Efe 5:5-18
Efe 5:5-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ẹnyin mọ̀ eyi daju pe, kò si panṣaga, tabi alaimọ́ enia, tabi olojukòkoro, ti iṣe olubọriṣa, ti yio ni ini kan ni ijọba Kristi ati ti Ọlọrun. Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni fi ọ̀rọ asan tàn nyin jẹ: nitori nipasẹ nkan wọnyi ibinu Ọlọrun mbọ̀ wá sori awọn ọmọ alaigbọran. Nitorina ẹ máṣe jẹ alajọpin pẹlu wọn. Nitori ẹnyin ti jẹ òkunkun lẹ̃kan, ṣugbọn nisisiyi, ẹnyin di imọlẹ nipa ti Oluwa: ẹ mã rìn gẹgẹ bi awọn ọmọ imọlẹ: (Nitori eso Ẹmí wà niti iṣore gbogbo, ati ododo, ati otitọ;) Ẹ si mã wadi ohun ti iṣe itẹwọgbà fun Oluwa. Ẹ má si ba aileso iṣẹ òkunkun kẹgbẹ pọ̀, ṣugbọn ẹ kuku mã ba wọn wi. Nitori itiju tilẹ ni lati mã sọ̀rọ nkan wọnni ti nwọn nṣe nikọ̀kọ. Ṣugbọn ohun gbogbo ti a mba wi ni imọlẹ ifi han: nitori ohunkohun ti o ba fi nkan hàn, imọlẹ ni. Nitorina li o ṣe wipe, Jí, iwọ ẹniti o sùn, si jinde kuro ninu okú, Kristi yio si fun ọ ni imọlẹ. Nitorina ẹ kiyesi lati mã rìn ni ìwa pipé, kì iṣe bi awọn alailọgbọn, ṣugbọn bi awọn ọlọgbọn; Ẹ mã ra ìgba pada, nitori buburu li awọn ọjọ. Nitorina ẹ máṣe jẹ alailoye, ṣugbọn ẹ mã moye ohun ti ifẹ Oluwa jasi. Ẹ má si ṣe mu waini li amupara, ninu eyiti rudurudu wà; ṣugbọn ẹ kún fun Ẹmí
Efe 5:5-18 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin alára mọ̀ dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń ṣe àgbèrè, tabi tí ó ń ṣe ìṣekúṣe, tabi tí ó ní ojúkòkòrò, tabi tí ó ń bọ̀rìṣà, tí yóo ní ìpín ninu ìjọba Kristi, tíí ṣe ìjọba Ọlọrun. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ. Nítorí irú èyí ni ibinu Ọlọrun fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọràn. Nítorí náà ẹ má ṣe fi ara wé wọn. Nítorí nígbà kan, ninu òkùnkùn patapata ni ẹ wà. Ṣugbọn ní àkókò yìí ẹ ti bọ́ sinu ìmọ́lẹ̀ nítorí ẹ ti di ẹni Oluwa. Ẹ máa hùwà bí ọmọ ìmọ́lẹ̀. Nítorí èso ìmọ́lẹ̀ ni oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere, òdodo ati òtítọ́. Kí ẹ máa wádìí ohun tí yóo wu Oluwa. Ẹ má ṣe bá àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ òkùnkùn tí kò léso rere kẹ́gbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá wọn wí. Nítorí àwọn ohun tí wọn ń ṣe níkọ̀kọ̀ tilẹ̀ ti eniyan lójú láti sọ. Nítorí gbogbo nǹkan tí ìmọ́lẹ̀ bá tàn sí níí máa hàn kedere. Ohun gbogbo tí ó bá hàn kedere di ìmọ́lẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ orin kan ti sọ, pé, “Dìde, ìwọ tí ò ń sùn; jí dìde kúrò ninu òkú, Kristi yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ lára.” Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra bí ẹ ti ń hùwà. Ẹ má ṣe hùwà bí ẹni tí kò gbọ́n, ṣugbọn ẹ hùwà bí ọlọ́gbọ́n. Ẹ lo gbogbo àkókò yín dáradára nítorí àkókò tí a wà yìí burú. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ aṣiwèrè, ṣugbọn kí ẹ máa fi òye gbé ohun tíí ṣe ìfẹ́ Oluwa. Ẹ má máa mu ọtí yó, òfò ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.
Efe 5:5-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nítorí ẹ̀yin mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tàbí wọ̀bìà (tí í ṣé abọ̀rìṣà), tí yóò ni ìpín kan ni ìjọba Kristi àti Ọlọ́run. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn. Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ (nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́). Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa. Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí. Nítorí ìtìjú tilẹ̀ ni láti máa sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí àwọn aláìgbọ́ràn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀. Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn: nítorí ohunkóhun tí ó bá fi nǹkan hàn, ìmọ́lẹ̀ ni. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé, “Jí, ìwọ̀ ẹni tí ó sun, sí jíǹde kúrò nínú òkú Kristi yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.” Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n; ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́. Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.