Efe 5:17-20
Efe 5:17-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ẹ máṣe jẹ alailoye, ṣugbọn ẹ mã moye ohun ti ifẹ Oluwa jasi. Ẹ má si ṣe mu waini li amupara, ninu eyiti rudurudu wà; ṣugbọn ẹ kún fun Ẹmí; Ẹ si mã bá ara nyin sọ̀rọ ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã kọrin, ki ẹ si mã kọrin didun li ọkàn nyin si Oluwa; Ẹ mã dupẹ nigbagbogbo fun ohun gbogbo lọwọ Ọlọrun, ani Baba, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa
Efe 5:17-20 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ aṣiwèrè, ṣugbọn kí ẹ máa fi òye gbé ohun tíí ṣe ìfẹ́ Oluwa. Ẹ má máa mu ọtí yó, òfò ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ máa fi Orin Dafidi ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá bá ara yín sọ̀rọ̀. Ẹ máa kọrin; ẹ máa fi ìyìn fún Oluwa ninu ọ̀kan yín. Ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Baba nígbà gbogbo fún gbogbo nǹkan ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi.
Efe 5:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá.