Est 4:12-17
Est 4:12-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si sọ ọ̀rọ Esteri fun Mordekai. Nigbana ni Mordekai sọ ki a da Esteri lohùn pe, Máṣe rò ninu ara rẹ pe, iwọ o là ninu ile ọba jù gbogbo awọn Ju lọ. Nitori bi iwọ ba pa ẹnu rẹ mọ́ patapata li akokò yi, nigbana ni iranlọwọ ati igbala awọn Ju yio dide lati ibomiran wá; ṣugbọn iwọ ati ile baba rẹ li a o parun: tali o si mọ̀ bi nitori iru akokò bayi ni iwọ ṣe de ijọba? Nigbana ni Esteri rán wọn lọ ifi èsi yi fun Mordekai pe, Lọ, pè awọn Ju ti a le ri ni Ṣuṣani jọ, ki ẹnyin si ma gbãwẹ, fun mi, ki ẹnyin ki o máṣe jẹun, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe mu ni ijọ mẹta t'ọsan t'oru: emi pẹlu ati awọn iranṣẹbinrin mi yio gbãwẹ bẹ̃ gẹgẹ; bẹ̃li emi o si wọ̀ ile tọ̀ ọba lọ, ti o lòdi si ofin; bi mo ba ṣègbe, mo ṣègbe. Bẹ̃ni Mordekai ba ọ̀na rẹ̀ lọ, o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Esteri ti paṣẹ fun u.
Est 4:12-17 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Modekai gbọ́ ìdáhùn yìí láti ọ̀dọ̀ Ẹsita, ó tún ranṣẹ sí Ẹsita pada, ó ní, “Má rò pé ìwọ nìkan óo là láàrin àwọn Juu, nítorí pé o wà ní ààfin ọba. Bí o bá dákẹ́ ní irú àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́, ati ìgbàlà yóo ti ibòmíràn wá fún àwọn Juu, ṣugbọn a óo pa ìwọ ati àwọn ará ilé baba rẹ run. Ta ni ó sì lè sọ, bóyá nítorí irú àkókò yìí ni o fi di ayaba?” Ẹsita bá ranṣẹ sí Modekai, ó ní, “Lọ kó gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa jọ, kí ẹ gba ààwẹ̀ fún mi fún ọjọ́ mẹta, láìjẹ, láìmu, láàárọ̀ ati lálẹ́. Èmi ati àwọn iranṣẹ mi náà yóo máa gbààwẹ̀ níhìn-ín. Lẹ́yìn náà, n óo lọ rí ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin, bí n óo bá kú, kí n kú.” Modekai bá lọ, ó ṣe bí Ẹsita ti pàṣẹ fún un.
Est 4:12-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí a sọ ọ̀rọ̀ Esteri fún Mordekai, Nígbà náà ni Mordekai sọ kí a dá Esteri lóhùn pé; “Má ṣe rò nínú ara rẹ pé nítorí pé ìwọ wà ní ilé ọba ìwọ nìkan là láàrín gbogbo àwọn Júù. Nítorí bí ìwọ bá dákẹ́ ní àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ fún àwọn Júù yóò dìde láti ibòmíràn, ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ìdílé baba à rẹ yóò ṣègbé. Ta ni ó mọ̀ wí pé nítorí irú àkókò yìí ni o ṣe wà ní ipò ayaba?” Nígbà náà ni Esteri rán iṣẹ́ yìí sí Mordekai: “Lọ, kí o kó gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní Susa jọ, kí ẹ sì gbààwẹ̀ fún mi. Ẹ má ṣe jẹun tàbí omi fún ọjọ́ mẹ́ta, ní òru àti ní ọ̀sán. Èmi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi náà yóò gbààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti ṣe. Nígbà tí ẹ bá ṣe èyí, èmi yóò tọ ọba lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin. Bí mo bá sì ṣègbé, mo ṣègbé.” Bẹ́ẹ̀ ni Mordekai lọ, ó sì sọ gbogbo ohun tí Esteri pàṣẹ fún un.