Efe 5:1-4
Efe 5:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA ẹ mã ṣe afarawe Ọlọrun bi awọn ọmọ ọ̀wọ́n; Ẹ si mã rìn ni ifẹ, gẹgẹ bi Kristi pẹlu ti fẹ wa, ti o si fi ara rẹ̀ fun wa li ọrẹ ati ẹbọ fun Ọlọrun fun õrùn didun. Ṣugbọn àgbere, ati gbogbo ìwa ẽrí, tabi ojukòkoro, ki a má tilẹ darukọ rẹ̀ larin nyin mọ́, bi o ti yẹ awọn enia mimọ́; Ibã ṣe ìwa ọ̀bun, ati isọ̀rọ wère, tabi iṣẹ̀fẹ, awọn ohun ti kò tọ́: ṣugbọn ẹ kuku mã dupẹ.
Efe 5:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ, ẹ fi ìwà jọ Ọlọrun. Ẹ máa rìn ninu ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ wa, tí ó fi ara òun tìkararẹ̀ rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí Ọlọrun nítorí tiwa. Kí á má ṣe gbúròó ìwà àgbèrè, tabi oríṣìíríṣìí ìṣekúṣe, tabi ojúkòkòrò láàrin àwọn eniyan Ọlọrun. Ìwà ìtìjú, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tabi àwàdà burúkú kò yẹ yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọpẹ́ sí Ọlọrun ni ó yẹ yín.
Efe 5:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọ́run bí àwọn olùfẹ́ ọmọ, ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn. Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà èérí, tàbí ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàrín yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; Ìbá à ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́.