Efe 4:9-12
Efe 4:9-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
(Njẹ niti pe o goke lọ, kili o jẹ, bikoṣepe o kọ́ sọkalẹ pẹlu lọ si iha isalẹ ilẹ? Ẹniti o ti sọkalẹ, on kanna li o si ti goke rekọja gbogbo awọn ọrun, ki o le kún ohun gbogbo.) O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran bi oluṣọ-agutan ati olukọni; Fun aṣepé awọn enia mimọ́ fun iṣẹ-iranṣẹ, fun imudagba ara Kristi
Efe 4:9-12 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó sọ pé, “Ó lọ sí òkè ọ̀run,” ìtumọ̀ èyí kò lè yéni tóbẹ́ẹ̀ bí kò bá jẹ́ pé ó ti kọ́kọ́ wá sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Òun kan náà tí ó wá sí ìsàlẹ̀ ni ó lọ sí òkè, tí ó tayọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́run, kí ó lè sọ gbogbo nǹkan di kíkún. Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti jẹ́ aposteli, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ wolii, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ ajíyìnrere, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ alufaa ati olùkọ́ni. Àwọn ẹ̀bùn wọnyi wà fún lílò láti mú kí ara àwọn eniyan Ọlọrun lè dá ṣáṣá kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, ati láti mú kí ara Kristi lè dàgbà.
Efe 4:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
(Ǹjẹ́ ní ti pé, “Ó gòkè lọ!” Kín ni ó túmọ̀ sí, bí kò ṣe pé ó kọ́ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀? Ẹni tí ó ti sọ̀kalẹ̀, Òun kan náà ni ó sì ti gòkè rékọjá gbogbo àwọn ọ̀run, kí ó lè kún ohun gbogbo.) Nítorí náà ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí aposteli; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí efangelisti, àti àwọn mìíràn bí olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ́ni. Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ́ fun iṣẹ́ ìránṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kristi.