Efe 4:1-16

Efe 4:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

NITORINA emi ondè ninu Oluwa, mbẹ̀ nyin pe, ki ẹnyin ki o mã rìn bi o ti yẹ fun ìpe na ti a fi pè nyin, Pẹlu irẹlẹ gbogbo ati inu tutù, pẹlu ipamọra, ẹ mã fi ifẹ farada a fun ẹnikeji nyin; Ki ẹ si mã lakaka lati pa iṣọkan Ẹmí mọ́ ni ìdipọ alafia. Ara kan ni mbẹ, ati Ẹmí kan, ani bi a ti pè nyin sinu ireti kan ti ipè nyin; Oluwa kan, igbagbọ́ kan, baptismu kan, Ọlọrun kan ati Baba gbogbo, ẹniti o wà lori gbogbo ati nipa gbogbo ati ninu nyin gbogbo. Ṣugbọn olukuluku wa li a fi ore-ọfẹ fun gẹgẹ bi oṣuwọn ẹ̀bun Kristi. Nitorina o wipe, Nigbati o gòke lọ si ibi giga, o di igbekun ni igbekun, o si fi ẹ̀bun fun enia. (Njẹ niti pe o goke lọ, kili o jẹ, bikoṣepe o kọ́ sọkalẹ pẹlu lọ si iha isalẹ ilẹ? Ẹniti o ti sọkalẹ, on kanna li o si ti goke rekọja gbogbo awọn ọrun, ki o le kún ohun gbogbo.) O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran bi oluṣọ-agutan ati olukọni; Fun aṣepé awọn enia mimọ́ fun iṣẹ-iranṣẹ, fun imudagba ara Kristi: Titi gbogbo wa yio fi de iṣọkan igbagbọ́ ati ìmọ Ọmọ Ọlọrun, titi a o fi di ọkunrin, titi a o fi de iwọn gigun ẹ̀kún Kristi: Ki awa ki o máṣe jẹ ewe mọ́, ti a nfi gbogbo afẹfẹ ẹ̀kọ́ tì siwa tì sẹhin, ti a si fi ngbá kiri, nipa itanjẹ enia, nipa arekereke fun ọgbọnkọgbọn ati múni ṣina; Ṣugbọn ki a mã sọ otitọ ni ifẹ, ki a le mã dàgbasoke ninu rẹ̀ li ohun gbogbo, ẹniti iṣe ori, ani Kristi: Lati ọdọ ẹniti ara na ti a nso ṣọkan pọ, ti o si nfi ara mọra, nipa gbogbo orike ipese, (gẹgẹ bi iṣẹ olukuluku ẹya-ara ni ìwọn tirẹ̀) o nmu ara na bi si i fun idagbasoke on tikararẹ ninu ifẹ.

Efe 4:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí náà, èmi tí mo di ẹlẹ́wọ̀n nítorí ti Oluwa, ń bẹ̀ yín pé kí ẹ máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, bí irú ìpè tí Ọlọrun pè yín. Kí ẹ máa hùwà pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ọkàn tútù, kí ẹ sì máa mú sùúrù. Kí ẹ máa fi ìfẹ́ bá ara yín lò nípa ìfaradà. Ẹ ní ìtara láti pa ìṣọ̀kan ti Ẹ̀mí mọ́ ninu alaafia tí ó so yín pọ̀. Ara kan ni ó wà, ati Ẹ̀mí kan, gẹ́gẹ́ bí ìpè tí a ti pè yín ti jẹ́ ti ìrètí kan. Oluwa kan ṣoṣo ni ó wà, ati igbagbọ kan, ati ìrìbọmi kan. Ọlọrun kan ni ó wà, tíí ṣe Baba gbogbo eniyan, òun ni olórí ohun gbogbo, tí ó ń ṣiṣẹ́ ninu ohun gbogbo, tí ó sì wà ninu ohun gbogbo. Ṣugbọn ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ẹ̀bùn tí Kristi fi fún wa. Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé, “Nígbà tí ó lọ sí òkè ọ̀run, ó kó àwọn ìgbèkùn lẹ́yìn, ó sì fi ẹ̀bùn fún àwọn eniyan.” Nígbà tí ó sọ pé, “Ó lọ sí òkè ọ̀run,” ìtumọ̀ èyí kò lè yéni tóbẹ́ẹ̀ bí kò bá jẹ́ pé ó ti kọ́kọ́ wá sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Òun kan náà tí ó wá sí ìsàlẹ̀ ni ó lọ sí òkè, tí ó tayọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́run, kí ó lè sọ gbogbo nǹkan di kíkún. Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti jẹ́ aposteli, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ wolii, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ ajíyìnrere, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ alufaa ati olùkọ́ni. Àwọn ẹ̀bùn wọnyi wà fún lílò láti mú kí ara àwọn eniyan Ọlọrun lè dá ṣáṣá kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, ati láti mú kí ara Kristi lè dàgbà. Báyìí ni gbogbo wa yóo fi dé ìṣọ̀kan ninu igbagbọ ati ìmọ̀ Ọmọ Ọlọrun, tí a óo fi di géńdé, tí a óo fi dàgbà bí Kristi ti dàgbà. A kì í tún ṣe ọmọ-ọwọ́ mọ́, tí ìgbì yóo máa bì sọ́tùn-ún, sósì, tabi tí afẹ́fẹ́ oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àrékérekè àwọn tí wọn ń lo ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ láti fi tan eniyan jẹ yóo máa fẹ́ káàkiri. Ṣugbọn a óo máa sọ òtítọ́ pẹlu ìfẹ́, a óo máa dàgbà ninu rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, ninu Kristi tíí ṣe orí. Òun ni ó mú kí gbogbo ẹ̀yà ara wà ní ìṣọ̀kan, tí gbogbo oríkèé-ríkèé ara wa sì wà ní ipò wọn, pẹlu iṣan tí ó mú wọn dúró, tí gbogbo wọn sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ipò olukuluku wọn, tí gbogbo ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan fi ń dàgbà, tí ó ń mú kí gbogbo ara rẹ̀ dàgbà ninu ìfẹ́.

Efe 4:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí. Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín. Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà. Ara kan ni ń bẹ, àti Ẹ̀mí kan, àní bí a ti pè yín sínú ìrètí kan nígbà tí a pè yín. Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan àti ìtẹ̀bọmi kan. Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó ṣe olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú ohun gbogbo. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ni a fi oore-ọ̀fẹ́ fun gẹ́gẹ́ bi òṣùwọ̀n ẹ̀bùn Kristi. Nítorí náà a wí pé: “Nígbà tí ó gòkè lọ sí ibi gíga, ó di ìgbèkùn ni ìgbèkùn, ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn.” (Ǹjẹ́ ní ti pé, “Ó gòkè lọ!” Kín ni ó túmọ̀ sí, bí kò ṣe pé ó kọ́ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀? Ẹni tí ó ti sọ̀kalẹ̀, Òun kan náà ni ó sì ti gòkè rékọjá gbogbo àwọn ọ̀run, kí ó lè kún ohun gbogbo.) Nítorí náà ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí aposteli; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí efangelisti, àti àwọn mìíràn bí olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ́ni. Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ́ fun iṣẹ́ ìránṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kristi. Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kristi. Kí àwa má ṣe jẹ́ èwe mọ́, tí a ń fi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá tì sẹ́yìn, tí a sì fi ń gbá kiri, nípa ìtànjẹ ènìyàn, nípa àrékérekè fun ọgbọ́nkọ́gbọ́n àti mú ni ṣìnà; Ṣùgbọ́n ká a máa sọ òtítọ́ ní ìfẹ́, kí a lè máa dàgbàsókè nínú rẹ̀ ní ohun gbogbo ẹni tí i ṣe orí, àní Kristi. Láti ọ̀dọ̀ ẹni ti ara náà tí a ń so ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń fi ara mọ́ra, nípasẹ̀ oríkèé kọ̀ọ̀kan tí a ti pèsè, nígbà tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ dáradára, yóò mú ara dàgbà, yóò sì gbé ara òun tìkára rẹ̀ dìde nínú ìfẹ́.

Efe 4:1-16

Efe 4:1-16 YBCVEfe 4:1-16 YBCVEfe 4:1-16 YBCV