Efe 5:1-11
Efe 5:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA ẹ mã ṣe afarawe Ọlọrun bi awọn ọmọ ọ̀wọ́n; Ẹ si mã rìn ni ifẹ, gẹgẹ bi Kristi pẹlu ti fẹ wa, ti o si fi ara rẹ̀ fun wa li ọrẹ ati ẹbọ fun Ọlọrun fun õrùn didun. Ṣugbọn àgbere, ati gbogbo ìwa ẽrí, tabi ojukòkoro, ki a má tilẹ darukọ rẹ̀ larin nyin mọ́, bi o ti yẹ awọn enia mimọ́; Ibã ṣe ìwa ọ̀bun, ati isọ̀rọ wère, tabi iṣẹ̀fẹ, awọn ohun ti kò tọ́: ṣugbọn ẹ kuku mã dupẹ. Nitori ẹnyin mọ̀ eyi daju pe, kò si panṣaga, tabi alaimọ́ enia, tabi olojukòkoro, ti iṣe olubọriṣa, ti yio ni ini kan ni ijọba Kristi ati ti Ọlọrun. Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni fi ọ̀rọ asan tàn nyin jẹ: nitori nipasẹ nkan wọnyi ibinu Ọlọrun mbọ̀ wá sori awọn ọmọ alaigbọran. Nitorina ẹ máṣe jẹ alajọpin pẹlu wọn. Nitori ẹnyin ti jẹ òkunkun lẹ̃kan, ṣugbọn nisisiyi, ẹnyin di imọlẹ nipa ti Oluwa: ẹ mã rìn gẹgẹ bi awọn ọmọ imọlẹ: (Nitori eso Ẹmí wà niti iṣore gbogbo, ati ododo, ati otitọ;) Ẹ si mã wadi ohun ti iṣe itẹwọgbà fun Oluwa. Ẹ má si ba aileso iṣẹ òkunkun kẹgbẹ pọ̀, ṣugbọn ẹ kuku mã ba wọn wi.
Efe 5:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọ́run bí àwọn olùfẹ́ ọmọ, ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn. Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà èérí, tàbí ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàrín yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; Ìbá à ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́. Nítorí ẹ̀yin mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tàbí wọ̀bìà, (tí í ṣé abọ̀rìṣà) tí yóò ni ìpín kan ni ìjọba Kristi àti Ọlọ́run. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn. Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: Ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀: (Nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́). Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa. Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí.
Efe 5:1-11 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ, ẹ fi ìwà jọ Ọlọrun. Ẹ máa rìn ninu ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ wa, tí ó fi ara òun tìkararẹ̀ rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí Ọlọrun nítorí tiwa. Kí á má ṣe gbúròó ìwà àgbèrè, tabi oríṣìíríṣìí ìṣekúṣe, tabi ojúkòkòrò láàrin àwọn eniyan Ọlọrun. Ìwà ìtìjú, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tabi àwàdà burúkú kò yẹ yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọpẹ́ sí Ọlọrun ni ó yẹ yín. Ẹ̀yin alára mọ̀ dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń ṣe àgbèrè, tabi tí ó ń ṣe ìṣekúṣe, tabi tí ó ní ojúkòkòrò, tabi tí ó ń bọ̀rìṣà, tí yóo ní ìpín ninu ìjọba Kristi, tíí ṣe ìjọba Ọlọrun. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ. Nítorí irú èyí ni ibinu Ọlọrun fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọràn. Nítorí náà ẹ má ṣe fi ara wé wọn. Nítorí nígbà kan, ninu òkùnkùn patapata ni ẹ wà. Ṣugbọn ní àkókò yìí ẹ ti bọ́ sinu ìmọ́lẹ̀ nítorí ẹ ti di ẹni Oluwa. Ẹ máa hùwà bí ọmọ ìmọ́lẹ̀. Nítorí èso ìmọ́lẹ̀ ni oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere, òdodo ati òtítọ́. Kí ẹ máa wádìí ohun tí yóo wu Oluwa. Ẹ má ṣe bá àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ òkùnkùn tí kò léso rere kẹ́gbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá wọn wí.