Efe 2:4-10
Efe 2:4-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn Ọlọrun, ẹniti iṣe ọlọrọ̀ li ãnu, nitori ifẹ nla rẹ̀ ti o fi fẹ wa, Nigbati awa tilẹ ti kú nitori irekọja wa, o sọ wa di ãye pẹlu Kristi (ore-ọfẹ li a ti fi gba nyin là). O si ti ji wa dide pẹlu rẹ̀, o si ti mu wa wa joko pẹlu rẹ̀ ninu awọn ọrun ninu Kristi Jesu: Pe ni gbogbo ìgba ti mbọ ki o ba le fi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀ ti o pọ rekọja han ninu iṣeun rẹ̀ si wa ninu Kristi Jesu. Nitori ore-ọfẹ li a ti fi gbà nyin là nipa igbagbọ́; ati eyini kì iṣe ti ẹnyin tikaranyin: ẹ̀bun Ọlọrun ni: Kì iṣe nipa iṣẹ, ki ẹnikẹni má bã ṣogo. Nitori awa ni iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ ti a ti dá ninu Kristi Jesu fun iṣẹ rere, ti Ọlọrun ti pèse tẹlẹ, ki awa ki o le mã rìn ninu wọn.
Efe 2:4-10 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nítorí ìfẹ́ ńlá tí Ọlọrun tí ó ní àánú pupọ ní sí wa, ó sọ wá di alààyè pẹlu Kristi nígbà tí a ti di òkú ninu ìwàkíwà wa. Oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là. Ọlọrun tún jí wa dìde pẹlu Kristi Jesu, ó wá fi wá jókòó pẹlu rẹ̀ lọ́run, kí ó lè fihàn ní àkókò tí ó ń bọ̀ bí ọlá oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ti tóbi tó, nípa àánú tí ó ní sí wa ninu Kristi Jesu. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là nípa igbagbọ. Kì í ṣe nítorí iṣẹ́, ẹ̀bùn Ọlọrun ni. Kì í ṣe ìtorí iṣẹ́ tí eniyan ṣe, kí ẹnikẹ́ni má baà máa gbéraga. Nítorí òun ni ó dá wa bí a ti rí, ó dá wa fún iṣẹ́ rere nípasẹ̀ Kristi Jesu, àwọn iṣẹ́ tí Ọlọrun ti ṣe tẹ́lẹ̀, pé kí á máa ṣe.
Efe 2:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe ọlọ́rọ̀ ni àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa, nígbà tí àwa tilẹ̀ ti kú nítorí ìrékọjá wa, ó sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kristi, oore-ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là. Ọlọ́run sì ti jí wa dìde pẹ̀lú Kristi, ó sì ti mú wa jókòó pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run nínú Kristi Jesu. Pé ni gbogbo ìgbà tí ń bọ̀ kí ó bà á lè fi ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí o pọ̀ rékọjá hàn fún wa nínú ìṣeun rẹ̀ sì wà nínú Kristi Jesu. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́. Èyí kì í ṣe nípa agbára ẹ̀yin fúnrayín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni: Kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo. Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kristi Jesu fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèsè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe.