Est 1:10-12
Est 1:10-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li ọjọ keje, nigbati ọti-waini mu inu ọba dùn, o paṣẹ fun Mehumani, Bista, Harbona, Bigta ati Abagta, Ṣetari ati Karkasi, awọn iwẹfa meje ti njiṣẹ niwaju Ahaswerusi ọba. Lati mu Faṣti, ayaba wá siwaju ọba, ti on ti ade ọba, lati fi ẹwà rẹ̀ hàn awọn enia, ati awọn ijoye: nitori arẹwà obinrin ni. Ṣugbọn Faṣti ayaba kọ̀ lati wá nipa aṣẹ ọba lati ọwọ awọn ìwẹfa rẹ̀: nitorina ni ọba binu gidigidi, ibinu rẹ̀ si gbiná ninu rẹ̀.
Est 1:10-12 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ keje, nígbà tí ọba mu ọtí waini tí inú rẹ̀ dùn, ó pàṣẹ fún meje ninu àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ iranṣẹ rẹ̀: Mehumani, Bisita ati Habona, Bigita ati Abagita, Setari ati Kakasi, pé kí wọ́n lọ mú Ayaba Faṣiti wá siwaju òun, pẹlu adé lórí rẹ̀, láti fi ẹwà rẹ̀ han gbogbo àwọn eniyan ati àwọn olórí, nítorí pé ó jẹ́ arẹwà obinrin. Ṣugbọn nígbà tí àwọn ìwẹ̀fà tí ọba rán jíṣẹ́ fún un, ó kọ̀, kò wá siwaju ọba. Nítorí náà, inú bí ọba gidigidi, inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ru.
Est 1:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì mú inú ọba dùn, ó pàṣẹ fún Mehumani, Bista, Harbona, Bigta àti Abagta, Setari àti Karkasi, àwọn ìwẹ̀fà méje tí ń jíṣẹ́ fún Ahaswerusi. Kí wọn mú ayaba Faṣti wá síwájú rẹ̀, ti òun ti adé ọba rẹ̀, kí ó lè wá fi ẹwà rẹ̀ hàn àwọn ènìyàn àti àwọn ọlọ́lá, nítorí tí ó rẹwà. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Faṣti kọ̀ láti wá. Nígbà náà ni ọba bínú gidigidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ.