Est 1:1-18

Est 1:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe li ọjọ Ahaswerusi, (eyi ni Ahaswerusi ti o jọba lati India, ani titi o fi de Etiopia, lori ẹtadiladoje ìgberiko:) Li ọjọ wọnni, nigbati Ahaswerusi, ọba, joko lori itẹ ijọba rẹ̀, ti o wà ni Ṣuṣani, ãfin. Li ọdun kẹta ijọba rẹ̀, o sè àse kan fun gbogbo awọn ijoye ati awọn iranṣẹ rẹ̀; awọn balogun Persia ati Media, awọn ọlọla, ati awọn olori ìgberiko wọnni wà niwaju rẹ̀: Nigbati o fi ọrọ̀ ijọba rẹ̀ ti o logo, ati ọṣọ iyebiye ọlanla rẹ̀ han lọjọ pipọ̀, ani li ọgọsan ọjọ. Nigbati ọjọ wọnyi si pari, ọba sè àse kan li ọjọ meje fun gbogbo awọn enia ti a ri ni Ṣuṣani ãfin, ati àgba ati ewe ni agbala ọgba ãfin ọba. Nibiti a gbe ta aṣọ àla daradara, aṣọ alaro, ati òféfe, ti a fi okùn ọ̀gbọ daradara, ati elesè aluko dimu mọ oruka fadaka, ati ọwọ̀n okuta marbili: wura ati fadaka ni irọgbọku, ti o wà lori ilẹ ti a fi okuta alabastari, marbili, ilẹkẹ daradara, ati okuta dudu tẹ́. Ninu ago wura li a si nfun wọn mu, (awọn ohun elo na si yatọ si ara wọn) ati ọti-waini ọba li ọ̀pọlọpọ gẹgẹ bi ọwọ ọba ti to. Gẹgẹ bi aṣẹ si ni mimu na; ẹnikẹni kò fi ipa rọ̀ ni: nitori bẹ̃ni ọba ti fi aṣẹ fun gbogbo awọn olori ile rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣe gẹgẹ bi ifẹ olukuluku. Faṣti ayaba sè àse pẹlu fun gbogbo awọn obinrin ni ile ọba ti iṣe ti Ahaswerusi. Li ọjọ keje, nigbati ọti-waini mu inu ọba dùn, o paṣẹ fun Mehumani, Bista, Harbona, Bigta ati Abagta, Ṣetari ati Karkasi, awọn iwẹfa meje ti njiṣẹ niwaju Ahaswerusi ọba. Lati mu Faṣti, ayaba wá siwaju ọba, ti on ti ade ọba, lati fi ẹwà rẹ̀ hàn awọn enia, ati awọn ijoye: nitori arẹwà obinrin ni. Ṣugbọn Faṣti ayaba kọ̀ lati wá nipa aṣẹ ọba lati ọwọ awọn ìwẹfa rẹ̀: nitorina ni ọba binu gidigidi, ibinu rẹ̀ si gbiná ninu rẹ̀. Ọba si bi awọn ọlọgbọ́n, ti nwọn moye akokò, (nitori bẹ̃ni ìwa ọba ri si gbogbo awọn ti o mọ̀ ofin ati idajọ: Awọn ti o sunmọ ọ ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena, ati Memukani, awọn ijoye Persia ati Media mejeje, ti nri oju ọba, ti nwọn si joko ni ipò ikini ni ijọba). Pe, gẹgẹ bi ofin, Kini ki a ṣe si Faṣti ayaba, nitoriti on kò ṣe bi Ahaswerusi ọba ti paṣẹ fun u, lati ọwọ awọn ìwẹfa rẹ̀ wá? Memukani si dahùn niwaju ọba ati awọn ijoye pe, Faṣti ayaba kò ṣẹ̀ si ọba nikan, ṣugbọn si gbogbo awọn ijoye, ati si gbogbo awọn enia ti o wà ni ìgberiko Ahaswerusi ọba. Nitori ìwa ayaba yi yio tàn de ọdọ gbogbo awọn obinrin, tobẹ̃ ti ọkọ wọn yio di gigàn loju wọn, nigbati a o sọ ọ wi pe, Ahaswerusi ọba paṣẹ pe, ki a mu Faṣti ayaba wá siwaju rẹ̀, ṣugbọn on kò wá. Awọn ọlọla-obinrin Persia ati Media yio si ma wi bakanna li oni yi fun gbogbo awọn ijoye ọba ti nwọn gbọ́ ìwa ti ayaba hù. Bayi ni ẹ̀gan pipọ̀-pipọ̀, ati ibinu yio dide.

