Efe 4:17-23
Efe 4:17-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ eyi ni mo nwi, ti mo si njẹri ninu Oluwa pe, lati isisiyi lọ ki ẹnyin ki o máṣe rìn mọ́, ani gẹgẹ bi awọn Keferi ti nrin ninu ironu asan wọn, Òye awọn ẹniti o ṣòkunkun, awọn ti o si ti di àjeji si ìwa-bi-Ọlọrun nitori aimọ̀ ti mbẹ ninu wọn, nitori lile ọkàn wọn: Awọn ẹniti ọkàn wọn le rekọja, ti nwọn si ti fi ara wọn fun wọ̀bia, lati mã fi iwọra ṣiṣẹ ìwa-ẽri gbogbo. Ṣugbọn a kò fi Kristi kọ́ nyin bẹ̃; Bi o ba ṣe pe nitotọ li ẹ ti gbohùn rẹ̀, ti a si ti kọ́ nyin ninu rẹ̀, gẹgẹ bi otitọ ti mbẹ ninu Jesu: Pe, niti iwa nyin atijọ, ki ẹnyin ki o bọ ogbologbo ọkunrin nì silẹ, eyiti o dibajẹ gẹgẹ bi ifẹkufẹ ẹ̀tan; Ki ẹ si di titun ni ẹmi inu nyin
Efe 4:17-23 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, mò ń sọ fun yín, mo sì ń bẹ̀ yín ní orúkọ Oluwa pé, kí ẹ má máa hùwà bíi ti àwọn abọ̀rìṣà mọ́, àwọn tí wọn ń hùwà gẹ́gẹ́ bí èrò asán ọkàn wọn. Ọkàn àwọn yìí ti ṣókùnkùn, ó sì ti yàtọ̀ pupọ sí irú ìgbé-ayé tí Ọlọrun fẹ́. Nítorí òpè ni wọ́n, ọkàn wọn ti le. Wọn kò bìkítà: wọ́n ti fi ara wọn fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara nípa oríṣìíríṣìí ìwà burúkú nítorí ojúkòkòrò. Ṣugbọn a kò kọ́ ẹ̀yin bẹ́ẹ̀ nípa Kristi. Ẹ ti gbọ́ nípa Jesu, a sì ti fi òtítọ́ rẹ̀ kọ yín, pé kí ẹ jìnnà sí irú ìwà àtijọ́ tí ẹ ti ń hù, ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tíí máa tan eniyan lọ sinu ìparun. Kí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ yín di ẹni titun ninu ọkàn yín.
Efe 4:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí nínú Olúwa pé, láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹ̀yin má ṣe rìn mọ́, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà ti ń rìn nínú ìrònú asán wọn. Òye àwọn ẹni tí ó ṣókùnkùn, a sì yà wọ́n nínú ìyè Ọlọ́run nítorí àìmọ̀ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí líle ọkàn wọn. Àwọn ẹni tí ọkàn wọn le rékọjá, tí wọ́n sì ti fi ara wọn fún wọ̀bìà, láti máa fi ìwọra ṣiṣẹ́ ìwà èérí gbogbo. Ṣùgbọ́n a kò fi Kristi kọ́ yín bẹ́ẹ̀. Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ti ń bẹ nínú Jesu. Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ògbólógbòó ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn; Kí ẹ sì di tuntun ni ẹ̀mí inú yín