fẹ́ kí kabiyesi ati Hamani wá sí ibi àsè tí n óo sè fun yín ní alẹ́ òní.” Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ lọ pe Hamani wá kíákíá, kí á lè lọ ṣe ohun tí Ẹsita bèèrè.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati Hamani ṣe lọ sí ibi àsè tí Ẹsita ti sè sílẹ̀. Bí wọn tí ń mu ọtí, ọba tún bi Ẹsita léèrè pé, “Kí ni ìbéèrè rẹ Ẹsita, a óo ṣe é fún ọ, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ ni a óo jẹ́ kí ó tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ títí dé ìdajì ìjọba mi.” Ẹsita bá dáhùn pé, “Ìbéèrè ati ẹ̀bẹ̀ mi ni pé, bí inú kabiyesi bá dùn sí mi láti ṣe ohun tí mò ń fẹ́, ati láti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, kí kabiyesi ati Hamani wá síbi àsè tí n óo sè fún wọn ní ọ̀la. Nígbà náà ni n óo sọ ohun tí ó wà ní ọkàn mi.”
Est 5:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ọba béèrè pé, “Kí ni ó dé, ayaba Esteri? Kí ni o fẹ́? Bí ó tilẹ̀ ṣe títí dé ìdajì ọba mi, àní, a ó fi fún ọ.” Esteri sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, jẹ́ kí ọba, pẹ̀lú Hamani, wá lónìí sí ibi àsè tí èmi ti pèsè fún un.” Ọba sì wí pé, “ẹ mú Hamani wá kíákíá, nítorí kí a lè ṣe ohun tí Esteri béèrè fún un.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti Hamani lọ sí ibi àsè tí Esteri ti pèsè. Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì, ọba tún béèrè lọ́wọ́ Esteri, “Báyìí pé: kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìwọ ń béèrè fún? Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọba mi, a ó fi fún ọ.” Esteri sì dáhùn, “Ẹ̀bẹ̀ mi àti ìbéèrè mi ni èyí: Bí ọba bá fi ojúrere rẹ̀ fún mi, tí ó bá sì tẹ́ ọba lọ́rùn láti gba ẹ̀bẹ̀ mi àti láti mú ìbéèrè mi ṣẹ, jẹ́ kí ọba àti Hamani wá ní ọ̀la sí ibi àsè tí èmi yóò pèsè fún wọn. Nígbà náà ni èmi yóò dáhùn ìbéèrè ọba.”