Est 1:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò tí Ahasu-erusi jọba ní ilẹ̀ Pasia, ìjọba rẹ̀ tàn dé agbègbè mẹtadinlaadoje (127), láti India títí dé Kuṣi ní ilẹ̀ Etiopia. Nígbà tí ó wà lórí oyè ní Susa tíí ṣe olú-ìlú ìjọba rẹ̀, ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè fún àwọn ìjòyè, ati àwọn olórí, àwọn òṣìṣẹ́, ati àwọn olórí ogun Pasia ati ti Media, àwọn eniyan pataki pataki tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ati àwọn gomina agbègbè rẹ̀. Fún odidi ọgọsan-an (180) ọjọ́ ni ọba fi ń fi ògo ìjọba rẹ̀ hàn, pẹlu ọrọ̀ ati dúkìá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọba se àsè ní àgbàlá ààfin fún ọjọ́ meje, fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní Susa, àtàwọn talaka, àtàwọn eniyan ńláńlá. Wọ́n ṣe ọgbà náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró ati aṣọ funfun. Wọ́n fi òwú funfun ati òwú àlàárì ṣe okùn, wọ́n fi so wọ́n mọ́ òrùka fadaka, wọ́n gbé wọn kọ́ sára òpó òkúta mabu. Wúrà ati fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn àga tí ó wà ninu ọgbà. Òkúta mabu pupa ati aláwọ̀ aró ni wọ́n fi ṣe gbogbo ọ̀dẹ̀dẹ̀, tí gbogbo wọn ń dán gbinringbinrin. Wọ́n ń fi oríṣìíríṣìí ife wúrà mu ọtí, ọba sì pèsè ọtí lọpọlọpọ gẹ́gẹ́ bí ipò ọlá ńlá rẹ̀. Àṣẹ ọba ni wọ́n tẹ̀lé nípa ọ̀rọ̀ ọtí mímu. Wọn kò fi ipá mú ẹnikẹ́ni, nítorí pé ọba ti pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ ààfin pé ohun tí olukuluku bá fẹ́ ni kí wọn fi tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ayaba Faṣiti pàápàá se àsè fún àwọn obinrin ní ààfin ọba Ahasu-erusi. Ní ọjọ́ keje, nígbà tí ọba mu ọtí waini tí inú rẹ̀ dùn, ó pàṣẹ fún meje ninu àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ iranṣẹ rẹ̀: Mehumani, Bisita ati Habona, Bigita ati Abagita, Setari ati Kakasi, pé kí wọ́n lọ mú Ayaba Faṣiti wá siwaju òun, pẹlu adé lórí rẹ̀, láti fi ẹwà rẹ̀ han gbogbo àwọn eniyan ati àwọn olórí, nítorí pé ó jẹ́ arẹwà obinrin. Ṣugbọn nígbà tí àwọn ìwẹ̀fà tí ọba rán jíṣẹ́ fún un, ó kọ̀, kò wá siwaju ọba. Nítorí náà, inú bí ọba gidigidi, inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ru. Ọba bá fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n ní òye nípa àkókò, (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ọba máa ń ṣe sí gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òfin ati ìdájọ́. Àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọn ni: Kaṣena, Ṣetari, ati Adimata, Taṣiṣi ati Meresi, Masena ati Memkani, àwọn ìjòyè meje ní Pasia ati Media. Àwọn ni wọ́n súnmọ́ ọn jù, tí ipò wọn sì ga jùlọ). Ọba bi wọ́n pé, “Gẹ́gẹ́ bí òfin, kí ni kí á ṣe sí Ayaba Faṣiti, nítorí ohun tí ọba pa láṣẹ, tí ó rán àwọn ìwẹ̀fà sí i pé kí ó ṣe kò ṣe é.” Memkani bá dáhùn níwájú ọba ati àwọn ìjòyè pé, “Kì í ṣe ọba nìkan ni Faṣiti kò kà sí, bíkòṣe gbogbo àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè ìjọba Ahasu-erusi ọba. Nǹkan tí Faṣiti ṣe yìí yóo di mímọ̀ fún àwọn obinrin, àwọn náà yóo sì máa fi ojú tẹmbẹlu àwọn ọkọ wọn. Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọba ṣá ti ranṣẹ sí ayaba pé kí ó wá siwaju òun rí, tí ó kọ̀, tí kò lọ.’ Láti òní lọ, àwọn obinrin, pàápàá àwọn obinrin Pasia ati ti Media, tí wọ́n ti gbọ́ ohun tí Ayaba ṣe yóo máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ sí àwọn ìjòyè. Èyí yóo sì mú kí aifinipeni ati ibinu pọ̀ sí i.

