Est 1:4-9
Est 1:4-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o fi ọrọ̀ ijọba rẹ̀ ti o logo, ati ọṣọ iyebiye ọlanla rẹ̀ han lọjọ pipọ̀, ani li ọgọsan ọjọ. Nigbati ọjọ wọnyi si pari, ọba sè àse kan li ọjọ meje fun gbogbo awọn enia ti a ri ni Ṣuṣani ãfin, ati àgba ati ewe ni agbala ọgba ãfin ọba. Nibiti a gbe ta aṣọ àla daradara, aṣọ alaro, ati òféfe, ti a fi okùn ọ̀gbọ daradara, ati elesè aluko dimu mọ oruka fadaka, ati ọwọ̀n okuta marbili: wura ati fadaka ni irọgbọku, ti o wà lori ilẹ ti a fi okuta alabastari, marbili, ilẹkẹ daradara, ati okuta dudu tẹ́. Ninu ago wura li a si nfun wọn mu, (awọn ohun elo na si yatọ si ara wọn) ati ọti-waini ọba li ọ̀pọlọpọ gẹgẹ bi ọwọ ọba ti to. Gẹgẹ bi aṣẹ si ni mimu na; ẹnikẹni kò fi ipa rọ̀ ni: nitori bẹ̃ni ọba ti fi aṣẹ fun gbogbo awọn olori ile rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣe gẹgẹ bi ifẹ olukuluku. Faṣti ayaba sè àse pẹlu fun gbogbo awọn obinrin ni ile ọba ti iṣe ti Ahaswerusi.
Est 1:4-9 Yoruba Bible (YCE)
Fún odidi ọgọsan-an (180) ọjọ́ ni ọba fi ń fi ògo ìjọba rẹ̀ hàn, pẹlu ọrọ̀ ati dúkìá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọba se àsè ní àgbàlá ààfin fún ọjọ́ meje, fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní Susa, àtàwọn talaka, àtàwọn eniyan ńláńlá. Wọ́n ṣe ọgbà náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró ati aṣọ funfun. Wọ́n fi òwú funfun ati òwú àlàárì ṣe okùn, wọ́n fi so wọ́n mọ́ òrùka fadaka, wọ́n gbé wọn kọ́ sára òpó òkúta mabu. Wúrà ati fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn àga tí ó wà ninu ọgbà. Òkúta mabu pupa ati aláwọ̀ aró ni wọ́n fi ṣe gbogbo ọ̀dẹ̀dẹ̀, tí gbogbo wọn ń dán gbinringbinrin. Wọ́n ń fi oríṣìíríṣìí ife wúrà mu ọtí, ọba sì pèsè ọtí lọpọlọpọ gẹ́gẹ́ bí ipò ọlá ńlá rẹ̀. Àṣẹ ọba ni wọ́n tẹ̀lé nípa ọ̀rọ̀ ọtí mímu. Wọn kò fi ipá mú ẹnikẹ́ni, nítorí pé ọba ti pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ ààfin pé ohun tí olukuluku bá fẹ́ ni kí wọn fi tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ayaba Faṣiti pàápàá se àsè fún àwọn obinrin ní ààfin ọba Ahasu-erusi.
Est 1:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọláńlá rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko. Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí kọjá, ọba ṣe àsè fún ọjọ́ méje, nínú ọgbà tí ó wà nínú àgbàlá ààfin ọba, gbogbo ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni tí ó lọ́lá jùlọ, tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa. Ọgbà náà ní aṣọ fèrèsé funfun àti aláwọ̀ òféfèé. Àwọn okùn tí a fi aṣọ aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ elése àlùkò rán ni a fi ta á mọ́ òrùka fàdákà lára àwọn òpó mábù. Àwọn ibùsùn tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe wà níbi pèpéle òkúta tí a fi ń tẹ́lẹ̀ ilé tí ó jẹ́ mábù, píálì àti òkúta olówó iyebíye mìíràn. Kọ́ọ̀bù wúrà onídìí-odó ni a fi ń bu wáìnì fún wọn mu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì yàtọ̀ sí èkejì, wáìnì ọba pọ̀ púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe lawọ́ sí. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba a fi ààyè gba àlejò kọ̀ọ̀kan láti mu tó bí ó bá ti fẹ́, nítorí ọba ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ti ń bu wáìnì láti bù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ṣe béèrè fún mọ. Ayaba Faṣti náà ṣe àsè fún àwọn obìnrin ní ààfin ọba Ahaswerusi.