Est 4:13-14
Est 4:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Mordekai sọ ki a da Esteri lohùn pe, Máṣe rò ninu ara rẹ pe, iwọ o là ninu ile ọba jù gbogbo awọn Ju lọ. Nitori bi iwọ ba pa ẹnu rẹ mọ́ patapata li akokò yi, nigbana ni iranlọwọ ati igbala awọn Ju yio dide lati ibomiran wá; ṣugbọn iwọ ati ile baba rẹ li a o parun: tali o si mọ̀ bi nitori iru akokò bayi ni iwọ ṣe de ijọba?
Est 4:13-14 Yoruba Bible (YCE)
ó tún ranṣẹ sí Ẹsita pada, ó ní, “Má rò pé ìwọ nìkan óo là láàrin àwọn Juu, nítorí pé o wà ní ààfin ọba. Bí o bá dákẹ́ ní irú àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́, ati ìgbàlà yóo ti ibòmíràn wá fún àwọn Juu, ṣugbọn a óo pa ìwọ ati àwọn ará ilé baba rẹ run. Ta ni ó sì lè sọ, bóyá nítorí irú àkókò yìí ni o fi di ayaba?”
Est 4:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Mordekai sọ kí a dá Esteri lóhùn pé; “Má ṣe rò nínú ara rẹ pé nítorí pé ìwọ wà ní ilé ọba ìwọ nìkan là láàrín gbogbo àwọn Júù. Nítorí bí ìwọ bá dákẹ́ ní àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ fún àwọn Júù yóò dìde láti ibòmíràn, ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ìdílé baba à rẹ yóò ṣègbé. Ta ni ó mọ̀ wí pé nítorí irú àkókò yìí ni o ṣe wà ní ipò ayaba?”