Est 3:7-11
Est 3:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li oṣù kini, eyinì ni oṣù Nisani, li ọdun kejila ijọba Ahaswerusi, nwọn da purimu, eyinì ni, ìbo, niwaju Hamani, lati ọjọ de ọjọ, ati lati oṣù de oṣù lọ ide oṣù kejila, eyinì ni oṣù Adari. Hamani si sọ fun Ahaswerusi ọba pe, awọn enia kan fọn kakiri, nwọn si tuka lãrin awọn enia ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ, ofin wọn si yatọ si ti gbogbo enia; bẹ̃ni nwọn kò si pa ofin ọba mọ́; nitorina kò yẹ fun ọba lati da wọn si. Bi o ba wù ọba, jẹ ki a kọwe rẹ̀ pe, ki a run wọn: emi o si wọ̀n ẹgbãrun talenti fadaka fun awọn ti a fi iṣẹ na rán, ki nwọn ki o le mu u wá sinu ile iṣura ọba. Ọba si bọ́ oruka rẹ̀ kuro li ọwọ rẹ̀, o si fi fun Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi, ọta awọn Ju. Ọba si wi fun Hamani pe, a fi fadaka na bùn ọ, ati awọn enia na pẹlu, lati fi wọn ṣe bi o ti dara loju rẹ.
Est 3:7-11 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọdún kejila ìjọba Ahasu-erusi, Hamani pinnu láti yan ọjọ́ tí ó wọ̀, nítorí náà, ní oṣù kinni tíí ṣe oṣù Nisani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́ gègé tí wọn ń pè ní Purimu, níwájú Hamani láti ọjọ́ dé ọjọ́ ati láti oṣù dé oṣù, títí dé oṣù kejila tíí ṣe oṣù Adari. Nígbà náà ni Hamani lọ bá Ahasu-erusi ọba, ó sọ fún un pé, “Àwọn eniyan kan wà tí wọ́n fọ́n káàkiri ààrin àwọn eniyan ati ní gbogbo agbègbè ìjọba rẹ; òfin wọn kò bá ti gbogbo eniyan mu, wọn kò sì pa àṣẹ ọba mọ́. Kò dára kí o gbà wọ́n láàyè ninu ìjọba rẹ. Bí ó bá dùn mọ́ Kabiyesi ninu, jẹ́ kí àṣẹ kan jáde lọ láti pa wọ́n run. N óo sì gbé ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka fún àwọn tí a bá fi iṣẹ́ náà rán, kí wọ́n gbé e sí ilé ìṣúra ọba.” Ọba bọ́ òrùka àṣẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó fún Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Juu. Ọba sọ fún un pé, “Má wulẹ̀ san owó kankan, àwọn eniyan náà wà ní ìkáwọ́ rẹ, lọ ṣe wọ́n bí o bá ti fẹ́.”
Est 3:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọdún kejìlá ọba Ahaswerusi, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù Nisani, wọ́n da puri (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hamani láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Addari. Nígbà náà ni Hamani sọ fún ọba Ahaswerusi pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fọ́nká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tókù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀. Tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, kí a gbé òfin kan jáde tí yóò pa wọ́n run, èmi yóò sì fi ẹgbàárùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà sínú ìṣúra ọba fún àwọn ọkùnrin tí wọn o ṣe iṣẹ́ náà.” Nítorí náà ọba sì bọ́ òrùka dídán (èdìdì) tí ó wà ní ìka rẹ̀ ó sì fi fún Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Júù. Ọba sọ fún Hamani pé, “pa owó náà mọ́, kí o sì ṣe ohun tí ó wù ọ́ fún àwọn ènìyàn náà.”