Est 1:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èyí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà Ahaswerusi, tí ó jẹ ọba lórí ẹ̀tàdínláàdóje ìletò bẹ̀rẹ̀ láti India títí ó fi dé Etiopia. Ní àkókò ìgbà náà ọba Ahaswerusi ń ṣe ìjọba ní orí ìtẹ́ ẹ rẹ̀ ní ilé ìṣọ́ ti Susa, Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè. Àwọn olórí ológun láti Persia àti Media, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọláńlá rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko. Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí kọjá, ọba ṣe àsè fún ọjọ́ méje, nínú ọgbà tí ó wà nínú àgbàlá ààfin ọba, gbogbo ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni tí ó lọ́lá jùlọ, tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa. Ọgbà náà ní aṣọ fèrèsé funfun àti aláwọ̀ òféfèé. Àwọn okùn tí a fi aṣọ aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ elése àlùkò rán ni a fi ta á mọ́ òrùka fàdákà lára àwọn òpó mábù. Àwọn ibùsùn tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe wà níbi pèpéle òkúta tí a fi ń tẹ́lẹ̀ ilé tí ó jẹ́ mábù, píálì àti òkúta olówó iyebíye mìíràn. Kọ́ọ̀bù wúrà onídìí-odó ni a fi ń bu wáìnì fún wọn mu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì yàtọ̀ sí èkejì, wáìnì ọba pọ̀ púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe lawọ́ sí. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba a fi ààyè gba àlejò kọ̀ọ̀kan láti mu tó bí ó bá ti fẹ́, nítorí ọba ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ti ń bu wáìnì láti bù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ṣe béèrè fún mọ. Ayaba Faṣti náà ṣe àsè fún àwọn obìnrin ní ààfin ọba Ahaswerusi. Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì mú inú ọba dùn, ó pàṣẹ fún Mehumani, Bista, Harbona, Bigta àti Abagta, Setari àti Karkasi, àwọn ìwẹ̀fà méje tí ń jíṣẹ́ fún Ahaswerusi. Kí wọn mú ayaba Faṣti wá síwájú rẹ̀, ti òun ti adé ọba rẹ̀, kí ó lè wá fi ẹwà rẹ̀ hàn àwọn ènìyàn àti àwọn ọlọ́lá, nítorí tí ó rẹwà. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Faṣti kọ̀ láti wá. Nígbà náà ni ọba bínú gidigidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní ìgbà gbogbo, ọba máa ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ìmọ̀ òfin àti ìdájọ́, ó sọ ọ́ fún àwọn amòye tí wọ́n mòye àkókò, àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọba àwọn wọ̀nyí ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena àti Memukani, àwọn ọlọ́lá méje ti Persia àti Media tí wọ́n ṣe pàtàkì sí ọba, wọ́n sì tún wà ní ibi gíga ní ìjọba. Ó béèrè pé, “Kí ni a lè ṣe sí ayaba Faṣti gẹ́gẹ́ bí òfin? Nítorí kò tẹríba fún àṣẹ ọba Ahaswerusi tí àwọn ìwẹ̀fà ọba sọ fún un.” Memukani sì dáhùn níwájú ọba àti àwọn ọlọ́lá pé, “Ayaba Faṣti ti ṣe búburú, kì í ṣe sí ọba nìkan ṣùgbọ́n sí gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba Ahaswerusi. Nítorí ìwà ayaba yìí yóò tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn obìnrin, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ wọn yóò di gígàn lójú u wọn, wọn yóò sì sọ pé, ọba Ahaswerusi pàṣẹ pé kí á mú ayaba Faṣti wá síwájú òun, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti wá. Ní ọjọ́ yìí gan an ni àwọn ọlọ́lá obìnrin Persia àti ti Media tí wọ́n ti gbọ́ nípa ìwà ayaba wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba bákan náà. Àfojúdi àti àìnírẹ́pọ̀ tí kò lópin yóò wà.