Efe 5:14-20
Efe 5:14-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina li o ṣe wipe, Jí, iwọ ẹniti o sùn, si jinde kuro ninu okú, Kristi yio si fun ọ ni imọlẹ. Nitorina ẹ kiyesi lati mã rìn ni ìwa pipé, kì iṣe bi awọn alailọgbọn, ṣugbọn bi awọn ọlọgbọn; Ẹ mã ra ìgba pada, nitori buburu li awọn ọjọ. Nitorina ẹ máṣe jẹ alailoye, ṣugbọn ẹ mã moye ohun ti ifẹ Oluwa jasi. Ẹ má si ṣe mu waini li amupara, ninu eyiti rudurudu wà; ṣugbọn ẹ kún fun Ẹmí; Ẹ si mã bá ara nyin sọ̀rọ ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã kọrin, ki ẹ si mã kọrin didun li ọkàn nyin si Oluwa; Ẹ mã dupẹ nigbagbogbo fun ohun gbogbo lọwọ Ọlọrun, ani Baba, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa
Efe 5:14-20 Yoruba Bible (YCE)
Ohun gbogbo tí ó bá hàn kedere di ìmọ́lẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ orin kan ti sọ, pé, “Dìde, ìwọ tí ò ń sùn; jí dìde kúrò ninu òkú, Kristi yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ lára.” Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra bí ẹ ti ń hùwà. Ẹ má ṣe hùwà bí ẹni tí kò gbọ́n, ṣugbọn ẹ hùwà bí ọlọ́gbọ́n. Ẹ lo gbogbo àkókò yín dáradára nítorí àkókò tí a wà yìí burú. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ aṣiwèrè, ṣugbọn kí ẹ máa fi òye gbé ohun tíí ṣe ìfẹ́ Oluwa. Ẹ má máa mu ọtí yó, òfò ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ máa fi Orin Dafidi ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá bá ara yín sọ̀rọ̀. Ẹ máa kọrin; ẹ máa fi ìyìn fún Oluwa ninu ọ̀kan yín. Ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Baba nígbà gbogbo fún gbogbo nǹkan ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi.
Efe 5:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà ni ó ṣe wí pé, “Jí, ìwọ̀ ẹni tí ó sun, sí jíǹde kúrò nínú òkú Kristi yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.” Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n; Ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́. Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá.