Efe 5:25-32
Efe 5:25-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. Kí òun lè sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fi ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí. Kí òun lé mú un wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó ní ògo ní àìlábàwọ́n, tàbí àlébù kan, tàbí irú nǹkan bá-wọ̀n-ọn-nì: ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù. Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnrawọn. Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀; bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti ń ṣe sí ìjọ. Nítorí pé àwa ni ẹ̀yà ara rẹ̀, àti tí ẹran-ara rẹ̀, àti egungun ara rẹ̀. Nítorí èyí ní ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan. Àṣírí ńlá ní èyí: ṣùgbọ́n èmí ń sọ nípá ti Kristi àti tí ìjọ.
Efe 5:25-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya nyin, gẹgẹ bi Kristi si ti fẹran ìjọ, ti o si fi ara rẹ̀ fun u; Ki on ki o le sọ ọ di mimọ́ lẹhin ti a ti fi ọ̀rọ wẹ ẹ mọ́ ninu agbada omi, Ki on ki o le mu u wá sọdọ ara rẹ̀ bi ìjọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni; ṣugbọn ki o le jẹ mimọ́ ati alaini àbuku. Bẹ̃li o tọ́ ki awọn ọkunrin ki o mã fẹràn awọn aya wọn gẹgẹ bi ara awọn tikarawọn. Ẹniti o ba fẹran aya rẹ̀, o fẹran on tikararẹ̀. Nitori kò si ẹnikan ti o ti korira ara rẹ̀; bikoṣepe ki o mã bọ́ ọ ki o si mã ṣikẹ rẹ̀ gẹgẹ bi Kristi si ti nṣe si ìjọ. Nitoripe awa li ẹ̀ya-ara rẹ̀, ati ti ẹran-ara rẹ̀, ati ti egungun ara rẹ̀. Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, on o si dàpọ mọ́ aya rẹ̀, awọn mejeji a si di ara kan. Aṣiri nla li eyi: ṣugbọn emi nsọ nipa ti Kristi ati ti ijọ.
Efe 5:25-32 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. Ó ṣe èyí láti yà á sọ́tọ̀. Ó sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó ti fi omi wẹ̀ ẹ́ nípa ọ̀rọ̀ iwaasu. Kí ó lè mú ìjọ wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó lọ́lá, tí kò ní àléébù kankan, tabi kí ó hunjọ, tabi kí ó ní nǹkan àbùkù kankan, ṣugbọn kí ó lè jẹ́ ìjọ mímọ́ tí kò ní èérí. Bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ kí àwọn ọkọ fẹ́ràn àwọn aya wọn, bí wọ́n ti fẹ́ràn ara tiwọn. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn aya rẹ̀, òun tìkararẹ̀ ni ó fẹ́ràn. Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó kórìíra ara rẹ̀. Ńṣe ni eniyan máa ń tọ́jú ara rẹ̀, tí ó sì máa ń kẹ́ ẹ. Bẹ́ẹ̀ ni Kristi ń ṣe sí ìjọ. Nítorí ẹ̀yà ara Kristi ni a jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, pé, “Nítorí náà ni ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, tí yóo darapọ̀ pẹlu aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo wá di ara kan.” Àṣírí ńlá ni èyí. Mò ń sọ nípa ipò tí Kristi wà sí ìjọ.